Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ṣé Wàá Lè Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà?

Ṣé Wàá Lè Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà?

“Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù.”​—JÁK. 5:8.

ORIN: 78, 139

1, 2. (a) Kí ló lè mú ká béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó”? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ ṣe mú kí ọkàn wa balẹ̀?

WÒLÍÌ Aísáyà àti Hábákúkù béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Yóò ti pẹ́ tó?” (Aísá. 6:11; Háb. 1:⁠2) Bákan náà, ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọba Dáfídì béèrè nínú Sáàmù 13 pé: “Yóò ti pẹ́ tó?” (Sm. 13:​1, 2) Kódà Jésù Kristi Olúwa wa náà béèrè ìbéèrè yìí nígbà kan tó ń bá àwọn èèyàn tí kò nígbàgbọ́ sọ̀rọ̀. (Mát. 17:17) Torí náà, kò burú tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwa náà béèrè irú ìbéèrè yìí.

2 Kí ló lè mú ká béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó”? Ó lè jẹ́ torí pé wọ́n fẹ̀tọ́ wa dù wá tàbí torí pé wọ́n hùwà àìdáa sí wa. Ó sì lè jẹ́ torí àìsàn tàbí ara tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ torí ọjọ́ ogbó. Bákan náà, ó lè jẹ́ àwọn ìṣòro tá à ń kojú nítorí bí nǹkan ṣe le koko lásìkò tá a wà yìí. (2 Tím. 3:⁠1) Yàtọ̀ síyẹn, ìwàkiwà táwọn tó yí wa ká ń hù lè máa ni wá lára. Ohun yòówù kó jẹ́, ọkàn wa balẹ̀ pé kò burú tá a bá béèrè ìbéèrè yẹn torí pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ náà ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ò sì bínú sí wọn.

3. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá bára wa nínú ipò tó nira?

 3 Tá a bá bára wa nírú àwọn ipò yìí, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù tó jẹ́ àbúrò Jésù sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Nítorí náà, ẹ mú sùúrù, ẹ̀yin ará, títí di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa.” (Ják. 5:⁠7) Ó dájú nígbà náà pé gbogbo wa la nílò sùúrù. Àmọ́ kí ló túmọ̀ sí pé ká ní sùúrù?

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ PÉ KÉÈYÀN NÍ SÙÚRÙ?

4, 5. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ní sùúrù? (b) Àpèjúwe wo ni Jákọ́bù lò ká lè mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn ní sùúrù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìpamọ́ra tàbí sùúrù wà lára àwọn ànímọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ kéèyàn ní. Láìjẹ́ pé Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́, àwa èèyàn aláìpé ò lè ní sùúrù débi tó yẹ. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká ní sùúrù, tá a bá sì ní sùúrù, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ṣe sùúrù, a tún ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ìfẹ́ yìí á sì máa lágbára sí i. Àmọ́ tá ò bá kí í ní sùúrù, ṣe ni ìfẹ́ yẹn á máa jó rẹ̀yìn. (1 Kọ́r. 13:4; Gál. 5:22) Ẹni bá ní sùúrù máa ní àwọn ànímọ́ dáadáa míì. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó ní sùúrù á ní ìfaradà. Ìfaradà máa ń mú ká ní àmúmọ́ra kódà bí nǹkan bá tiẹ̀ nira, á sì dá wa lójú pé nǹkan ṣì máa dáa. (Kól. 1:11; Ják. 1:​3, 4) Ẹni tó ní sùúrù kì í gbẹ̀san, ó máa ń rọ́jú, kì í sì í bọ́hùn bó ti wù kí ìṣòro náà le tó. Bákan náà, Bíbélì rọ̀ wá pé ká ní ẹ̀mí ìdúródeni. Kókó yìí ni Jákọ́bù tẹnu mọ́ nínú Jákọ́bù 5:7, 8. (Kà á.)

5 Kí nìdí tó fi pọn dandan pé ká ṣe sùúrù, ká sì dúró de Jèhófà? Kí ọ̀rọ̀ náà lè yé wa, Jákọ́bù lo àpèjúwe àgbẹ̀. Àgbẹ̀ kan lè ṣiṣẹ́ kára láti fún irúgbìn, àmọ́ kò lè mú kójò rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè mú kí ohun tó gbìn yára hù. Torí náà, ṣe ló máa mú sùúrù títí dìgbà tí irè oko náà máa tó kórè. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ nǹkan wà tá ò lè ṣe, àfi ká dúró dìgbà tí Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Máàkù 13:​32, 33; Ìṣe 1:⁠7) Bíi tàwọn àgbẹ̀, àwa náà ní láti ṣe sùúrù.

