Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  December 2016

Ọlọ́run Dá Wa Sílẹ̀ Nípasẹ̀ Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí

Ọlọ́run Dá Wa Sílẹ̀ Nípasẹ̀ Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí

‘Ẹ̀ṣẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀gá lórí yín, níwọ̀n bí ẹ ti wà lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.’RÓÒMÙ 6:14.

ORIN: 2, 61

1, 2. Báwo ni Róòmù 5:12 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

KÁ SỌ pé o fẹ́ máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ dáadáa, tá a sì máa ń lò, ṣé Róòmù 5:12 máa tètè wá sí ẹ lọ́kàn? Bóyá wàá lè rántí iye ìgbà tó o ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ yẹn fáwọn èèyàn. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”

2 Léraléra la lo ẹsẹ yẹn nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bó o ṣe ń lo ìwé yìí láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ àtàwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kó o ka Róòmù 5:12 tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé nínú orí kẹta. Ó ṣeé ṣe kó o tún kà á tẹ́ ẹ bá ń jíròrò nípa ìràpadà ní orí karùn-ún àti nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò nípa ipò tí àwọn òkú wà ní orí kẹfà. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti ronú nípa bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe kan àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà, ìwà rẹ àti ọjọ́ ọ̀la rẹ?

3. Kí ló yẹ kí gbogbo wa gbà pé a jẹ́?

3 Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ojoojúmọ́ la sì máa ń ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run máa ń rántí pé  erùpẹ̀ ni wá, ó sì ń fàánú hàn sí wa. (Sm. 103:13, 14) Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù gbà, ó ní ká máa bẹ Jèhófà pé: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.” (Lúùkù 11:2-4) Torí náà, kò yẹ ká tún máa banú jẹ́ lórí àwọn àṣìṣe tí Ọlọ́run ti dárí ẹ̀ jì wá. Síbẹ̀, ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń ronú nípa ohun tó ń mú kí Ọlọ́run dárí jì wá.

ỌLỌ́RUN Ń DÁRÍ JÌ WÁ NÍPASẸ̀ INÚ RERE ÀÌLẸ́TỌ̀Ọ́SÍ

4, 5. (a) Kí ló mú ká túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú Róòmù 5:12? (b) Kí ni “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” tí Róòmù 3:24 sọ?

4 Pọ́ọ̀lù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ká túbọ̀ lóye Róòmù 5:12 nínú àwọn orí tó ṣáájú àtàwọn èyí tó tẹ̀ lé e, ní pàtàkì nínú orí kẹfà. Àwọn orí yìí máa jẹ́ ká lóye bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá. Nínú orí kẹta, ó sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ . . . , a sì ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.” (Róòmù 3:23, 24) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí”? Ìwé ìwádìí kan sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí “oore tá a ṣe fún ẹnì kan láìretí ohunkóhun pa dà lọ́dọ̀ rẹ̀.” Kì í ṣe ohun tá a ṣiṣẹ́ fún, a ò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí i.

5 Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ John Parkhurst sọ pé: “Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tàbí Kristi, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run àti Kristi fi hàn sí aráyé tàbí oore tí wọ́n ṣe láti gba aráyé là.” Èyí mú kó ṣe kedere pé “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” tá a lò nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun bá a mu wẹ́kú. Àmọ́, báwo ni Ọlọ́run ṣe ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa? Báwo nìyẹn ṣe kan ọjọ́ ọ̀la rẹ àti àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run? A máa rí i bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú.

6. Báwo ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ṣe lè ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní?

6 Ádámù ni “ènìyàn kan” tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tipasẹ̀ rẹ̀ “wọ ayé.” Torí náà, ‘nípa àṣemáṣe ọkùnrin yẹn ni ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.’ Pọ́ọ̀lù tún fi kún un pé a rí ọ̀pọ̀ yanturu inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọ́run] gbà “nípasẹ̀ ènìyàn kan, Jésù Kristi.” (Róòmù 5:12, 15, 17) Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí sì ti mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún aráyé. Bí àpẹẹrẹ, “nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan [Jésù], ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” Ó ṣe kedere pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run máa fún wa ní ‘ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jésù Kristi.’Róòmù 5:19, 21.

7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìràpadà jẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí?

7 Kì í ṣe ọ̀ranyàn pé kí Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti rà wá pa dà. Ó ṣe tán, aláìpé ni wá, a ò sì yẹ lẹ́ni tó yẹ kí Ọlọ́run àti Jésù rà pa dà. Síbẹ̀, ìràpadà yìí ló mú kí ìdáríjì ṣeé ṣe. Torí náà, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbáà ló jẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jì wá tó sì tún fún wa láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ó yẹ ká mọyì ẹ̀bùn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ká sì jẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé wa.

