Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máa Fúnni Níṣìírí Bíi Ti Jèhófà

Máa Fúnni Níṣìírí Bíi Ti Jèhófà

“Ìbùkún ni fún Ọlọ́run . . . ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”​—2 KỌ́R. 1:​3, 4.

ORIN: 7, 3

1. Ìṣírí wo ni Jèhófà fáwọn tó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀?

ỌLỌ́RUN tí ń fúnni níṣìírí ni Jèhófà. Àtìgbà táwa èèyàn ti dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ti di aláìpé ló ti ń fún wa níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, kété lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà fún àwọn tó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù níṣìírí tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ìrètí ṣì wà fún wọn. Lẹ́yìn tá a lóyè àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:​15, ọkàn wa balẹ̀ pé bó pẹ́, bó yá “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” ìyẹn Sátánì Èṣù àti gbogbo iṣẹ́ burúkú rẹ̀ máa pa run.​—Ìṣí. 12:9; 1 Jòh. 3:8.

JÈHÓFÀ FÚN ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ RẸ̀ ÌGBÀANÌ NÍṢÌÍRÍ

2. Báwo ni Jèhófà ṣe fún Nóà níṣìírí?

2 Àárín àwọn èèyàn burúkú ni Nóà tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń gbé, kódà òun àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló ń sin Jèhófà. Àwọn oníṣekúṣe àti oníwà ipá ló yí wọn ká, ó sì ṣeé ṣe kíyẹn kó  ìrẹ̀wẹ̀sì bá Nóà. (Jẹ́n. 6:​4, 5, 11; Júúdà 6) Àmọ́ Jèhófà fún un láwọn ìtọ́ni kan tó fún un níṣìírí láti máa “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn” nìṣó. (Jẹ́n. 6:9) Jèhófà sọ fún Nóà pé òun máa tó pa ayé búburú yẹn run, ó sì jẹ́ kó mọ ohun tó máa ṣe kí òun àti ìdílé rẹ̀ má bàa pa run. (Jẹ́n. 6:​13-18) Èyí mú kí Nóà rí i pé Ọlọ́run tí ń fúnni níṣìírí ni Jèhófà.

3. Báwo ni Jèhófà ṣe fún Jóṣúà níṣìírí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Nígbà tó yá, Jèhófà gbé iṣẹ́ ńlá kan fún Jóṣúà, ó fẹ́ kí Jóṣúà kó àwọn èèyàn òun wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́, kí wọ́n tó lè gba Ilẹ̀ Ìlérí yìí, wọ́n máa ní láti ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tó wà níbẹ̀. Jèhófà mọ̀ pé àyà Jóṣúà lè máa já, torí náà, ó ní kí Mósè fi Jóṣúà lọ́kàn balẹ̀. Ó sọ fún Mósè pé: “Fàṣẹ yan Jóṣúà, kí o sì fún un ní ìṣírí, kí o sì fún un lókun, nítorí pé òun ni ẹni tí yóò lọ níwájú àwọn ènìyàn yìí, òun sì ni ẹni tí yóò mú kí wọ́n jogún ilẹ̀ tí ìwọ yóò rí.” (Diu. 3:28) Àmọ́ kí Jóṣúà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Jèhófà fún un níṣìírí, ó sọ fún un pé: “Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” (Jóṣ. 1:​1, 9) Ẹ wo bí ìyẹn ti máa fọkàn Jóṣúà balẹ̀ tó!

4, 5. (a) Ìṣírí wo ni Jèhófà fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyé àtijọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fún Ọmọ rẹ̀ níṣìírí?

4 Bí Jèhófà ṣe ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ níṣìírí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ló ń fún wọn lápapọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mọ̀ pé àwọn Júù máa nílò ìṣírí nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn Bábílónì, torí náà ó sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí fún wọn nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan, ó ní: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Aísá. 41:10) Nígbà tó yá, Jèhófà fún àwọn Kristẹni ìgbàanì níṣìírí, bó sì ṣe ń fún àwa náà nìyẹn.​—Ka 2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.

5 Jésù náà rí ìṣírí gbà lọ́dọ̀ Baba rẹ̀. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó gbọ́ tí ohùn kan jáde wá láti ọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:17) Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún Jésù lókun jálẹ̀ àkókò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé!