6. Kí la rí kọ́ lára wòlíì Míkà?

6 Bí àwọn nǹkan ṣe rí lásìkò wa yìí jọ bó ṣe rí lásìkò wòlíì Míkà. Àsìkò tí Ọba Áhásì tó jẹ́ ọba burúkú wà lórí oyè ni Míkà gbáyé, onírúurú ìwà burúkú ló sì kún ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àní sẹ́, Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn náà ti gbówọ́ nínú ìwà ibi. (Ka Míkà 7:​1-3.) Míkà mọ̀ pé kò sóhun tí òun lè ṣe nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Torí náà, ó sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi. Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.” (Míkà 7:7) Bíi ti Míkà, àwa náà gbọ́dọ̀ ní “ẹ̀mí ìdúródeni.”

7. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní bá a ṣe ń dúró de Jèhófà pé kó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ?

7 Tá a bá nígbàgbọ́ bíi ti Míkà, ṣe lá máa wù wá láti dúró de Jèhófà. Ọ̀rọ̀ wa yàtọ̀ pátápátá sí ti ẹlẹ́wọ̀n kan tó kàn ń dúró de ọjọ́ ikú rẹ̀. Kò sí ohun tó lè ṣe ju pé kó dúró de ọjọ́ náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù ú pé kóun kú. Àmọ́, kì í ṣe bọ́rọ̀ tiwa ṣe rí nìyẹn. Ó máa ń wù wá láti dúró de Jèhófà torí pé ó dá wa lójú pé á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Èyí máa ṣẹlẹ̀ ní àsìkò tó pinnu gẹ́lẹ́, ìyẹn sì ni àsìkò tó dáa jù! Ìdí nìyẹn tá a fi ń ‘fara dà á ní kíkún, pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ìdùnnú.’ (Kól. 1:11, 12) Torí náà, tá a bá sọ pé à ń dúró de Jèhófà, àmọ́ tá à ń ráhùn, tá a sì ń fapá jánú pé Jèhófà ò tètè gbé  ìgbésẹ̀, inú Jèhófà ò ní dùn sí wa.​—Kól. 3:12.

ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ NÍ SÙÚRÙ

8. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń ronú nípa àwọn olóòótọ́ ìgbàanì?

8 Á túbọ̀ rọrùn fún wa láti ní ẹ̀mí ìdúródeni tá a bá ń ronú nípa àwọn olóòótọ́ tó fi sùúrù dúró de Jèhófà láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Róòmù 15:⁠4) Bá a ṣe ń ronú lórí àpẹẹrẹ wọn, á dáa ká fi àwọn kókó yìí sọ́kàn. Àkọ́kọ́, bí wọ́n ṣe dúró pẹ́ tó, ìkejì, ohun tó mú kí wọ́n ní sùúrù, àti ìkẹta, àwọn ìbùkún tí wọ́n rí torí pé wọ́n ní sùúrù.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Ábúráhámù fi dúró kó tó ní àwọn ọmọ-ọmọ, ìyẹn Ísọ̀ àti Jékọ́bù (Wo ìpínrọ̀ 9 àti 10)

9, 10. Ọdún mélòó ni Ábúráhámù àti Sárà fi dúró kí ìlérí Jèhófà tó ṣẹ?

9 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ábúráhámù àti Sárà. Wọ́n wà lára “àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti fi sùúrù hàn,” ó rí ìlérí tí Jèhófà ṣe fún un gbà pé òun máa bù kún un, á sì ní àwọn àtọmọdọ́mọ. (Héb. 6:​12, 15) Kí nìdí tí Ábúráhámù fi ní láti mú sùúrù? Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ó máa gba àkókò kí ìlérí náà tó lè nímùúṣẹ. Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Nísàn 14, 1943 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tóun àti ìyàwó rẹ̀ àti agboolé wọn sọdá Odò Yúfírétì tí wọ́n sì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni Ábúráhámù fi dúró kí Sárà tó bí Ísákì lọ́dún 1918 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Lẹ́yìn náà, ó tún dúró fún ọgọ́ta [60] ọdún kó tó ní àwọn ọmọ-ọmọ, ìyẹn Ísọ̀ àti Jékọ́bù lọ́dún 1858 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.​—Héb. 11:9.