FI HÀN PÉ O MỌYÌ INÚ RERE ÀÌLẸ́TỌ̀Ọ́SÍ ỌLỌ́RUN

8. Èrò tí kò dáa wo làwọn kan ní nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń dá?

8 Torí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá, a máa ń ṣàṣiṣe, a sì máa ń dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, kò ní bójú mu ká máa dẹ́ṣẹ̀ ká sì máa ronú pé Ọlọ́run máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa. A sì lè máa sọ lọ́kàn wa pé: ‘Tí mo bá ṣẹ̀, kódà kó jẹ́ ẹ̀sẹ̀ tó burú jáì, kò yẹ kí n da ara mi láàmú torí Jèhófà máa dárí jì mí.’ Ó ṣeni láàánú pé àwọn Kristẹni kan nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì náà ronú bẹ́ẹ̀. (Ka Júúdà 4.) Lóòótọ́, a lè má sọ irú  ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ jáde, àmọ́ irú èrò bẹ́ẹ̀ lè wà lọ́kàn wa, àwọn míì sì lè mú ká máa ronú bẹ́ẹ̀.

9, 10. Báwo ni Ọlọ́run ṣe gba Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni ìgbàanì sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?

9 Èrò kan wà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé a ò gbọ́dọ̀ gbà láyè rárá. Èrò náà ni pé: ‘Ọlọ́run náà mọ̀. Kò ní ka ìwà burúkú mi sí.’ Àmọ́, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ronú bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni ti “kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀.” (Ka Róòmù 6:1, 2.) Kí nìdí tó fi sọ pé wọ́n ti “kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀” nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè?

10 Ọlọ́run mú kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni ìgbàanì jàǹfààní látinú ìràpadà. Nípasẹ̀ ìràpadà, ó dárí jì wọ́n, ó fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, ó sì sọ wọ́n dọmọ. Èyí mú kí wọ́n nírètí láti lọ sí ọ̀run. Tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, ó ní wọ́n jẹ́ ‘òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì wà láàyè tí wọ́n sì ń sin Ọlọ́run. Ó fi Jésù ṣe àpẹẹrẹ, torí Jésù kú nínú ẹran ara àmọ́ Ọlọ́run jí i dìde sí ọ̀run, ó sì fún un ní àìleèkú. Torí náà, ikú kò ní agbára lórí Jésù mọ́. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró torí wọ́n ka ara wọn sí ‘òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ alààyè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Róòmù 6:9, 11) Ìgbésí ayé wọn ti yàtọ̀. Wọ́n jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀. Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n kú ní ti ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀.

11. Báwo ni àwa tá a ní ìrètí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè ṣe jẹ́ ‘òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀’?

11 Àwa Kristẹni tòde òní ńkọ́? Ká tó di Kristẹni, a máa ń dẹ́ṣẹ̀, kódà a lè má mọ bí ohun tá à ń ṣe ṣe burú tó lójú Ọlọ́run. Ṣe la dà bí “ẹrú fún ìwà àìmọ́ àti ìwà àìlófin.” Torí náà, a lè sọ pé a “jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:19, 20) Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, a ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wa, a ya ara wa sí mímọ́ a sì ṣe ìrìbọmi. Àtìgbà yẹn ló ti ń wù wá láti jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà” sí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà Ọlọ́run. Ní báyìí, Ọlọ́run ti “dá [wa] sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀” a sì ti “di ẹrú fún òdodo.” (Róòmù 6:17, 18) Torí náà, a lè sọ pé àwa náà jẹ́ ‘òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀.’

12. Ìpinnu wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ṣe?

12 Fojú inú wò ó bíi pé ìwọ ni Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nínú àwọn ara kíkú yín, tí ẹ ó fi máa ṣègbọràn sí àwọn ìfẹ́-ọkàn wọn.” (Róòmù 6:12) Tá a bá ń fi àìpé kẹ́wọ́, tá a wá ń ṣe ohun tó wù wá, ńṣe là ń “jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso” wa. Ọwọ́ wa ló wà tá a bá fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa ṣàkóso wa tàbí kó má ṣàkóso wa. Ìbéèrè náà ni pé, Ṣé ìwọ fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa ṣàkóso rẹ? Á dáa kó o bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń jẹ́ kí àìpé mú kí n máa ro èròkerò kí n sì jẹ́ kó tì mí ṣe ohun tí kò dáa? Ṣé mo ti di òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀? Ṣé mo wà láàyè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù?’ Ìdáhùn wa sinmi lórí bóyá a mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sí wa tàbí a ò mọyì rẹ̀.