JÉSÙ FÚNNI NÍ ÌṢÍRÍ

6. Báwo ni àkàwé nípa tálẹ́ńtì ṣe fúnni níṣìírí?

6 Jésù náà máa ń fúnni níṣìírí bíi ti Baba rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ àkàwé nípa tálẹ́ńtì, àkàwé yìí sì jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká jólóòótọ́. Nínú àkàwé yẹn, ọ̀gá àwọn ẹrú náà kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹrú tó jẹ́ olóòótọ́ pé: “O káre láé, ẹrú rere àti olùṣòtítọ́! Ìwọ jẹ́ olùṣòtítọ́ lórí ìwọ̀nba àwọn ohun díẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò yàn ọ́ sípò lórí ohun púpọ̀. Bọ́ sínú ìdùnnú ọ̀gá rẹ.” (Mát. 25:​21, 23) Ó dájú pé ìyẹn máa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níṣìírí gan-an pé táwọn bá jẹ́ olóòótọ́, àwọn máa rí ojú rere Ọlọ́run.

7. Ìṣírí wo ni Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, pàápàá jù lọ Pétérù?

7 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn àpọ́sítélì Jésù máa ń bá ara wọn jiyàn lórí ẹni tó jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Àmọ́ ṣe ni Jésù máa ń fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà, tó sì máa ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa ṣe bí ìránṣẹ́  dípò kí wọ́n máa ṣe bí ọ̀gá. (Lúùkù 22:​24-26) Ọ̀pọ̀ ìgbà tiẹ̀ ni Pétérù ṣe ohun tó dun Jésù. (Mát. 16:​21-23; 26:​31-35, 75) Àmọ́ dípò kí Jésù bínú sí Pétérù, ṣe ló fún un níṣìírí, kódà ó tún ní kó máa fún àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun.​—Jòh. 21:16.

BÍ WỌ́N ṢE FÚNNI NÍṢÌÍRÍ NÍGBÀ ÀTIJỌ́

8. Báwo ni Hesekáyà ṣe fún àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti gbogbo èèyàn Júdà níṣìírí?

8 Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá di pé ká fúnni níṣìírí, àmọ́ kó tó wá sáyé làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ń fúnni níṣìírí. Nígbà táwọn ará Ásíríà ń halẹ̀ mọ́ Hesekáyà, ó pe àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti gbogbo èèyàn Júdà lápapọ̀, ó sì fún wọn níṣìírí. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ Hesekáyà ọba Júdà gbé ara wọn ró.”​—Ka 2 Kíróníkà 32:​6-8.

9. Kí ni ìwé Jóòbù kọ́ wa tó bá di pé ká máa fúnni níṣìírí?

9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù fúnra rẹ̀ nílò ìṣírí, síbẹ̀ ó jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa fúnni níṣìírí. Kàkà káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí tù ú nínú, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé ni wọ́n ń sọ sí i. Ó wá sọ fún wọn pé ká ní àwọn ni wọ́n wà nírú ipò tóun wà ni, òun ‘ì bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu òun fún wọn lókun, ìtùnú ètè òun ì bá sì fún wọn lágbára.’ (Jóòbù 16:​1-5) Nígbà tó yá, Élíhù fún Jóòbù níṣìírí, Jèhófà náà sì tún fún un níṣìírí.​—Jóòbù 33:​24, 25; 36:​1, 11; 42:​7, 10.

10, 11. (a) Kí nìdí tí ọmọbìnrin Jẹ́fútà fi nílò ìṣírí? (b) Àwọn wo ló tún nílò ìṣírí lónìí?

10 Ẹlòmíì tó nílò ìṣírí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà. Kí Jẹ́fútà tó lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jagun, ó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà pé tí òun bá ṣẹ́gun, òun máa fún Jèhófà ní ẹni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé òun. Ṣé ẹ mọ ẹni tó kọ́kọ́ wá pàdé rẹ̀? Ọmọbìnrin rẹ̀, ọmọ kan ṣoṣo tó ní ló jáde wá fayọ̀ pàdé rẹ̀. Inú Jẹ́fútà ò dùn rárá. Síbẹ̀, ó mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ó rán ọmọbìnrin rẹ̀ lọ sí Ṣílò kó lè lọ sìn jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.​—Oníd. 11:​30-35.

