Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  December 2016

“Gbígbé Èrò Inú Ka Ẹ̀mí Túmọ̀ Sí Ìyè àti Àlàáfíà”

“Gbígbé Èrò Inú Ka Ẹ̀mí Túmọ̀ Sí Ìyè àti Àlàáfíà”

“Àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí gbé [èrò inú wọn] ka àwọn ohun ti ẹ̀mí.”RÓÒMÙ 8:5.

ORIN: 57, 52

1, 2. Kí nìdí tí Róòmù orí 8 fi ṣe pàtàkì sáwọn ẹni àmì òróró?

NÍGBÀ Ìrántí Ikú Jésù, a sábà máa ń ka Róòmù 8:15-17. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣàlàyé bí àwọn ẹni àmì òróró ṣe máa ń mọ̀ pé Ọlọ́run ti yan àwọn, ó ní ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wọn. Ẹsẹ àkọ́kọ́nínú Róòmù orí 8 tọ́ka sí “àwọn tí wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” Àmọ́, ṣé àwọn ẹni àmì òróró nìkan ló lè jàǹfààní látinú Róòmù orí 8? Àǹfààní wo ni orí Bíbélì yìí máa ṣe àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé?

2 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró la dìídì darí orí Bíbélì yìí sí. Wọ́n gba “ẹ̀mí,” wọ́n sì ń ‘dúró de ìsọdọmọ, ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ẹran ara wọn nípasẹ̀ ìràpadà.’ (Róòmù 8:23) Lọ́jọ́ iwájú, wọ́n nírètí láti lọ sọ́run, wọ́n sì máa di ọmọ Ọlọ́run. Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé, wọ́n ṣèrìbọmi, Ọlọ́run sì mú kí wọ́n jọlá ẹbọ ìràpadà náà, ó tipa bẹ́ẹ̀ dárí ẹ̀sẹ̀ wọn jì wọ́n, ó kà wọ́n sí olódodo, ó sì sọ wọ́n dọmọ.Róòmù 3:23-26; 4:25; 8:30.

3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù orí 8 máa ṣe àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé láǹfààní?

3 Síbẹ̀, Róòmù orí 8 ṣe pàtàkì fáwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ìdí ni pé lọ́nà kan, Ọlọ́run ka àwọn náà sí olódodo.  Ohun tó mú ká sọ bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú àwọn orí tó ṣáájú. Bí àpẹẹrẹ, ní orí 4 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù. Ọkùnrin tó nígbàgbọ́ yìí gbáyé ṣáájú kí Jésù tó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kódà ó ti gbáyé kí Jèhófà tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin. Síbẹ̀, Jèhófà kíyè sí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí Ábúráhámù ní, ó sì kà á sí olódodo. (Ka Róòmù 4:20-22.) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, Jèhófà lè ka àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé sí olódodo. Torí náà, ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fáwọn ẹni àmì òróró nínú Róòmù orí 8 máa ṣe wọ́n láǹfààní tí wọ́n bá fi í sílò.

4. Ìbéèrè wo ló yẹ ká ronú lé tá a bá ka Róòmù 8:21?

4 Ìwé Róòmù 8:21 mú kó dá wa lójú pé ayé tuntun máa dé. Ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣèlérí pé “a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Àmọ́ ohun tó yẹ ká bi ara wa ni pé, ṣé ìbùkún yìí máa ṣojú wa? Ṣé ó dá ẹ lójú pé wàá wà níbẹ̀? Róòmù orí 8 fún wa nímọ̀ràn tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí ìbùkún yìí gbà.

“GBÍGBÉ ÈRÒ INÚ KA ẸRAN ARA”

5. Ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 8:4-13?

5 Ka Róòmù 8:4-13. Róòmù orí 8 sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń rìn ní “ìbámu pẹ̀lú ẹran ara,” ó wá fi wọ́n wéra pẹ̀lú àwọn tó ń rìn ní “ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.” Àwọn kan rò pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń fi àwọn tó mọ òtítọ́ wé àwọn tí kò mọ òtítọ́ tàbí pé ó ń fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn Kristẹni àtàwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Àmọ́ àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ ìwé yìí sí ni “àwọn tí ó wà ní Róòmù gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run, tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́.” (Róòmù 1:7) Torí náà, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tó ń rìn níbàámu pẹ̀lú ẹran ara àtàwọn Kristẹni tó ń rìn níbàámu pẹ̀lú ẹ̀mí. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín wọn?

