Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  August 2017

 LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Ìgbà Wo La Tún Máa Ṣe Àpéjọ Mí ì?”

“Ìgbà Wo La Tún Máa Ṣe Àpéjọ Mí ì?”

ÀWỌN tó ń gbé nílùú Mexico City lé ní mílíọ̀nù kan. Ní oṣù November 1932, wọ́n ṣe iná tó ń darí ọkọ̀ lójú pópó síbẹ̀, gbogbo àwọn oníròyìn ló sì ń sọ̀rọ̀ nípa iná náà. Àmọ́ ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìyẹn, àwọn èèyàn ò rí ti iná yẹn rò mọ́. Ìdí ni pé àlejò pàtàkì kan ń bọ̀ fún àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta kan níbẹ̀. Àwọn oníròyìn gbé kámẹ́rà wọn, wọ́n sì lọ dúró de àlejò náà ní ibùdókọ̀ ojú irin. Arákùnrin Joseph F. Rutherford tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn ni àlejò pàtàkì yẹn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ náà ò gbẹ́yìn, àwọn náà ti wà níbẹ̀ láti kí i káàbọ̀.

Ìwé ìròyìn The Golden Age sọ pé: “Láìsí àní-àní àpéjọ yìí máa jẹ́ àpéjọ mánigbàgbé torí pé ó wà lára ohun táá mú kí òtítọ́ tàn kálẹ̀ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.” Àmọ́, kí ló mú kí àpéjọ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà tó jẹ́ pé àádọ́jọ [150] èèyàn péré ló pésẹ̀ síbẹ̀?

Kó tó dìgbà yẹn, ìwọ̀nba èèyàn ló ń wá sínú ètò Ọlọ́run ní Mẹ́síkò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtọdún 1919 ni wọ́n ti ń ṣe àwọn àpéjọ kéékèèké, síbẹ̀ ṣe ni iye ìjọ tó wà níbẹ̀ ń dín kù bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Nígbà tí wọ́n dá ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun sílẹ̀ nílùú Mexico City lọ́dún 1929, ó dà bíi pé nǹkan máa sunwọ̀n sí i, àmọ́ wọ́n ṣì kojú àwọn ìṣòro kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìtọ́ni wá pé káwọn ará má ṣe da òwò wọn pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù mọ́, aṣáájú-ọ̀nà kan yarí, ó sì fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, ló bá lọ dá àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiẹ̀ sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, alábòójútó ẹ̀ka tó wà níbẹ̀ nígbà yẹn lọ́wọ́ sí ìwà àìtọ́, torí náà, ó máa gba pé kí wọ́n fi ẹlòmíì rọ́pò rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ nílò ìṣírí gan-an nípa tẹ̀mí.

Nígbà tí Arákùnrin Rutherford bẹ̀ wọ́n wò, ó sọ àsọyé méjì tó tani jí ní àpéjọ yẹn, ó sì tún sọ àsọyé márùn-ún tó fakíki lórí rédíò. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn táwọn iléeṣẹ́ rédíò máa tan ìhìn rere náà kálẹ̀ lórílẹ̀-èdè yẹn. Lẹ́yìn àpéjọ náà, alábòójútó ẹ̀ka míì tí wọ́n yàn ṣètò bí iṣẹ́ ìwàásù náà á ṣe gbòòrò sí i. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù nìyẹn, Jèhófà sì bù kún wọn.

Àpéjọ ọdún 1941 ní Mexico City

Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, ìbísí náà ti pọ̀ débi pé dípò tí wọ́n á fi ṣe àpéjọ kan, àpéjọ méjì ni wọ́n ṣe. Wọ́n ṣe ọ̀kan nílùú Veracruz, wọ́n sì ṣe èkejì nílùú Mexico City. Iṣẹ́ takuntakun táwọn ará ń ṣe ti bẹ̀rẹ̀ sí í sèso torí lọ́dún 1931, àwọn akéde méjìlélọ́gọ́rin [82] péré ló wà níbẹ̀. Àmọ́ ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, wọ́n ti fi ìlọ́po mẹ́wàá lé sí iye tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀! Àwọn tó tó ẹgbẹ̀rún kan [1,000] ló wá sí Àpéjọ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti ọdún 1941 nílùú Mexico City.

“WỌ́N KÚN INÚ ÌGBORO”

Lọ́dún 1943 àwọn ará gbé àwọn àkọlé fífẹ̀ kan kọ́rùn láti polongo àpéjọ “Àwọn Orílẹ̀-Èdè Olómìnira” tí wọ́n ṣe láwọn ìlú méjìlá lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. *  Wọ́n ṣe àkọlé náà bí àgbékọ́, tí apá kan wà níwájú tí èkejì sì kọjú sẹ́yìn. Àtọdún 1936 làwọn ará wa ti máa ń lo ọ̀nà yìí láti polongo ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run.