10 Báwo ni ilẹ̀ tí Ábúráhámù jogún ṣe pọ̀ tó? Bíbélì sọ pé: “[Jèhófà] kò fún  [Ábúráhámù] ní ohun ìní kankan tí ó ṣeé jogún nínú rẹ̀, rárá o, kì í tilẹ̀ ṣe ìbú ẹsẹ̀ kan; ṣùgbọ́n ó ṣèlérí láti fi í fún un gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, àti lẹ́yìn rẹ̀ fún irú-ọmọ rẹ̀, nígbà tí kò tíì ní ọmọ kankan.” (Ìṣe 7:5) Nǹkan bí irínwó ó lé ọgbọ̀n [430] ọdún lẹ́yìn tí Ábúráhámù sọdá Yúfírétì ni Ọlọ́run tó sọ àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di orílẹ̀-èdè kan, táá gba Ilẹ̀ Ìlérí náà.​—Ẹ́kís. 12:40-42; Gál. 3:17.

11. Kí nìdí tí Ábúráhámù fi ní sùúrù, báwo sì ni Jèhófà ṣe máa bù kún un?

11 Kí nìdí tí Ábúráhámù fi ní sùúrù tó bẹ́ẹ̀? Ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà ló jẹ́ kó ní sùúrù. (Ka Hébérù 11:8-12.) Tayọ̀tayọ̀ ni Ábúráhámù fi dúró de Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí ló ṣẹ lójú rẹ̀. Ẹ wo bí inú Ábúráhámù ṣe máa dùn tó nígbà tó bá jíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé! Á yà á lẹ́nu pé àwọn ibi tí wọ́n ti sọ ìtàn ìgbésí ayé òun àti tàwọn àtọmọdọ́mọ òun pọ̀ gan-an nínú Bíbélì. * Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó bá mọ̀ pé òun kó ipa ribiribi nínú bí Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa mú irú-ọmọ kan jáde! Ó dájú pé inú rẹ̀ á dùn pé òun dúró de Jèhófà.

12, 13. Kí nìdí tó fi yẹ kí Jósẹ́fù ní sùúrù, báwo ló sì ṣe hùwà?

12 Jósẹ́fù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù náà ní ẹ̀mí ìdúródeni. Wọ́n hùwà ìkà tó burú jáì sí i. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà á sóko ẹrú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. Lẹ́yìn náà, ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ parọ́ mọ́ ọn pé ó fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀, wọ́n sì tìtorí ẹ̀ jù ú sẹ́wọ̀n. (Jẹ́n. 39:​11-20; Sm. 105:​17, 18) Ibi ni wọ́n fi ń san gbogbo rere tó ń ṣe, wọ́n fìyà jẹ ẹ́ dípò kí wọ́n máa yìn ín. Ọdún mẹ́tàlá [13] lẹ́yìn náà, gbogbo nǹkan yí pa dà bìrí. Wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n sì sọ ọ́ di igbá kejì Ọba Íjíbítì.​—Jẹ́n. 41:​14, 37-43; Ìṣe 7:​9, 10.

13 Ṣé ìwà ìkà tí wọ́n hù sí Jósẹ́fù mú kó di àwọn èèyàn náà sínú? Ṣẹ́yẹn mú kí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà jó rẹ̀yìn? Rárá. Kí ló mú kí Jósẹ́fù lè fi sùúrù dúró de Jèhófà? Ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà ló jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ó rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ̀. Èyí hàn nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀ sọ, ó ní: “Ẹ má fòyà, nítorí èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí? Ní tiyín, ẹ ní ibi lọ́kàn sí mi. Ọlọ́run ní in lọ́kàn fún rere, fún ète ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ti òní yìí, láti pa àwọn ènìyàn púpọ̀ mọ́ láàyè.” (Jẹ́n. 50:​19, 20) Kò sí àní-àní pé Jósẹ́fù gbà pé ó bọ́gbọ́n mu bí òun ṣe dúró de Jèhófà.

14, 15. (a) Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa bí Dáfídì ṣe mú sùúrù? (b) Kí ló mú kí Dáfídì lè dúró de Jèhófà?