6, 7. (a) Onírúurú ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ẹran ara”? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “ẹran ara” nínú Róòmù 8:4-13?

6 Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “ẹran ara”? Onírúurú ọ̀nà ni Bíbélì máa ń gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ẹran ara.” Nígbà míì, ó máa ń tọ́ka sí ara tá a lè fojú rí. (Róòmù 2:28; 1 Kọ́r. 15:39, 50) Ó  tún lè tọ́ka sí àwọn tó bá ara wọn tan. Bí àpẹẹrẹ, Jésù “jáde wá láti inú irú-ọmọ Dáfídì lọ́nà ti ẹran ara,” Pọ́ọ̀lù sì sọ pé àwọn Júù jẹ́ “ìbátan [òun] lọ́nà ti ẹran ara.”Róòmù 1:3; 9:3.

7 Àmọ́, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ ní orí 7 jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “ẹran ara” nínú Róòmù 8:4-13. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara” ni àwọn tó ń jẹ́ kí “ìfẹ́ onígbòónára tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀” máa ‘ṣiṣẹ́ nínú àwọn ẹ̀yà ara wọn.’ (Róòmù 7:5) Èyí jẹ́ ká lóye ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tó ń gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara.” Ó sì sọ pé àwọn yìí máa ń “gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹran ara.” Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí àwọn tó gbájú mọ́ bí wọ́n á ṣe tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn. Àwọn yìí máa ń ṣe ohun tó bá ṣáà ti tẹ́ ẹran ara àìpé wọn lọ́rùn, ó lè jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tàbí àwọn nǹkan míì.

8. Kí nìdí tó fi dáa bí Pọ́ọ̀lù ṣe kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nípa rírìn “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara”?

8 O lè máa ronú pé kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara.” Lóde òní, Ọlọ́run ti sọ àwọn Kristẹni di ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì ti kà wọ́n sí olódodo, síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa kó sínú ewu yìí. Ó ṣeni láàánú pé kò sẹ́ni tí kò lè bẹ̀rẹ̀ sí í rìn níbàámu pẹ̀lú ẹran ara. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni kan ní Róòmù jẹ́ ẹrú fún ìfẹ́ ọkàn ara wọn. Lára irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ ni ìṣekúṣe, àjẹkì, àmuyíràá àtàwọn nǹkan míì. Àwọn kan tiẹ̀ tún ń tan àwọn aláìmọ̀kan jẹ. (Róòmù 16:17, 18; Fílí. 3:18, 19; Júúdà 4, 8, 12) Ẹ tún rántí pé ìgbà kan wà tí arákùnrin kan ní Kọ́ríńtì ń fẹ́ ìyàwó bàbá rẹ̀. (1 Kọ́r. 5:1) Èyí mú ká rídìí tí Ọlọ́run fi lo Pọ́ọ̀lù láti kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe ‘gbé èrò inú wọn ka ẹran ara.’Róòmù 8:5, 6.

9. Níbàámu pẹ̀lú Róòmù 8:6, kí ni Pọ́ọ̀lù ò ní ká má ṣe?

9 Ìkìlọ̀ yìí tún ṣe pàtàkì lónìí. Ẹnì kan lè ti máa sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ tí kò bá ṣọ́ra, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé èrò inú rẹ̀ ka ẹran ara. Èyí kò túmọ̀ sí pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan Kristẹni kan ò lè ronú nípa oúnjẹ, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ìgbafẹ́ tàbí ọ̀rọ̀  lọ́kọláya. Kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí. Jésù náà máa ń gbádùn oúnjẹ, ó sì bọ́ àwọn míì. Kódà ó máa ń lọ sí àpèjẹ. Pọ́ọ̀lù náà sì sọ pé kò sóhun tó burú tí tọkọtaya bá ń gbádùn ìbálòpọ̀.

