Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2017

Ṣé Èrò Tí Jèhófà Ní Nípa Ìdájọ́ Òdodo Ni Ìwọ Náà Ní?

Ṣé Èrò Tí Jèhófà Ní Nípa Ìdájọ́ Òdodo Ni Ìwọ Náà Ní?

“Èmi yóò polongo orúkọ Jèhófà . . . , Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.”​DIU. 32:​3, 4.

ORIN: 110, 2

1, 2. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Nábótì àtàwọn ọmọ rẹ̀? (b) Ànímọ́ méjì wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

FOJÚ inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Wọ́n parọ́ mọ́ ọkùnrin kan pé ó dẹ́ṣẹ̀ kan tó burú jáì. Àwọn ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun ló fi ẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un. Èyí ya tẹbí tọ̀rẹ́ lẹ́nu gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, inú àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ ká máa rẹ́ni jẹ kò dùn nígbà tí wọ́n rí bí wọ́n ṣe pa aláìmọwọ́mẹsẹ̀ yẹn àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kì í ṣe ìtàn àròsọ rárá. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Nábótì ló ṣẹlẹ̀ sí, ìgbà ayé Áhábù ọba Ísírẹ́lì ló sì ṣẹlẹ̀.​—1 Ọba 21:​11-13; 2 Ọba 9:26.

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé àpẹẹrẹ Nábótì yẹ̀ wò, a tún máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe tí alàgbà olóòótọ́ kan ṣe nínú ìjọ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì yìí máa jẹ́ ká rí i pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìdájọ́ òdodo wò ó. Bákan náà, a tún máa rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká lẹ́mìí ìdáríjì tó bá dà bíi pé wọ́n hùwà àìdáa nínú ìjọ, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé èrò tí Jèhófà ní nípa ìdájọ́ òdodo làwa náà ní.

 WỌ́N YÍ ÌDÁJỌ́ PO

3, 4. Irú èèyàn wo ni Nábótì, kí sì nìdí tó fi kọ̀ láti ta ọgbà àjàrà rẹ̀ fún Ọba Áhábù?

3 Nábótì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpẹẹrẹ búburú Ọba Áhábù àti Jésíbẹ́lì ìyàwó rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń tẹ̀ lé. Báálì ni wọ́n ń jọ́sìn, torí náà wọn ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Àmọ́ Nábótì ní tiẹ̀ mọyì àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà, kódà ó kà á sí pàtàkì ju ẹ̀mí òun alára lọ.

4 Ka 1 Àwọn Ọba 21:​1-3. Áhábù sọ fún Nábótì pé kó ta ọgbà àjàrà rẹ̀ fún òun tàbí kó jẹ́ kóun fún un ní òmíì tó dáa jùyẹn lọ, àmọ́ Nábótì kò gbà. Nábótì fìrẹ̀lẹ̀ sọ fún Ọba pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n fi ohun ìní àjogúnbá àwọn baba ńlá mi fún ọ.” Kí nìdí tí Nábótì fi kọ̀? Ìdí ni pé nínú òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ta ogún ìdílé wọn títí lọ fáàbàdà. (Léf. 25:23; Núm. 36:7) Ó ṣe kedere pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ni Nábótì náà fi ń wò ó.

5. Kí ni Jésíbẹ́lì ṣe kí ọkọ rẹ̀ lè gba ọgbà àjàrà Nábótì?

5 Ó ṣeni láàánú pé bí Nábótì ṣe kọ̀ láti ta ọgbà rẹ̀ mú kí Ọba Áhábù àti ìyàwó rẹ̀ hu àwọn ìwà burúkú kan. Kí Jésíbẹ́lì lè gba ọgbà àjàrà náà fún ọkọ rẹ̀, ó ṣètò pé káwọn kan fẹ̀sùn èké kan Nábótì, èyí sì mú kí wọ́n pa Nábótì àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Kí ni Jèhófà máa ṣe sí ìwà ìkà yìí?

ONÍDÀÁJỌ́ ÒDODO DÁ SỌ́RỌ̀ NÁÀ

6, 7. Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni, kí sì nìdí tí èyí fi máa tu àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ Nábótì nínú?