14 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn hùwà àìdáa sí Ọba Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtikékeré ni Jèhófà ti yàn án pé òun ló máa jọba, síbẹ̀ nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni Dáfídì fi dúró kó tó di ọba ní Júdà. (2 Sám. 2:​3, 4) Láàárín àkókò yìí, Ọba Sọ́ọ̀lù tó ti di aláìṣòótọ́ ń wá bó ṣe máa gbẹ̀mí Dáfídì. * Èyí ló mú kí Dáfídì máa sá kiri nínú aginjù, àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó sá lọ sórílẹ̀-èdè míì. Kódà lẹ́yìn  tí wọ́n pa Sọ́ọ̀lù lójú ogun, Dáfídì ṣì ní láti dúró fún odindi ọdún méje kó tó di ọba gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì.​—2 Sám. 5:4, 5.

15 Kí nìdí tí Dáfídì fi mú sùúrù? Ó sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ nínú Sáàmù kan náà tó ti béèrè lẹ́ẹ̀mẹrin pé: “Yóò ti pẹ́ tó?” Ó ní: “Ní tèmi, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; jẹ́ kí ọkàn-àyà mi kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ. Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti bá mi lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.” (Sm. 13:5, 6) Dáfídì gbà pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní kì í yẹ̀. Bí Dáfídì ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún un jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà máa dá òun nídè. Ó ṣe kedere pé Dáfídì gbà pé ó bọ́gbọ́n mu bí òun ṣe dúró de Jèhófà.

Tó bá di pé ká ní sùúrù, Jèhófà ò retí pé ká ṣe ohun tí òun alára ò ní ṣe

16, 17. Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ tó ga lélẹ̀ tó bá di pé ká ní sùúrù?

16 Tó bá di pé ká ní sùúrù, Jèhófà ò retí pé ká ṣe ohun tí òun alára ò ní ṣe. Òun ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ní sùúrù. (Ka 2 Pétérù 3:9.) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni Jèhófà ti fi ń mú sùúrù kí ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì lè yanjú pátápátá. Ó ń mú sùúrù, ó sì ń dúró de ìgbà tó máa ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́. Ìbùkún ńlá lèyí máa jẹ́ fáwọn tó “ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.”​—Aísá. 30:18.

17 Jésù náà ń mú sùúrù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú nígbà tó wà láyé, tó sì gbé ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ lọ sọ́run lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, síbẹ̀ ó ní láti dúró títí di ọdún 1914 kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. (Ìṣe 2:33-35; Héb. 10:12, 13) Bákan náà, ó dìgbà tí ìṣàkóso rẹ̀ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún bá parí kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó parun. (1 Kọ́r. 15:25) Kò sí àní-àní pé Jésù ń mú sùúrù gan-an, àmọ́ ó dájú pé sùúrù tí Jésù ní tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

KÍ LÁÁ JẸ́ KÁ LÈ NÍ SÙÚRÙ?

18, 19. Kí láá jẹ́ ká lè ní sùúrù?

18 Ó ṣe kedere nígbà náà pé gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ní sùúrù. Àmọ́ kí láá jẹ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀? Máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ìdí sì ni pé ìpamọ́ra tàbí sùúrù jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí. (Éfé. 3:16; 6:18; 1 Tẹs. 5:17-19) Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi sùúrù dúró dè é.

19 Má gbàgbé ohun tó mú kí Ábúráhámù, Jósẹ́fù àti Dáfídì fi sùúrù dúró de àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wọn. Kì í ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ tàbí ohun tó wù wọ́n nìkan ni wọ́n gbájú mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà àti bí wọ́n ṣe ń ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn ló mú kí wọ́n lẹ́mìí ìdúródeni. Táwa náà bá ń ṣàṣàrò lórí ìbùkún tí wọ́n rí, á túbọ̀ máa wù wá láti dúró de Jèhófà.

20. Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pinnu?

20 Kódà tá a bá ń kojú àwọn àdánwò tó lékenkà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa dúró de Jèhófà. Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì lè wà táwa náà máa béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà?” (Aísá. 6:11) Àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní irú èrò tí Jeremáyà ní nígbà tó sọ pé: “Jèhófà ni ìpín mi . . . Ìdí nìyẹn tí èmi yóò ṣe fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí i.”​—Ìdárò 3:21, 24.

^ ìpínrọ̀ 11 Orí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ló dá lórí ìtàn Ábúráhámù. Yàtọ̀ síyẹn, àádọ́rin [70] ìgbà ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

^ ìpínrọ̀ 14 Jèhófà kọ Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjì ó lé díẹ̀ tó ṣàkóso. Síbẹ̀, Jèhófà gbà á láyè pé kó ṣàkóso fún ọdún méjìdínlógójì [38] sí i kó tó di pé ó kú.​—1 Sám. 13:1; Ìṣe 13:21.