Ṣé ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ fi hàn pé nǹkan tẹ̀mí lò ń rò ṣáá tàbí nǹkan tara ló máa ń gbà ẹ́ lọ́kàn? (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 11)

10. Bó ṣe wà nínú Róòmù 8:5, 6, kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan ‘gbé èrò inú rẹ̀ ka’ nǹkan?

10 Kí wá ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “gbígbé èrò inú ka ẹran ara”? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí “kéèyàn máa ronú ṣáá nípa nǹkan kan, kéèyàn pàfiyèsí sí nǹkan ọ̀hún, kó sì gbájú mọ́ ọn.” Àwọn tó bá ń gbé níbàámu pẹ̀lú ẹran ara máa ń ṣe ohun tára àìpé wọn bá ṣáà ti fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ohun tí ọ̀mọ̀wé kan sọ nípa Róòmù 8:5 ni pé: “Ohun téèyàn gbé èrò inú rẹ̀ kà ni ohun téèyàn sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, téèyàn máa ń lọ́wọ́ sí, tó sì fi ń ṣayọ̀.”

11. Àwọn nǹkan wo ló lè gbà wá lọ́kàn jù?

11 Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà káwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ronú nípa ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì jù lọ. Ṣé kì í ṣe pé “àwọn ohun ti ẹran ara” ló gbà wọ́n lọ́kàn jù? Ó yẹ káwa náà ronú nípa ohun tá a kà sí pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa. Kí la nífẹ̀ẹ́ sí jù, kí lọ̀rọ̀ wa sábà máa ń dá lé? Kí là ń fi ìgbésí ayé wa lé? Ohun táwọn míì kúndùn àtimáa ṣe ni pé kí wọ́n máa gbádùn oríṣiríṣi wáìnì, kí wọ́n máa ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́, kí wọ́n wọ aṣọ aláràbarà, kí wọ́n ṣòwò táá mú èrè rẹpẹtẹ wọlé, kí wọ́n máa gbafẹ́ kiri àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ omi di ọtí wáìnì, Pọ́ọ̀lù náà sì ní kí Tímótì máa mu “wáìnì díẹ̀.” (1 Tím. 5:23; Jòh. 2:3-11) Àmọ́ ṣé ọjọ́ kan ò lè lọ kí Jésù àti Pọ́ọ̀lù má sọ̀rọ̀ ọtí, ṣé ohun tí wọ́n sì fi ń ṣayọ̀ nìyẹn? Ṣé nǹkan tó máa ń wù wọ́n ṣáá nìyẹn, tí wọn ò sì rí nǹkan míì sọ àfi ọ̀rọ̀ wáìnì? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀. Àwa ńkọ́? Kí ló máa ń wù wá jù?

12, 13. Kí nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí ohun tá à ń ‘gbé èrò inú wa kà’?

12 Ó ṣe pàtàkì ká yẹ ara wa wò dáadáa. Kí nìdí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú.” (Róòmù 8:6) Ọ̀rọ̀ ńlá nìyẹn o. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa kú nípa tẹ̀mí báyìí, tó bá sì tún dọjọ́ iwájú, á kú. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò sọ pé tẹ́nì kan bá ń ‘gbé èrò inú rẹ̀ ka àwọn ohun ti ẹran ara,’ ó di dandan kó kú. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣì lè yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ẹ rántí arákùnrin tó fẹ́ ìyàwó bàbá rẹ̀ ní Kọ́ríńtì nígbà yẹn, ṣe ni wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Síbẹ̀, ó ronú pìwà dà, ó jáwọ́ nínú ìwà náà, wọ́n sì gbà á pa dà sínú ìjọ.2 Kọ́r. 2:6-8.

13 Tí arákùnrin tó hùwà tó burú jáì ní Kọ́ríńtì bá lè yí pa dà, ó dájú pé Kristẹni tí kò hùwà tó burú tó yẹn lè yí pa dà. Torí náà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ṣe ìyípadà tó yẹ tó bá ronú lórí ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù pé ikú ló máa gbẹ̀yìn ẹni tó bá ń ‘gbé èrò inú rẹ̀ ka ẹran ara.’