A LÈ BORÍ Ẹ̀ṢẸ̀

13. Kí ló mú kó dá wa lójú pé a lè borí ẹ̀ṣẹ̀?

13 Àwọn èèyàn Jèhófà ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tí wọ́n ń hù kí wọ́n tó mọ Jèhófà. Wọ́n ti wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ìwà kan “tí ń tì [wọ́n] lójú nísinsìnyí,” ni wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀, àwọn ìwà yìí sì lè yọrí sí ikú. (Róòmù 6:21) Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti yí pa dà. Àwọn ará Kọ́ríńtì náà ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn pé, tẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ abọ̀rìṣà, olè, ọ̀mùtípara, wọ́n ń ṣe panṣágà,  ọkùnrin ń bá ọkùnrin lò pọ̀, obìnrin ń bá obìnrin lò pọ̀, wọ́n sì ń hu àwọn ìwàkiwà míì. Síbẹ̀, Ọlọ́run ‘wẹ̀ wọ́n mọ́,’ ó sì ‘sọ wọ́n di mímọ́.’ (1 Kọ́r. 6:9-11) Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan ní ìjọ Róòmù náà ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀, ìyẹn ló mú kí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn pé kí wọ́n ‘má ṣe máa bá a lọ ní jíjọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ bí àwọn ohun ìjà àìṣòdodo, ṣùgbọ́n kí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún Ọlọ́run bí àwọn tí ó wà láàyè láti inú òkú, àti àwọn ẹ̀yà ara wọn pẹ̀lú fún Ọlọ́run bí àwọn ohun ìjà òdodo.’ (Róòmù 6:13) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé tí wọ́n bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n á máa jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.

14, 15. Kí ló yẹ ká bi ara wa tá a bá fẹ́ jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà”?

14 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí náà jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Bíi tàwọn ará Kọ́ríńtì, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀, a sì ti ‘wẹ̀ wọ́n mọ́.’ Bó ti wù kí ipò rẹ burú tó tẹ́lẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé, báwo ni àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe rí báyìí? Ní báyìí tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ti wà fún wa, ṣé o ti pinnu pé o ò ní jọ̀wọ́ ‘àwọn ẹ̀yà ara rẹ fún ẹ̀ṣẹ̀’ mọ́? Ṣé o sì ti pinnu pé wàá ‘jọ̀wọ́ ara rẹ fún Ọlọ́run bí àwọn tí ó wà láàyè láti inú òkú’?

15 Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má di pé a mọ̀ọ́mọ̀ ń lọ́wọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, irú èyí táwọn ará kan ní Kọ́ríńtì dá kí wọ́n tó di Kristẹni. Ó ṣe pàtàkì ká fi ìmọ̀ràn yìí sílò tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la ti tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, tá ò sì fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ ‘jẹ ọ̀gá lórí wa.’ Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ṣe pàtàkì ká bi ara wa pé, ṣé mo ti pinnu pé màá jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà” kí n sì sa gbogbo ipá mí láti yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ táwọn kan kà sí ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké?Róòmù 6:14, 17.

16. Báwo la ṣe mọ̀ pé jíjẹ́ Kristẹni ju pé kéèyàn má ṣe lọ́wọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo?

16 Ẹ jẹ́ ká ronú nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó dá wa lójú pé Pọ́ọ̀lù ò lọ́wọ́ sí irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo tá a mẹ́nu bà nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9-11. Síbẹ̀, ó jẹ́wọ́ pé òun máa ń ṣẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí ohun tí mo ń ṣe ni èmi kò mọ̀. Nítorí ohun tí mo ń fẹ́, èyí ni èmi kò fi ṣe ìwà hù; ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni èmi ń ṣe.” (Róòmù 7:14, 15) Èyí fi hàn pé àwọn nǹkan míì wà tí Pọ́ọ̀lù kà sí ẹ̀ṣẹ̀, tó sì ń tiraka láti jáwọ́ nínú rẹ̀. (Ka Róòmù 7:21-23.) Ẹ jẹ́ káwa náà ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, ká pinnu láti jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà.”

17. Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ olóòótọ́?