6 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà rán Èlíjà lọ sọ́dọ̀ Áhábù. Èlíjà sọ fún Áhábù pé apààyàn ni, olè sì ni. Ìdájọ́ wo ni Jèhófà ṣe fún Áhábù? Jèhófà sọ pé torí wọ́n pa Nábótì àtàwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n máa pa Áhábù náà, wọ́n á tún pa ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀.​—1 Ọba 21:​17-25.

7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa dun àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ Nábótì nítorí èèyàn wọn tí Áhábù pa, ó dájú pé inú wọn máa dùn pé Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì tètè dá sọ́rọ̀ náà. Síbẹ̀, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó máa fi hàn bóyá wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

8. Kí ni Áhábù ṣe nígbà tó gbọ́ ìdájọ́ Jèhófà, kí sì ni Jèhófà ṣe?

8 Nígbà tí Áhábù gbọ́ ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe, ‘ó bẹ̀rẹ̀ sí í fa àwọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ wọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbààwẹ̀, ó ń dùbúlẹ̀ nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.’ Àbí ẹ ò rí nǹkan, Áhábù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀! Kí wá ni Jèhófà ṣe fún un? Jèhófà sọ fún Èlíjà pé: “Nítorí ìdí náà pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí mi, èmi kì yóò mú ìyọnu àjálù náà wá ní àwọn ọjọ́ rẹ̀. Àwọn ọjọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ ni èmi yóò mú ìyọnu àjálù náà wá sórí ilé rẹ̀.” (1 Ọba 21:​27-29; 2 Ọba 10:​10, 11, 17) Jèhófà tó jẹ́ ‘olùṣàyẹ̀wò ọkàn,’ fojú àánú hàn sí Áhábù.​—Òwe 17:3.

Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀ MÁA DÁÀBÒ BÒ WÁ

9. Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ò ṣe ní jẹ́ káwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Nábótì ṣinú rò?

9 Báwo ni ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe lọ́tẹ̀ yìí ṣe máa rí lára àwọn tó mọ̀ nípa ìwà ìkà tí Áhábù hù? Ó ṣeé ṣe kí èyí dán ìgbàgbọ́ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Nábótì wò. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni kò ní jẹ́ kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀. Wọ́n á máa bá ìjọsìn wọn nìṣó torí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà kò ní yí ìdájọ́ po láé. (Ka Diutarónómì 32:​3, 4.) Jèhófà máa san Nábótì àtàwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé wọn lẹ́san nígbà àjíǹde, ó sì dájú  pé ìdájọ́ òdodo pípé nìyẹn. (Jóòbù 14:​14, 15; Jòh. 5:​28, 29) Láfikún sí i, ẹni tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa rántí pé “Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.” (Oníw. 12:14) Ká fi sọ́kàn pé tí Jèhófà bá fẹ́ ṣèdájọ́, ó tún máa ń wo àwọn nǹkan míì tó lè má hàn sáwa. Torí náà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ò ní jẹ́ ká ṣinú rò débi pé àá fi Jèhófà sílẹ̀.

10, 11. (a) Àwọn nǹkan wo ló lè dán ìgbàgbọ́ wa wò? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa gbà ràn wá lọ́wọ́?

10 Ká sọ pé àwọn alàgbà ṣèpinnu kan tí kò yé ẹ tàbí tó ò fara mọ́, kí lo máa ṣe? Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe tí ìwọ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ bá pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan? Ká sọ pé wọ́n yọ ọkọ tàbí aya rẹ lẹ́gbẹ́, ó sì lè jẹ́ ọmọ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó sún mọ́ ẹ, tó ò sì fara mọ́ ìpinnu yẹn, kí lo máa ṣe? Tó o bá ronú pé wọn ò dá ẹjọ́ tó yẹ fún ẹnì kan tó hùwà àìtọ́ ńkọ́? Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè dán ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà àti ètò rẹ̀ wò. Báwo lẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè gbà ràn wá lọ́wọ́.

