Kí nìdí tí ohun tí Mátíù àti Lúùkù sọ nípa ìgbà tí Jésù wà ní kékeré fi yàtọ̀ síra?

Ohun tí Mátíù sọ nípa ìgbà tí Jésù wà ní kékeré yàtọ̀ díẹ̀ sí ohun tí Lúùkù sọ. Ìdí sì ni pé àkọsílẹ̀ Mátíù dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù, àmọ́ àkọsílẹ̀ Lúùkù dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màríà.

Àkọsílẹ̀ Mátíù sọ nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù. Ó sọ nípa ohun tí Jósẹ́fù pinnu láti ṣe nígbà tó gbọ́ pé Màríà lóyún. Ó tún sọ nípa ìgbà tí áńgẹ́lì kan fara hàn án lójú àlá, tó sì ṣàlàyé bí Màríà ṣe lóyún àtohun tí Jósẹ́fù ṣe lẹ́yìn náà. (Mát. 1:19-25) Mátíù tún sọ̀rọ̀ nípa àlá kan tí Jósẹ́fù lá níbi tí áńgẹ́lì kan ti sọ fún un pé kó sá lọ sí Íjíbítì àti bó ṣe kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Íjíbítì. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún sọ nípa àlá míì tí Jósẹ́fù lá níbi tí áńgẹ́lì kan ti sọ fún un pé kó pa dà sílẹ̀ Ísírẹ́lì àti bó ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tún sọ ohun tó mú kó pinnu pé Násárétì lòun àti ìdílé òun á máa gbé. (Mát. 2:13, 14, 19-23) Nínú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ Ìwé Ìhìn Rere Mátíù, ẹ̀ẹ̀meje ni Mátíù dárúkọ Jósẹ́fù, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mẹrin péré ló dárúkọ Màríà.

Lọ́wọ́ kejì, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màríà ni àkọsílẹ̀ Lúùkù dá lé. Ó sọ nípa ìgbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì wá bá Màríà, ìgbà tí Màríà lọ kí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Èlísábẹ́tì àti bí Màríà ṣe yin Jèhófà. (Lúùkù 1:26-56) Lúùkù tún ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Síméónì sọ fún Màríà nípa ìyà tó máa jẹ Jésù lọ́jọ́ iwájú. Kódà nígbà tí Lúùkù ń sọ nípa ìgbà tí Jósẹ́fù kó ìdílé rẹ̀ lọ sí tẹ́ńpìlì nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ọ̀rọ̀ Màríà ni Lúùkù mẹ́nu kàn, kì í ṣe ti Jósẹ́fù. Lúùkù tún jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni Màríà ń pa mọ́ sínú ọkàn rẹ̀. (Lúùkù 2:19, 34, 35, 48, 51) Nínú orí méjì àkọ́kọ́ nínú Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù, ìgbà méjìlá ni Lúùkù dárúkọ Màríà, àmọ́ ìgbà mẹ́ta péré ló dárúkọ Jósẹ́fù. Torí náà, àkọsílẹ̀ Mátíù sọ púpọ̀ nípa ohun tí Jósẹ́fù ṣe, àmọ́ àkọsílẹ̀ Lúùkù sọ púpọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Màríà ṣe.

Bákan náà, bí àkọsílẹ̀ Mátíù ṣe to ìlà ìdílé Jésù yàtọ̀ sí ti Lúùkù. Mátíù to ìlà ìdílé Jésù látọ̀dọ̀ Jósẹ́fù, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì torí pé Jósẹ́fù gba Jésù ṣọmọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jósẹ́fù jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì láti ìlà idílé Sólómọ́nì. (Mát. 1:6, 16) Àmọ́ Lúùkù to ìlà ìdílé Jésù látọ̀dọ̀ Màríà, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà àbínibí láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì torí pé ó jẹ́ ọmọ Dáfídì “lọ́nà ti ẹran ara.” (Róòmù 1:3) Kí nìdí? Ìdí ni pé Màríà jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì láti ìlà ìdílé Nátánì ọmọ Dáfídì. (Lúùkù 3:31) Àmọ́ kí nìdí tí Lúùkù fi pe Jósẹ́fù ní ọmọ Hélì dípò kó pe Màríà ní ọmọ Hélì? Ìdí ni pé orúkọ àwọn ọkùnrin ni wọ́n máa ń tò sínú ìlà ìdílé. Torí náà, nígbà tí Lúùkù pe Jósẹ́fù ní ọmọ Hélì, ohun tó ń sọ ni pé Jósẹ́fù ni ọkọ ọmọbìnrin Hélì.​—Lúùkù 3:23.

Bí Mátíù àti Lúùkù ṣe to ìlà ìdílé Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé àtọmọdọ́mọ Dáfídì ni Jésù, kódà àwọn Farisí àtàwọn Sadusí gan-an ò jiyàn rẹ̀. Àkọsílẹ̀ tí Mátíù àti Lúùkù ṣe nípa ìlà ìdílé Jésù wà lára ohun tó mú ká nígbàgbọ́, ó sì tún jẹ́ ká gbà pé gbogbo ìlérí Jèhófà máa ṣẹ.