Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) August 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti September 25 sí October 22, 2017, ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ṣé Wàá Lè Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà?

Àwọn tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà láyé àtijọ́ béèrè bó ṣe máa pẹ́ tó táwọn á fi fara da àdánwò, síbẹ̀ Jèhófà kò bínú sí wọn.

‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’

Ṣé o máa ń bi ara rẹ pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn ìṣòro tó dé bá ẹ? Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí ló máa jẹ́ kó o gbà pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Fara Da Ìpọ́njú, Jèhófà sì Bù Kún Wa

Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n lé lọ sí Siberia fi ń béèrè màlúù nígbà tó jẹ́ pé àwọn ẹni bí àgùntàn ni wọ́n ń wá? Ìtàn ìgbésí ayé Pavel àti Maria Sivulsky jẹ́ ká rí ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀.

Bá A Ṣe Lè Bọ́ Àwọn Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀, Ká Má sì Gbé E Wọ̀ Mọ́

Ohun kan ni pé kéèyàn bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, ohun mí ì ni pé kéèyàn má pa dà sídìí rẹ̀ mọ́. Kí la lè ṣe tá ò fi ní pa dà sídìí ìwà àtijọ́ mọ́, kódà ká tiẹ̀ ní a ti jingíri sínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀?

Bá A Ṣe Lè Gbé Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Wọ̀, Tá Ò sì Ní Bọ́ Ọ Sílẹ̀ Mọ́

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, o lè di irú ẹni tí Jèhófà fẹ́ kó o jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ọ̀nà mélòó kan tó o lè máa fi àánú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù hàn.

Ìfẹ́​—Ànímọ́ Kan Tó Ṣe Pàtàkì

Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tí ẹ̀mí Jèhófà máa ń jẹ́ ká ní. Kí ni ìfẹ́ gan-⁠an? Báwo la ṣe lè ní in? Báwo la ṣe lè máa fi í hàn lójoojúmọ́?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Ìgbà Wo La Tún Máa Ṣe Àpéjọ Mí ì?”

Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àpéjọ àgbègbè kékeré tí wọ́n ṣe ní Mexico City lọ́dún 1932?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí ohun tí Mátíù àti Lúùkù sọ nípa ìgbà tí Jésù wà ní kékeré àti ìlà ìdílé rẹ̀ fi yàtọ̀ síra?