Kí lo máa ṣe táwọn alàgbà bá ṣèpinnu kan tí kò bá ẹ lára mu? (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 11)

11 Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ ká gbà pé a ò mọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an. Bó ti wù  ká mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà tó, Jèhófà nìkan ló mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn. (1 Sám. 16:7) Tá a bá fi èyí sọ́kàn, ó máa jẹ́ ká rẹ ara wa sílẹ̀, ká gbà pé kì í ṣe gbogbo bí nǹkan ṣe rí ló hàn sí wa, ìyẹn á sì mú ká tún inú rò. Ìkejì, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ ká gba ìpinnu èyíkéyìí táwọn tó ń múpò iwájú bá ṣe, ká sì ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà fi máa dá sọ́rọ̀ náà, táá sì ṣàtúnṣe sí àìṣèdájọ́ òdodo tó wáyé. Bíbélì sọ pé: ‘Yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, ṣùgbọ́n kì yóò dára rárá fún ẹni burúkú, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọjọ́ rẹ̀ kì yóò gùn.’ (Oníw. 8:​12, 13) Torí náà, tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kò ní jẹ́ káwa àtàwọn míì tọ́rọ̀ kàn fi Jèhófà sílẹ̀.​—Ka 1 Pétérù 5:5.

ÌWÀ ÀGÀBÀGEBÈ

12. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò, kí sì nìdí?

12 Ohun kan ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó wà ní Áńtíókù ti Síríà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí wọ́n fi hàn bóyá wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti pé wọ́n ṣe tán láti dárí jini. Ẹ jẹ́ ká gbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà yẹ̀ wò, ká sì wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́. Á jẹ́ ká mọ̀ bóyá àwa náà lẹ́mìí ìdáríjì, á sì tún jẹ́ ká rí i pé ẹ̀mí ìdáríjì ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ fi hàn pé a ní èrò tí Jèhófà ní nípa ìdájọ́ òdodo.

13, 14. Àwọn àǹfààní wo ni àpọ́sítélì Pétérù ní, kí ló sì ṣe tó fi hàn pé ó nígboyà?

13 Gbogbo èèyàn ló mọ àpọ́sítélì Pétérù tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ Kristẹni, òdú ni kì í ṣàìmọ̀ fólóko. Ọ̀rẹ́ Jésù ni nígbà tí Jésù wà láyé, Jésù sì gbé àwọn iṣẹ́ pàtàkì fún un. (Mát. 16:19) Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni, Pétérù lọ wàásù ìhìn rere fún Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀. Ohun tó ṣe yìí yani lẹ́nu torí pé Kọ̀nílíù kì í ṣe Júù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò dádọ̀dọ́. Nígbà tí Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀ gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, Pétérù sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni ha lè sọ pé kí a má fi omi batisí àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ti rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí i gbà?’​—Ìṣe 10:47.

14 Lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣèpàdé kan. Wọ́n fẹ́ pinnu bóyá ìdádọ̀dọ́ pọn dandan fáwọn Kèfèrí tó di Kristẹni. Ní ìpàdé yẹn, Pétérù fìgboyà sọ̀rọ̀, ó rán àwọn arákùnrin náà létí pé lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, ojú òun ló ṣe nígbà táwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́ gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́. Ohun tí Pétérù sọ yìí ran ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́ láti ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ náà. (Ìṣe 15:​6-11, 13, 14, 28, 29) Ó dájú pé inú àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí to jẹ́ Kristẹni máa dùn gan-an bí Pétérù ṣe fìgboyà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Ẹ ò rí i pé ó máa rọrùn fáwọn ará láti fọkàn tán Pétérù torí pé Kristẹni tó dàgbà dénú ni.​—Héb. 13:7.

15. Àṣìṣe wo ni Pétérù ṣe nígbà tó wà ní Áńtíókù ti Síríà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

15 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, Pétérù lọ ṣèbẹ̀wò sí Áńtíókù ti Síríà. Nígbà tó wà níbẹ̀, òun àtàwọn ará tí kì í ṣe Júù jọ ń jẹ, wọ́n sì jọ ń mu. Kò sí àní-àní pé àwọn ìrírí àti ìmọ̀ tí Pétérù ní ṣe wọ́n láǹfààní gan-an. Àmọ́ ṣàdédé ni Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún wọn, kò sì bá wọn jẹun mọ́. Ó dájú pé èyí máa yà wọ́n lẹ́nu, ó sì máa dùn wọ́n. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù nínú ìjọ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé Pétérù, wọ́n ń yẹra fáwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù, kódà Bánábà náà ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ló mú kí Pétérù tó jẹ́ alàgbà tó dàgbà  dénú hùwà bẹ́ẹ̀, tó sì jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè fa ìyapa nínú ìjọ? Ìbéèrè míì tó tún ṣe pàtàkì ni pé, kí la lè rí kọ́ nínú àṣìṣe Pétérù tó máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí alàgbà kan bá sọ ohun kan tàbí ṣe ohun tó dùn wá?