Fọ́tò àwọn Ẹlẹ́rìí tó gbé àkọlé kọ́rùn ní Mexico City nínú ìwé ìròyìn kan lọ́dún 1944

Ìwé ìròyìn La Nación ròyìn bí ìpolongo táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ní Mexico City ṣe mú káwọn èèyàn wá sí àpéjọ náà, ó ní: ‘Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà, wọ́n sọ fún àwọn tó wá pé kí wọ́n pe àwọn míì wá. Lọ́jọ́ kejì, èrò pọ̀ débi pé gbọ̀ngàn tí wọ́n lò kò gba àwọn tó wá.’ Àṣeyọrí táwọn ará ṣe yìí kò dùn mọ́ àwọn olórí ìjọ Kátólíìkì nínú, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í tako àwọn Ẹlẹ́rìí náà lójú méjèèjì. Àmọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣì ń tú yáyá jáde láìka àtakò yìí sí. Ìwé ìròyìn La Nación tún sọ pé: ‘Gbogbo àwọn aráàlú ló rí àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n gbé àkọlé kọ́rùn, tí wọ́n sì ń polongo àpéjọ náà.’ Kódà, fọ́tò àwọn ará tó gbé àkọlé kọ́rùn wà nínú ìwé ìròyìn náà, ọ̀rọ̀ tí ìwé ìròyìn náà kọ sábẹ́ fọ́tò náà ni: “Wọ́n kún inú ìgboro.”

“BẸ́Ẹ̀DÌ YÌÍ SÀN, Ó SÌ TURA JU ILẸ̀ LÁSÁN LỌ”

Láwọn ọdún yẹn, ó gba ìsapá gan-an káwọn ará wa ní Mẹ́síkò tó lè lọ sáwọn àpéjọ tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń wá láti àwọn abúlé tó jìn gan-an, kò sí ọkọ̀ ojú irin, kódà kò sí ọ̀nà tí mọ́tò lè gbà débẹ̀. Ìjọ kan kọ̀wé pé, “Nǹkan gidi kan ṣoṣo tó wà lágbègbè yìí ni wáyà ìbánisọ̀rọ̀ kan.” Torí náà, ọ̀pọ̀ ló máa ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí kí wọ́n rìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ kí wọ́n tó wọ ọkọ̀ ojú irin tó máa gbé wọn lọ sílùú tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará ni kò lówó lọ́wọ́, kódà owó àlọ nìkan ni wọ́n máa ń rí tù jọ. Ilé àwọn ará tó wà lágbègbè tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ ni wọ́n sábà máa ń dé sí, wọ́n sì máa ń gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Àwọn míì máa ń sun inú Gbọ̀ngàn Ìjọba, kódà ìgbà kan wà tí àwọn ará tó tó àádọ́rùn-ún [90] sun ẹ̀ka ọ́fíìsì, wọ́n sì to àwọn páálí ìwé pa pọ̀ fi ṣe bẹ́ẹ̀dì fún wọn. Ìwé Ọdọọdún wa sọ pé àwọn ará yẹn mọrírì ibùsùn tí wọ́n ṣètò yìí, wọ́n wá sọ pé “bẹ́ẹ̀dì yìí sàn, ó sì tura ju ilẹ̀ lásán lọ.”

Àwọn ará yẹn gbà pé gbogbo ohun táwọn yááfì láti wà láwọn àpéjọ yẹn tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lónìí, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé mílíọ̀nù kan, síbẹ̀ inú wọn ṣì máa ń dùn láti péjọ. * Ìròyìn láti ẹ̀ka wa ní Mẹ́síkò lọ́dún 1949 sọ nípa àwọn ará pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn, síbẹ̀ wọn ò jẹ́ kíyẹn paná ìtara tí wọ́n ní. Wọn kì í gbàgbé ohun tí wọ́n gbọ́ láwọn àpéjọ yẹn, òun sì ni ìjíròrò wọn máa ń dá lé. Wọ́n á wá máa béèrè pé, Ìgbà wo la tún máa ṣe àpéjọ míì?” Bí àwọn àpéjọ yẹn ṣe rí lára àwọn ará nígbà yẹn náà ló rí títí dòní.​—Látinú Àpamọ́ Wa ní Central America.

^ ìpínrọ̀ 9 Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 1944 sọ pé àpéjọ yìí “ló jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.”

^ ìpínrọ̀ 14 Lọ́dún 2016 àwọn 2,262,646 ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi ní Mẹ́síkò.