Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Fara Da Ìpọ́njú, Jèhófà sì Bù Kún Wa

A Fara Da Ìpọ́njú, Jèhófà sì Bù Kún Wa

ỌLỌ́PÀÁ KGB * kan pariwo mọ́ mi pé: “Ìwọ yìí mà dájú o, o pa ìyàwó ẹ tó lóyún àti ọmọbìnrin rẹ̀ tì. Ta lo fẹ́ kó máa tọ́jú wọn? Jáwọ́ nínú ẹ̀sìn tó ò ń ṣe yìí, kó o lè máa lọ sílé!” Mo wá sọ fún un pé: “Rárá, mi ò pa ìdílé mi tì, ẹ̀yin lẹ mú mi, kí lẹ̀ṣẹ̀ mi?” Ó wá kígbe mọ́ mi pé, “Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú tó kéèyàn jẹ́ Ajẹ́rìí.”

Ọgbà ẹ̀wọ̀n kan nílùú Irkutsk lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni mo wà nígbà yẹn lọ́dún 1959. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìdí tí èmi àti Maria ìyàwó mi fi múra tán láti “jìyà nítorí òdodo” àti bí Jèhófà ṣe bù kún wa torí pé a jẹ́ olóòótọ́ sí i.​—1 Pét. 3:​13, 14.

Ọdún 1933 ni wọ́n bí mi ní abúlé kan tó ń jẹ́ Zolotniki, lórílẹ̀-èdè Ukraine. Lọ́dún 1937, àbúrò màámi kan àti ọkọ wọn wá kí wa láti ilẹ̀ Faransé, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, wọ́n sì fún wa ní ìwé Government àti ìwé Deliverance tí àjọ Watch Tower Society ṣe. Nígbà tí bàbá mi ka àwọn ìwé náà, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára. Àmọ́ ó dùn mí pé lọ́dún 1939, wọ́n dùbúlẹ̀ àìsàn, àmọ́ kí wọ́n tó kú, wọ́n sọ fún màámi pé: “Òtítọ́ nìyí, rí i pé o fi kọ́ àwọn ọmọ wa.”

SIBERIA DI ÌPÍNLẸ̀ ÌWÀÁSÙ WA TUNTUN

Ní April 1951, ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Soviet Union lọ sílùú Siberia. Wọ́n lé èmi, màámi àti àbúrò mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Grigory kúrò ní Ukraine. Lẹ́yìn tá a rìnrìn-àjò ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] kìlómítà nínú ọkọ̀ ojú irin, a dé ìlú Tulun ní Siberia. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, wọ́n rán ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Bogdan lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó wà nílùú Angarsk ni wọ́n fi sí.

Èmi, Grigory àti màámi bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nílùú Tulun, àmọ́ a máa ń fọgbọ́n ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń bi àwọn èèyàn pé, “Ṣé ẹ máa ń ta màlúù níbí?” Tá a bá ti rẹ́ni tó ń ta màlúù, àá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ọ̀nà àrà tí Ọlọ́run gbà dá màlúù fún un, kí ẹni náà tó mọ̀, a ti ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Ó tiẹ̀ nígbà kan tí iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn kan kọ̀wé nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé màlúù la máa sọ pé à ń wá, àmọ́ àwọn tá a máa wàásù fún là ń wá. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ, torí pé à ń rí àwọn tó tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wa. Ìpínlẹ̀ tá a kò pín fúnni la wà, àmọ́ inú wa máa ń dùn láti kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì máa ń gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Ní báyìí, ìjọ kan ti wà ní Tulun, àwọn akéde tó sì wà níbẹ̀ lé lọ́gọ́rùn-ún.

 WỌ́N DÁN ÌGBÀGBỌ́ MARIA WÒ

Orílẹ̀-èdè Ukraine ni Maria ìyàwó mi ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lásìkò Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], ọlọ́pàá KGB kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìlọ̀kilọ̀ lọ̀ ọ́, ó sì ń fòró ẹ̀mí rẹ̀ kó lè bá a sùn, àmọ́ Maria kọ̀ jálẹ̀. Bí Maria ṣe délé lọ́jọ́ kan, ó bá ọlọ́pàá náà lórí bẹ́ẹ̀dì rẹ̀, ni Maria bá fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Inú bí ọlọ́pàá náà gan-an ló bá sọ pé òun máa ti Maria mọ́lé torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn, torí nígbà tó dọdún 1952, wọ́n rán Maria lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Maria gbà pé bíi ti Jósẹ́fù lọ̀rọ̀ òun rí, ẹni tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ó kọ̀ láti bá ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ṣèṣekúṣe. (Jẹ́n. 39:​12, 20) Awakọ̀ tó gbé Maria láti ilé ẹjọ́ lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù. Ọ̀pọ̀ ló ti lọ sẹ́wọ̀n tí wọn ò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn.” Ọ̀rọ̀ yẹn fún un lókun gan-an.