16. Báwo ni wọ́n ṣe tún èrò Pétérù ṣe, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹyọ?

16 Ka Gálátíà 2:​11-14. Ìbẹ̀rù èèyàn ló mú kí Pétérù ṣe àṣìṣe yìí. (Òwe 29:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù mọ̀ pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba àwọn tí kì í ṣe Júù, síbẹ̀ kò fẹ́ káwọn Júù tó wá láti ìjọ ní Jerúsálẹ́mù fojú burúkú wo òun, torí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn tí kì í ṣe Júù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tóun náà wà nípàdé tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni lọ bá Pétérù, ó kò ó lójú, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ìwà àgàbàgebè ló hù yẹn. (Ìṣe 15:12; Gál. 2:13) Kí làwọn Kristẹni tí Pétérù ń yẹra fún máa ṣe sí àìdáa tó ṣe sí wọn? Ṣé wọ́n á jẹ́ kíyẹn mú àwọn kọsẹ̀? Ṣé àṣìṣe yìí sì máa mú kí Pétérù pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?

MÁA DÁRÍ JINI

17. Àǹfààní wo ni Pétérù rí bí Jèhófà ṣe dárí jì í?

17 Ó dájú pé Pétérù fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún un. A ò sì rí i nínú Ìwé Mímọ́ pé Pétérù pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní. Kódà nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí i láti kọ lẹ́tà méjì tó wá di apá kan Bíbélì. Nínú lẹ́tà kejì tó kọ, ó tiẹ̀ pe Pọ́ọ̀lù ní “arákùnrin wa olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (2 Pét. 3:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣìṣe tí Pétérù ṣe máa dun àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù, síbẹ̀ Jésù tó jẹ́ orí ìjọ ṣì ń lo Pétérù nínú ìjọ. (Éfé. 1:22) Èyí fún àwọn ará náà láǹfààní láti fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìdáríjì, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fara wé Jésù àti Bàbá rẹ̀. A nígbàgbọ́ pé kò sẹ́ni tó jẹ́ kí àṣìṣe ọkùnrin tó jẹ́ aláìpé yìí mú òun kọsẹ̀.

18. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó?

18 Bíi ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, aláìpé ni gbogbo àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ Kristẹni lónìí. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Ják. 3:2) A lè gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ nígbà tí àìpé bá mú kí arákùnrin kan ṣẹ̀ wá, ó lè ṣòro fún wa láti gbójú fò ó. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé àwa náà á fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé alàgbà kan sọ ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó nípa rẹ tàbí ibi tó o ti wá, kí lo máa ṣe? Tí alàgbà kan bá sọ̀rọ̀ láìro bó ṣe máa rí lára rẹ, tọ́rọ̀ náà sì dùn ẹ́ gan-an, ṣé wàá jẹ́ kíyẹn mú ẹ kọsẹ̀? Dípò tí wàá fi máa ronú pé irú arákùnrin bẹ́ẹ̀ ò yẹ ní alàgbà mọ́, ṣé wàá ní sùúrù kí Jésù tó jẹ́ orí ìjọ dá sọ́rọ̀ náà? Ṣé wàá gbójú fo àìdáa tó ṣe, kó o sì ronú nípa ọ̀pọ̀ ọdún tí arákùnrin náà ti ń sin Jèhófà bọ̀? Tí arákùnrin náà bá ṣì jẹ́ alàgbà, tó tún wá gba àwọn àfikún iṣẹ́ ìsìn míì, ṣé wàá bá a yọ̀? Tó o bá dárí ji ẹni náà, ìyẹn á fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan nìwọ náà fi ń wò ó.​—Ka Mátíù 6:​14, 15.

19. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

19 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ tí Jèhófà máa ṣàtúnṣe gbogbo àìdáa tí Sátánì àti ayé búburú yìí ti fà fún àwa èèyàn. (Aísá. 65:17) Títí dìgbà náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan làwa náà á fi máa wò ó, ká fìrẹ̀lẹ̀ gbà pé kì í ṣe gbogbo bí ọ̀rọ̀ kan ṣe jẹ́ la mọ̀, ká sì tún ṣe tán láti dárí ji gbogbo àwọn tó bá ṣẹ̀ wá.