11 Ká sòótọ́, ìpinnu yìí ò rọrùn rárá fún Jẹ́fútà, síbẹ̀ ó dájú pé ó máa nira jùyẹn lọ fún ọmọ rẹ̀. (Oníd. 11:​36, 37) Ìdí ni pé kò ní lọ́kọ, kò sì ní bímọ, ìyẹn túmọ̀ sí pé ibi tí orúkọ ìdílé wọn máa pa rẹ́ sí nìyẹn. Ṣé ẹ̀yin náà rí i pé ọmọbìnrin Jẹ́fútà nílò ìtùnú àti ìṣírí? Bíbélì sọ pé: “Ó sì wá jẹ́ ìlànà ní Ísírẹ́lì pé: Láti ọdún dé ọdún, àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì a lọ láti gbóríyìn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà tí í ṣe ọmọ Gílíádì, ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́dún.” (Oníd. 11:​39, 40) Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó torí kí wọ́n lè gbájú mọ́ “àwọn ohun ti Olúwa”?​—1 Kọ́r. 7:​32-35.

ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ FÚN ÀWỌN ARÁ NÍṢÌÍRÍ

12, 13. Báwo ni Pétérù ṣe ‘fún àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun’?

12 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Símónì, Símónì, wò ó! Sátánì ti fi dandan béèrè láti gbà yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà. Ṣùgbọ́n èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa yẹ̀; àti ìwọ, ní gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.”​—Lúùkù 22:​31, 32.

Lẹ́tà táwọn àpọ́sítélì kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fún àwọn ará níṣìírí gan-an, ó sì ń fún àwa náà níṣìírí lónìí (Wo ìpínrọ̀ 12 sí 17)

13 Pétérù wà lára àwọn tó múpò iwájú nínú ìjọ Ọlọ́run láyé àtijọ́. (Gál. 2:9) Àwọn nǹkan tó ṣe lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì àti lẹ́yìn ìgbà yẹn fún àwọn ará lókun.  Lẹ́yìn tó ti sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sọ fáwọn Kristẹni pé: “Mo kọ̀wé sí yín ní ọ̀rọ̀ díẹ̀, láti fún yín ní ìṣírí àti ìjẹ́rìí àfi-taratara-ṣe pé èyí ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tòótọ́ ti Ọlọ́run; ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú rẹ̀.” (1 Pét. 5:12) Àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ nígbà yẹn fún àwọn ará níṣìírí, ó sì ń fún àwa náà níṣìírí lónìí. Kò sí àní-àní pé a nílò ìṣírí yìí gan-an bá a ṣe ń retí ìgbà tí àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ.​—2 Pét. 3:13.

14, 15. Báwo ni Ìhìn Rere tí Jòhánù kọ ṣe fún àwọn Kristẹni níṣìírí láyé àtijọ́ àti lóde òní?

14 Àpọ́sítélì Jòhánù náà wà lára àwọn tó múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni láyé àtijọ́. Òun náà wà lára àwọn tó kọ Ìhìn Rere nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Ìwé tó kọ yìí fún àwọn Kristẹni ìgbà yẹn níṣìírí gan-an, ó sì ń fún àwa náà níṣìírí lónìí torí pé ìròyìn amọ́kànyọ̀ ló wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù nìkan ló ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Jésù sọ pé ìfẹ́ la fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ mọ̀.​—Ka Jòhánù 13:​34, 35.

15 Yàtọ̀ sí Ìhìn Rere tí Jòhánù kọ, ó tún kọ àwọn lẹ́tà mẹ́ta sáwọn Kristẹni kó lè fún wọn níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ṣé ọkàn wa kì í balẹ̀ tá a bá rántí pé “ẹ̀jẹ̀ Jésù . . . ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀”? (1 Jòh. 1:7) Tí ọkàn wa bá sì ń dá wa lẹ́bi, ṣé inú wa kì í dùn tá a bá ka ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé, “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ”? (1 Jòh. 3:20) Yàtọ̀ síyẹn, Jòhánù nìkan ló sọ pé, “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:​8, 16) Nínú lẹ́tà kejì àti kẹta tí Jòhánù kọ sáwọn Kristẹni, ó fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”​—2 Jòh. 4; 3 Jòh. 3, 4.