Àgọ́ kan nítòsí ìlú Gorkiy, ní Rọ́ṣíà ni wọ́n rán Maria lọ, ó sì wà níbẹ̀ láti ọdún 1952 sí 1956, (Nizhniy Novgorod là ń pe ìlú yẹn báyìí.) Iṣẹ́ àṣekúdórógbó ni wọ́n fún un níbẹ̀. Wọ́n ní kó máa hú igi tigbòǹgbò-tigbòǹgbò nínú òtútù burúkú, ìyẹn sì mú kó ṣàìsàn gan-an. Nígbà tó dọdún 1956, wọ́n dá a sílẹ̀, ó sì lọ sílùú Tulun.

MO WÀ NÍBI TÓ JÌNNÀ GAN-AN SÍ ÌDÍLÉ MI

Arákùnrin kan tó ń gbé ní Tulun sọ fún mi pé arábìnrin kan ń kó bọ̀ níbẹ̀, torí náà, mo gun kẹ̀kẹ́ mi lọ sí ibùdókọ̀ kí n lè lọ bá a gbé ẹrù rẹ̀. Bí mo ṣe rí Maria báyìí ni mo ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Mo dẹnu ìfẹ́ kọ ọ́, àmọ́ kò tètè gbà fún mi. Nígbà tó yá, ó gbà fún mi, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1957. Ọdún kan lẹ́yìn náà la bí Irina ọmọbìnrin wa àkọ́kọ́. Àmọ́, wọn ò jẹ́ kí n gbádùn ìdílé mi torí pé lọ́dún 1959, wọ́n fàṣẹ ọba mú mi pé mò ń tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Oṣù mẹ́fà ni mo lò nínú àhámọ́. Àmọ́ kí ọkàn mi lè balẹ̀, mo máa ń gbàdúrà nígbà gbogbo, mo máa ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run, mo sì máa ń fọkàn yàwòrán bí màá ṣe máa wàásù tí wọ́n bá dá mi sílẹ̀.

Nígbà tí mo wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lọ́dún 1962

Nígbà kan tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pariwo mọ́ mi pé, “A máa tó gbá gbogbo yín wọlẹ̀, ẹ ò sì ní gbérí mọ́!” Mo wá sọ fún un pé, “Jésù sọ pé a MÁA wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé, kò sì sẹ́ni tó lè dáṣẹ́ náà dúró.” Nígbà tó rí i pé ìyẹn ò mú mi, ó dá ọgbọ́n míì. Bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, ó rọ̀ mí pé kí n jáwọ́ nínú ẹ̀sìn tí mò ń ṣe. Ìgbà tí wọ́n rí i pé ìyẹn náà ò ṣiṣẹ́, wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún méje pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára ní àgọ́ kan tó wà nítòsí ìlú Saransk. Ojú ọ̀nà ni mo wà nígbà tí mo gbọ́ pé ìyàwó mi ti bí Olga ọmọbìnrin wa kejì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí mo wà jìn gan-an sí ìdílé mi, ọkàn mi balẹ̀ pé bí mo ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà náà ni Maria jẹ́ olóòótọ́.

Maria àtàwọn ọmọ wa Olga àti Irina lọ́dún 1965

Maria máa ń wá wò mí lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlọ àti ààbọ̀ ìrìn àjò náà máa ń gbà á ní odindi ọjọ́ méjìlá. Ọdọọdún ló máa ń bá mi mú bàtà tuntun wá. Á wá tọ́jú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde sínú rẹ̀. Àmọ́, lọ́dún kan, Maria ṣe ohun tó wú mi lórí, ó kó àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì dání nígbà tó ń bọ̀. Inú mi dùn gan-an, ayọ̀ mi sì kún nígbà tí mo rí wọn.

A KOJÚ ÌṢÒRO LÁWỌN IBÒMÍÌ TÁ A KÓ LỌ

Wọ́n dá mi sílẹ̀ lọ́dún 1966, àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì kó lọ sílùú Armavir, nítòsí Òkun Dúdú. Ibẹ̀ la sì bí àwọn ọmọkùnrin wa sí, ìyẹn Yaroslav àti Pavel.