17 Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ jíjẹ́ olóòótọ́ yẹ̀ wò. Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. (Ka Òwe 14:5; Éfésù 4:25.) Sátánì ni “baba irọ́,” Ananíà àti ìyàwó rẹ̀ sì kú torí pé wọ́n parọ́. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ fara wé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, torí náà, a ò ní máa parọ́. (Jòh. 8:44; Ìṣe 5:1-11) Àmọ́, ti pé ẹnì kan ò parọ́ kò túmọ̀ sí pé ẹni náà jẹ́ olóòótọ́. Tá a bá mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, a máa jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.

18, 19. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ kọjá kéèyàn má parọ́?

18 Kéèyàn parọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́. Kì í ṣe irọ́ pípa nìkan ni Jèhófà fẹ́ ká yẹra fún, àmọ́ ó fẹ́ ká yẹra fún gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwà àìṣòótọ́. Ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.” Ó wá sọ ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n á fi jẹ́ mímọ́. Ó ní: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ jalè, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ tanni jẹ, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣèké, ẹnikẹ́ni sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.” (Léf. 19:2, 11) Ó ṣeni láàánú pé ẹnì kan  ti lè pinnu pé òun ò ní parọ́ mọ́, síbẹ̀ kó máa tan àwọn míì jẹ.

Ṣé a ti pinnu pé a ò ní máa parọ́, a ò sì ní máa tanni jẹ?(Wo ìpínrọ̀ 19)

19 Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè sọ fún ọ̀gá rẹ̀ tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé òun ò ní wá síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ kejì tàbí pé òun máa tètè kúrò torí pé òun fẹ́ lọ rí dókítà. Ó sì lè jẹ́ pé ó kàn fẹ́ lọ ra oògùn tàbí kó fẹ́ lọ sanwó nílé ìwòsàn. Àmọ́ ohun tó fẹ́ ṣe gan-an ni pé ó fẹ́ lọ síbì kan tàbí kó fẹ́ gbé ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ síbi ìgbafẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè yà nílé ìwòsàn lóòótọ́, àmọ́ ṣé a lè sọ pé ó sọ òótọ́ délẹ̀délẹ̀? Àbí ṣe ló tàn wọ́n jẹ? Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó máa ń dìídì tan àwọn míì jẹ. Ìdí tí ọ̀pọ̀ wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò fẹ́ kí wọ́n bá àwọn wí tàbí torí kí wọ́n lè rẹ́ àwọn míì jẹ. Kódà, tá ò bá tiẹ̀ parọ́, ká má gbàgbé pé Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ tanni jẹ.” Tún ronú nípa ohun tó wà nínú Róòmù 6:19 tó sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín nísinsìnyí bí ẹrú fún òdodo pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́ níwájú.”

20, 21. Kí ló yẹ kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run sún wa ṣe?

20 Tá a bá ń ronú nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, a máa yẹra fáwọn ìwà bí ìṣekúṣe, ìmutípara àtàwọn ìwà míì táwọn ará Kọ́ríńtì ń hù kí wọ́n tó di Kristẹni. Àmọ́, àwọn ìwà yìí nìkan kọ́ la máa yẹra fún. Tá a bá mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kì í ṣe ìṣekúṣe nìkan la máa yẹra fún, a ò ní máa wo ìwòkuwò. Tá a bá jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara wa bí ẹrú fún òdodo, kì í ṣe pé a máa yẹra fún ìmutípara nìkan, a ò tiẹ̀ ní dé bèbè àtimu ọtí yó. Ó lè gba pé ká sapá gan-an ká tó lè borí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, àmọ́ ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè borí.

21 Ó yẹ ká pinnu pé a máa yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì àtèyí táwọn èèyàn kà sí ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké. Òótọ́ ni pé kò sí béèyàn ṣe mọ̀ ọ́n rìn, kórí má mì, síbẹ̀ a lè sapá láti borí ẹ̀ṣẹ̀ bí Pọ́ọ̀lù náà ti ṣe. Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nínú àwọn ara kíkú yín, tí ẹ ó fi máa ṣègbọràn sí àwọn ìfẹ́-ọkàn wọn.” (Róòmù 6:12; 7:18-20) Bá a ṣe ń sapá láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ṣe là ń fi hàn pé a mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi.

22. Èrè wo la máa rí tá a bá fi hàn pé a mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run?

22 Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, Ọlọ́run ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, yóò sì máa dárí jì wá nìṣó. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, ká yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ táwọn kan kà sí ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ èrè tá a máa rí gbà tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Nísinsìnyí, nítorí pé a ti dá yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ ti di ẹrú fún Ọlọ́run, ẹ ń so èso yín lọ́nà ìjẹ́mímọ́, ìyè àìnípẹ̀kun sì ni òpin rẹ̀.”Róòmù 6:22.