Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2017

Àwọn Nǹkan Wo Ló Máa Lọ tí Ìjọba Ọlọ́run Bá Dé?

Àwọn Nǹkan Wo Ló Máa Lọ tí Ìjọba Ọlọ́run Bá Dé?

“Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”​—1 JÒH. 2:17.

ORIN: 134, 24

1, 2. (a) Báwo lọ̀rọ̀ ayé yìí ṣe jọ ti ọ̀daràn tí wọ́n dájọ́ ikú fún? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Báwo ló ṣe máa rí lára wa lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá pa ayé yìí run?

FOJÚ inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ná. Àwọn wọ́dà ń mú ọ̀daràn burúkú kan jáde lẹ́wọ̀n. Àmọ́, bó ṣe ń lọ ni wọ́n ń sọ pé: “Ẹ ò rí i, òkú tó ń rìn!” Kí nìdí tí wọ́n fi ń sọ bẹ́ẹ̀? Lójú, kò sóhun tó ṣe ọkùnrin náà, ó dà bíi pé koko lara ẹ̀ le. Àmọ́, ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á ni wọ́n ń mú un lọ yẹn. Ó jọ pé ikú ò lè yẹ̀ lórí ọkùnrin náà. *

2 Bí ọ̀rọ̀ ẹlẹ́wọ̀n yẹn ni ọ̀rọ̀ ayé búburú yìí rí. Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti dá ayé yìí lẹ́jọ́, kò sì ní pẹ́ tó máa mú ìdájọ́ náà ṣẹ. Bíbélì sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ.” (1 Jòh. 2:17) Torí náà, ó dájú pé ayé yìí máa dópin. Síbẹ̀, ìyàtọ̀ gedegbe wà nínú ọ̀rọ̀ ẹlẹ́wọ̀n yẹn àti bí ayé yìí ṣe máa wá sópin. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n rí àwọn tó máa sọ pé ẹjọ́ tí wọ́n dá yẹn kò tọ̀nà, ilé ẹjọ́ sì lè ní kí wọ́n má tíì pa ọ̀daràn náà. Àmọ́ ní ti ayé yìí, Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo ló dá ẹjọ́ rẹ̀. (Diu. 32:4) Torí náà, kò sí ilé ẹjọ́ tó lè ní kí Ọlọ́run má ṣe ohun  tó ti pinnu, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sẹ́ni tó lè sọ pé ìdájọ́ rẹ̀ kò tọ̀nà. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti pa ayé yìí run, gbogbo ẹ̀dá láyé àti lọ́run ló máa gbà pé ohun tó tọ́ ni Ọlọ́run ṣe. Ẹ wo bára ṣe máa tu gbogbo wa tó!

3. Àwọn ohun mẹ́rin tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú kúrò wo la máa jíròrò?

3 Àwọn nǹkan tó ti dara fún wa láyé yìí kò ní sí mọ́. Ṣé ìròyìn ayọ̀ nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, ìròyìn ayọ̀ ni! Kódà, apá pàtàkì lára ‘ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run’ tá à ń wàásù ni. (Mát. 24:14) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí kò ní sí mọ́ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé. Àwọn nǹkan wo ló wà nínú “ayé” tó “ń kọjá lọ” yìí? A máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin tó wà nínú ayé báyìí àmọ́ tí kò ní sí mọ́, ìyẹn àwọn èèyàn burúkú, ètò búburú inú ayé yìí, ìwàkiwà àtàwọn ipò tí kò bára dé. Lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, a máa jíròrò (1) bí wọ́n ṣe kan ìgbésí ayé wa, (2) ohun tí Jèhófà máa ṣe nípa wọn, àti (3) bí Jèhófà ṣe máa fi ohun rere rọ́pò wọn.

ÀWỌN ÈÈYÀN BURÚKÚ

4. Kí làwọn èèyàn burúkú ń ṣe fún wa báyìí?

4 Kí làwọn èèyàn burúkú ń ṣe fún wa báyìí? Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ọjọ́ ìkẹyìn yìí máa jẹ́ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” ó tún sọ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tím. 3:​1-5, 13) Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn nǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀? Ọ̀pọ̀ lára wa làwọn ìpáǹle, àwọn alákatakítí, àtàwọn jàǹdùkú ti hàn léèmọ̀. Àwọn kan ò fi tiwọn bò, afàwọ̀rajà sì làwọn míì, wọ́n á máa ṣe bí ẹni pé èèyàn rere làwọn, síbẹ̀ ìwà ibi ló kún ọwọ́ wọn. Ká tiẹ̀ ní wọn ò hàn wá léèmọ̀ rí, ìwà ibi wọn ṣì kàn wá. Kò sẹ́ni tínú rẹ̀ kì í bà jẹ́ tó bá gbọ́ nípa ìwà ibi táwọn èèyàn náà ń hù. Ṣé bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n àwọn ọmọdé ni ká sọ ni, tàbí bí wọ́n ṣe ń fojú àwọn àgbàlagbà gbolẹ̀ àtàwọn tí kò ní olùgbèjà? Ìwà táwọn èèyàn burúkú yẹn ń hù kò jọ tèèyàn, ṣe ló dà bíi ti ẹranko àti tàwọn ẹ̀mí èṣù. (Ják. 3:15) Àmọ́, inú wa dùn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan máa tó yí pa dà.

5. (a) Àǹfààní wo ni Ọlọ́run ṣì ń fún àwọn èèyàn burúkú? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn burúkú tí kò yí pa dà?