 Kò pẹ́ lẹ́yìn tá a débẹ̀ làwọn ọlọ́pàá KGB bẹ̀rẹ̀ sí í wá sílé wa, torí wọ́n ń wá àwọn ìtẹ̀jáde wa. Wọ́n máa ń gbọn gbogbo ilé wa yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ débi pé wọ́n tún ń tú ibi tá à ń kó oúnjẹ màlúù sí. Nígbà kan tí wọ́n wá, ooru fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn ọlọ́pàá náà, aṣọ wọn sì dọ̀tí gan-an. Àánú wọn ṣe Maria torí pé iṣẹ́ tí wọ́n rán wọn ni wọ́n ń jẹ́. Ni Maria bá bu ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò fún wọn, ó sì fún wọn ní nǹkan tí wọ́n á fi gbọn aṣọ wọn. Ó bu omi fún wọn, ó sì tún fún wọn láṣọ ìnura. Nígbà tí ọ̀gá wọn dé, àwọn ọlọ́pàá náà ròyìn bí Maria ṣe tọ́jú wọn. Bí wọ́n ṣe ń lọ, ọ̀gá wọn rẹ́rìn-ín, ó sì juwọ́ sí wa. Inú wa dùn bá a ṣe ń rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”​—Róòmù 12:21.

Láìka bí wọ́n ṣe ń dàámù wa sí, a ṣì ń wàásù nílùú Armavir. A tún ń ran àwùjọ kékeré kan tó wà nílùú Kurganinsk lọ́wọ́. Inú mi dùn gan-an pé ní báyìí ìjọ mẹ́fà ló wà ní Armavir, mẹ́rin sì wà ní Kurganinsk.

Àwọn ìgbà kan wà tí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Àmọ́, a dúpẹ́ pé Jèhófà lo àwọn arákùnrin olóòótọ́ láti tọ́ wa sọ́nà, wọ́n sì tún gbé wa ró. (Sm. 130:⁠3) Àwọn nǹkan míì tún dán ìgbàgbọ́ wa wò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́pàá KGB kan yọ́ wọnú ìjọ, a ò sì fura sí wọn rárá. Wọ́n di Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì ń ṣe bí ẹni nítara gan-an, kódà àwọn kan lára wọn tiẹ̀ láǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run. Àmọ́, nígbà tó yá, àṣírí wọn tú.

Lọ́dún 1978 nígbà tí Maria pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta [45], ó lóyún. Àmọ́ torí pé ó ní àrùn ọkàn, àwọn dókítà rọ̀ ọ́ pé kó ṣẹ́ oyún náà kó má bàa kú. Maria kọ̀ jálẹ̀, àmọ́ àwọn dókítà náà ò fi í lọ́rùn sílẹ̀, ṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé e kiri gbogbo ibi tó bá ń lọ nílé ìwòsàn náà kí wọ́n lè gún un lábẹ́rẹ́ táá jẹ́ kí oyún náà wálẹ̀. Bí Maria ṣe sá kúrò níbẹ̀ nìyẹn kó lè dáàbò bo ọmọ rẹ̀.

Àwọn ọlọ́pàá KGB sọ pé ká kúrò nílùú yẹn. Torí náà, a kó lọ sí abúlé kan tó wà nítòsí ìlú Tallinn, ní Estonia, tó jẹ́ apá kan Soviet Union. Ọ̀rọ̀ ò rí báwọn dókítà yẹn ṣe rò torí Maria bí ọmọkùnrin làǹtì-lanti kan níbẹ̀, a sì pe orúkọ rẹ̀ ní Vitaly.

Nígbà tó yá, a kó kúrò ní Estonia lọ sílùú Nezlobnaya, ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. A máa ń fọgbọ́n wàásù láwọn àgbègbè tó sún mọ́ ìlú yìí torí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá gbafẹ́ níbẹ̀ kí wọ́n sì tọ́jú ara wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa tọ́jú ara wọn ni wọ́n bá wá síbẹ̀, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun làwọn kan lára wọn máa ń mú lọ.

A KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ WA LÁTI NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ

A kọ́ àwọn ọmọ wa lọ́nà táá mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì fayé wọn sìn ín. A máa ń pe àwọn ará tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà wá sílé wa káwọn ọmọ wa lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Lára àwọn tá a máa ń pè ni Grigory ẹ̀gbọ́n mi tó ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká láti ọdún 1970 sí 1995. A máa ń gbádùn rẹ̀ gan-an torí pé gbogbo ìgbà ni inú rẹ̀ máa ń dùn, ó sì máa ń pa wá lẹ́rìn-ín. Tá a bá ti lálejò, a máa ń ṣe àwọn eré inú Bíbélì, ohun tó sì mú káwọn ọmọ wa nífẹ̀ẹ́ Bíbélì nìyẹn.

Àwọn ọmọ mi àtàwọn ìyàwó wọn.