16, 17. Ìṣírí wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ìgbà ayé rẹ̀?

16 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù  ló fún àwọn ará níṣìírí jù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Nígbà yẹn, Jerúsálẹ́mù ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àpọ́sítélì wà, ibẹ̀ sì ni ìgbìmọ̀ olùdarí wà. (Ìṣe 8:14; 15:2) Àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà wàásù nípa Jésù fáwọn ẹlẹ́sìn Júù tó gbà pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà. Àmọ́ ní ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹ̀mí mímọ́ rán an pé kó lọ wàásù fáwọn Gíríìkì, àwọn ará Róòmù àtàwọn míì tó ń jọ́sìn ọlọ́run púpọ̀.​—Gál. 2:​7-9; 1 Tím. 2:7.

17 Pọ́ọ̀lù rìnrìn-àjò jákèjádò ilẹ̀ Gíríìsì, Ítálì àti ibi tá a wá mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí, ó ń wàásù, ó sì ń dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe Júù. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yìí “jìyà lọ́wọ́ àwọn ará ilẹ̀ ìbílẹ̀ [wọn]” torí náà, wọ́n nílò ìṣírí. (1 Tẹs. 2:14) Nígbà tó di nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tuntun tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo yín nínú àwọn àdúrà wa, nítorí láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti ìfaradà yín.” (1 Tẹs. 1:​2, 3) Ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa fún ara wọn níṣìírí, ó ní: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró lẹ́nì kìíní-kejì.”​—1 Tẹs. 5:11.

ÌGBÌMỌ̀ OLÙDARÍ FÚN ÀWỌN ARÁ NÍṢÌÍRÍ

18. Báwo ni ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe fún Fílípì níṣìírí?

18 Bí ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ń fún àwọn ará níṣìírí náà ni wọ́n ń fún àwọn tó ń múpò iwájú níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Fílípì ajíhìnrere lọ wàásù fáwọn ará Samáríà, ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe ohun tó fi hàn pé àwọn mọyì iṣẹ́ tó ṣe. Wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù lọ síbẹ̀ láti gbàdúrà fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́, kí wọ́n lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Ìṣe 8:​5, 14-17) Ẹ wo bí inú Fílípì àtàwọn tó wàásù fún ṣe máa dùn tó pé ìgbìmọ̀ olùdarí mọyì àwọn!

19. Báwo ni lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí kọ sáwọn ìjọ ṣe rí lára àwọn ará?

19 Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn Júù gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́, àmọ́ nígbà tó yá, awuyewuye kan wáyé tó mú kó pọn dandan fún ìgbìmọ̀ olùdarí láti pinnu bóyá dandan ni káwọn tí kì í ṣe Júù dádọ̀dọ́ àbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 15:​1, 2) Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, tí wọ́n sì jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ tọ́ àwọn sọ́nà, wọ́n pinnu pé kò pọn dandan kí wọ́n dádọ̀dọ́. Torí náà, wọ́n kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ láti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n pinnu, wọ́n sì rán àwọn aṣojú lọ sáwọn ìjọ kí wọ́n lè fi lẹ́tà náà jíṣẹ́. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n kà á, wọ́n yọ̀ nítorí ìṣírí náà.”​—Ìṣe 15:​27-32.

20. (a) Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń fún ẹgbẹ́ ará níṣìírí lónìí? (b) Ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

20 Lónìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé níṣìírí títí kan àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn tó ń sìn ní pápá. Kí nìyẹn ti yọrí sí? Bó ṣe rí lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà ló rí lára wa. À ń yọ̀ torí ìṣírí tá à ń rí gbà. Yàtọ̀ síyẹn, lọ́dún 2015, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ìwé kan jáde tá a pè ní Jọ̀wọ́ Pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ìwé yìí sì ti fún ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé níṣìírí láti pa dà sínú ètò Jèhófà. Àmọ́, ṣé àwọn tó ń múpò iwájú nìkan ló yẹ kó máa fúnni níṣìírí? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.