“GBÍGBÉ ÈRÒ INÚ KA Ẹ̀MÍ”

14, 15. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní ká máa gbé èrò inú wa kà? (b) Kí ni “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí” kò túmọ̀ sí?

14 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti kìlọ̀ nípa ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn tó bá ń ‘gbé èrò inú ka ẹran ara,’ ó wá fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” Kí lèèyàn ò bá tún fẹ́ tó kọjá ìyè àti àlàáfíà! Àmọ́ báwo la ṣe lè rí èrè yìí gbà?

15 “Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí” kò túmọ̀ sí pé kẹ́ni náà máa ṣe bí áńgẹ́lì. Kò sì  túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti bó ṣe ń ka Bíbélì nìkan láá máa sọ ṣáá. Ẹ rántí pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni olóòótọ́ míì tó gbáyé nígbà yẹn gbádùn ìgbésí ayé wọn. Wọ́n gbádùn oúnjẹ aládùn, wọ́n mu, wọ́n ṣiṣẹ́, ọ̀pọ̀ wọn ṣègbéyàwó, wọ́n sì ní ìdílé.Máàkù 6:3; 1 Tẹs. 2:9.

16. Kí ló gba Pọ́ọ̀lù lọ́kàn jù?

16 Síbẹ̀, àwọn Kristẹni olóòótọ́ yẹn kò jẹ́ kí àwọn ìgbádùn yìí gbà wọ́n lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ pípa àgọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń ṣe, síbẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ló gba Pọ́ọ̀lù lọ́kàn jù. (Ka Ìṣe 18:2-4; 20:20, 21, 34, 35.) Ohun tó sì ní káwọn ará tó wà ní Róòmù máa ṣe nìyẹn. Èyí fi hàn pé ìjọsìn Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù gbájú mọ́. Ó yẹ káwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn.Róòmù 15:15, 16.

17. Báwo ni ìgbésí ayé wa ṣe máa rí tá a bá ń ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí’?

17 Ère wo la máa rí tá a bá gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí? Róòmù 8:6 sọ pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ká jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ká sì máa ṣe ohun tó wu Jèhófà. Ó dájú pé tá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa, ìgbésí ayé wa máa dùn bí oyin nísinsìnyí. Àá sì tún wà láàyè títí láé, ì báà jẹ́ lọ́run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.

18. Báwo la ṣe ń gbádùn àlàáfíà torí pé à ń ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí’?

18 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa gbólóhùn tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí . . . àlàáfíà.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọ́kàn sókè lónìí, tí wọ́n sì ń wá ohun táá mú kọ́kàn wọn balẹ̀. Àmọ́ àwa ti ń gbádùn àlàáfíà, ọkàn wa sì balẹ̀. Lára ohun tó ń mú kọ́kàn wa balẹ̀ ni pé a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà lè wà nínú ìdílé wa, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ. A mọ̀ pé aláìpé làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Torí náà, àìgbọ́ra-ẹni-yé lè wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, a máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó sọ pé: ‘Wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ.’ (Mát. 5:24) Ó túbọ̀ máa rọrùn fún wa láti wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa tá a bá ń rántí pé “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà” ni gbogbo wa ń sìn.Róòmù 15:33; 16:20.

19. Tá a bá ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí,’ àlàáfíà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo la máa gbádùn?

19 Tá a bá ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí,’ a máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Èyí sì ju àlàáfíà èyíkéyìí tá a lè ní lọ. Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ìmúṣẹ rẹ̀ gbòòrò gan-an lónìí, ó ní, Jèhófà yóò ‘pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé e mọ́ ní alaafia pípé, nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.’Aísá. 26:3, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀; ka Róòmù 5:1.

20. Kí nìdí tá a fi mọyì ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù orí 8?

20 Yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí a nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ó yẹ ká dúpẹ́ pé Jèhófà fún wa ní ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní nínú Róòmù orí 8. A ti rí i pé kò yẹ ká jẹ́ kí àwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a rí ọgbọ́n tó wà nínú bá a ṣe ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” Èrè tá a máa rí gbà máa wà títí láé torí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”Róòmù 6:23.