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún, ẹ̀yìn: Yaroslav, Pavel, Jr., Vitaly

Iwájú: Alyona, Raya, Svetlana

Lọ́dún 1987, Yaroslav ọmọ wa kó lọ sílùú Riga lórílẹ̀-èdè Latvia, kó lè ráyè wàásù dáadáa. Àmọ́, nígbà tó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n  ọdún kan àtààbọ̀, ọgbà ẹ̀wọ̀n mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì mú un lọ. Àwọn ohun tí mo sọ fún un nípa ìgbà tí mo wà lẹ́wọ̀n ló ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́dún 1990, Pavel ọmọ wa tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] fẹ́ lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní erékùṣù kan tó ń jẹ́ Sakhalin tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Japan. Kò wù wá kó lọ, torí pé ibẹ̀ jìn sọ́dọ̀ wa, kódà ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] kìlómítà lọ, ogún akéde péré ló sì wà níbẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, a gbà kó lọ, a sì rí i pé ìpinnu tó dáa la ṣe. Àwọn tó wà níbẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ìhìn rere gan-an, láàárín ọdún mélòó kan tó lò níbẹ̀, ìjọ mẹ́jọ ni wọ́n dá sílẹ̀. Pavel sìn níbẹ̀ títí di ọdún 1995. Nígbà tá à ń sọ yìí, Vitaly àbígbẹ̀yìn wa nìkan ló wà nílé pẹ̀lú wa. Àtikékeré ló ti fẹ́ràn kó máa ka Bíbélì. Ìgbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14], ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, a sì jọ ṣe iṣẹ́ náà fún ọdún méjì. A gbádùn àwọn àkókò yẹn gan-an. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], ó di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Mo rántí pé lọ́dún 1952, ọlọ́pàá KGB kan sọ fún Maria pé: “Jáwọ́ nínú ẹ̀sìn tó ò ń ṣe tàbí kó o lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Tó o bá fi máa jáde, wàá ti gbó bí aṣọ òfì.” Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bí wọ́n ṣe rò. A rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì fi wá sílẹ̀, àwọn ọmọ wa náà sì nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn nìkan kọ́ o, àwọn tá a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ náà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Èmi àti Maria máa ń lọ sáwọn ibi táwọn ọmọ wa ti ń sìn, inú wa sì máa ń dùn láti rí ayọ̀ tó wà lójú àwọn táwọn ọmọ wa ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.

A DÚPẸ́ LỌ́WỌ́ JÈHÓFÀ

Lọ́dún 1991, ìjọba forúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin, èyí sì mú ká lè fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. Kódà, ìjọ wa ra bọ́ọ̀sì kan tá a lè máa gbé lọ wàásù láwọn òpin ọ̀sẹ̀, a sì máa ń gbé e lọ sáwọn ìlú àtàwọn abúlé tó wà nítòsí wa.

Èmi àti ìyàwó mi lọ́dún 2011

Inú mi dùn pé Yaroslav àti ìyàwó rẹ̀ Alyona pẹ̀lú Pavel àti ìyàwó rẹ̀ Raya ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì báyìí. Vitaly àti ìyàwó rẹ̀ Svetlana sì ti di alábòójútó àyíká. Irina ọmọbìnrin wa àgbà àti ìdílé rẹ̀ ń gbé nílẹ̀ Jámánì, alàgbà sì ni Vladimir ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Olga ọmọ wa ń gbé ní Estonia, ó sì máa ń pè mí ní gbogbo ìgbà. Ó bà mí nínú jẹ́ pé Maria ìyàwó mi ọ̀wọ́n kú lọ́dún 2014. Ṣe ló ń ṣe mí bíi kí àjíǹde ti dé kí n lè rí i lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìlú Belgorod ni mò ń gbé báyìí, àwọn ará tó wà níbẹ̀ sì ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an.

Àwọn ọdún tí mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti jẹ́ kí n mọ̀ pé èèyàn gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìfaradà kó tó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àmọ́ ìbàlẹ̀ ọkàn tí Jèhófà máa ń fúnni ju gbogbo ohun téèyàn fara dà lọ. Torí pé èmi àti ìyàwó mi jẹ́ olóòótọ́, àwọn ìbùkún tá a rí ju gbogbo ohun tá a lérò lọ. Kí ìjọba Soviet Union tó pín lọ́dún 1991, ohun tó lé díẹ̀ ní ọ̀kẹ́ méjì [40,000] akéde ló wà níbẹ̀. Àmọ́ lónìí, àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400,000] ló wà láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ apá kan Soviet Union tẹ́lẹ̀. Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] ni mí báyìí, alàgbà sì ni mí nínú ìjọ. Kò sígbà tí Jèhófà kì í fún mi lókun kí n lè fara dà á. Ó dájú pé kò sóhun tí mo lè fi wé àwọn ìbùkún jìngbìnnì tí Jèhófà ti fún mi.​—Sm. 13:5, 6.

^ ìpínrọ̀ 4 KGB ni àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ìjọba Soviet Union.