5 Kí ni Jèhófà máa ṣe nípa wọn? Ní báyìí ná, Jèhófà ṣì ń fún àwọn èèyàn burúkú láǹfààní láti yí pa dà. (Aísá. 55:7) Kò tíì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ayé búburú yìí ni Ọlọ́run ti pinnu pé òun máa pa run. Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò bá yí pa dà, tí wọ́n ń lúwẹ̀ẹ́ nínú ìwà burúkú ayé yìí títí dìgbà ìpọ́njú ńlá? Jèhófà ti pinnu pé gbogbo àwọn èèyàn burúkú lòun máa pa run yán-án-yán. (Ka Sáàmù 37:10.) Àwọn èèyàn burúkú lè rò pé àwọn máa yè bọ́. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti gbówọ́ nínú kéèyàn máa fi ìwà búburú wọn pa mọ́, ó sì jọ pé wọ́n máa ń mú un jẹ nígbà míì. (Jóòbù 21:​7, 9) Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé: “Ojú [Ọlọ́run] ń bẹ ní àwọn ọ̀nà ènìyàn, ó sì ń rí ìṣísẹ̀ rẹ̀ gbogbo. Kò sí òkùnkùn tàbí ibú òjìji èyíkéyìí fún àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ láti fi ara wọn pa mọ́ níbẹ̀.” (Jóòbù 34:​21, 22) Kò síbi tẹ́nì kan lè sá pa mọ́ sí tí Ọlọ́run kò ní rí i. Kò sí afàwọ̀rajà tó lè tan Ọlọ́run jẹ, kò sí bí òkùnkùn ṣe kùn tó tàbí bí òjìji kan ṣe dúdú tó tí ojú Ọlọ́run kò ní rí. Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, ó lè wù wá láti wá àwọn  èèyàn burúkú yẹn, àmọ́ a ò ní rí wọn. Wọn ò ní sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni, a ò ní rí wọn mọ́ títí láé!​—Sm. 37:​12-15.

6. Àwọn wo ló máa rọ́pò àwọn ẹni burúkú, kí sì nìdí tíyẹn fi jẹ́ ìròyìn ayọ̀?

6 Àwọn wo ló máa rọ́pò àwọn ẹni burúkú? Jèhófà ṣèlérí tó ń múnú ẹni dùn yìí: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ní ẹsẹ míì nínú sáàmù kan náà, ó sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sm. 37:​11, 29) Àwọn wo ni “ọlọ́kàn tútù” àti “olódodo”? Ọlọ́kàn tútù làwọn tó fìrẹ̀lẹ̀ gba ìtọ́ni àti ìlànà Jèhófà, olódodo sì làwọn tó ń ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run. Nínú ayé tá a wà yìí, àwọn ẹni ibi pọ̀ ju àwọn olódodo lọ fíìfíì. Àmọ́ nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ bóyá àwọn ọlọ́kàn tútù àtàwọn olódodo ló máa pọ̀ jù tàbí ló máa kéré jù, àwọn nìkan ṣoṣo ló máa wà láyé nígbà yẹn, wọ́n á sì sọ ayé di Párádísè.

ÀWỌN ÈTÒ BÚBURÚ INÚ AYÉ

7. Àkóbá wo làwọn ètò búburú inú ayé yìí ń fà fún wa?

7 Àkóbá wo làwọn ètò búburú inú ayé yìí ń fà fún wa? Èyí táwọn ètò ayé yìí ń ṣe nínú ìwà ibi pọ̀ ju èyí táwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń ṣe lọ. Bí àpẹẹrẹ, àìmọye èèyàn làwọn ètò ẹ̀sìn ti ṣì lọ́nà, wọn ò sòótọ́ fún wọn nípa Ọlọ́run, wọn ò jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Bíbélì ṣeé gbára lé, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò sòótọ́ nípa bí ayé ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn àtàwọn irọ́ míì bẹ́ẹ̀. Kí ni ká sọ nípa àwọn ìjọba tó ń sọ ara wọn di arógunyọ̀, tí wọ́n ń dá ogun abẹ́lé sílẹ̀, tí wọ́n ń fìyà jẹ àwọn tálákà àtàwọn tí kò ní olùgbèjà? Àwọn ìjọba jẹgúdújẹrá tó tún ń ṣe ojúṣàájú ńkọ́? Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ni ò ro tàwọn míì mọ́ tiwọn, wọ́n ń ba àyíká jẹ́, wọ́n ń gbọ́n àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ní àgbọ́ngbẹ, wọ́n sì ń rẹ́ àwọn oníbàárà wọn jẹ kí wọ́n lè jẹ èrè gọbọi, èyí sì ń mú kí àìmọye èèyàn máa ráágó nínú ìṣẹ́. Kò sí àní-àní pé àwọn ètò búburú ayé yìí ló ń fa èyí tó pọ̀ jù lára ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn.

8. Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ètò búburú ayé tó dà bíi pé ó fìdí múlẹ̀?

8 Kí ni Jèhófà máa ṣe? Ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn olóṣèlú bá gbéjà ko ètò ẹ̀sìn èké, ìyẹn Bábílónì Ńlá tí Bíbélì fi wé aṣẹ́wó. (Ìṣí. 17:​1, 2, 16; 18:​1-4) Gbogbo ètò ẹ̀sìn èké ló máa pa run pátápátá. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ètò búburú tó ṣẹ́ kù nínú ayé yìí? Bíbélì fi àwọn ètò búburú ayé yìí wé àwọn òkè ńláńlá àtàwọn erékùṣù tó dà bí èyí tó fìdí múlẹ̀ gbọin lójú àwọn èèyàn. (Ka Ìṣípayá 6:14.) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa mi àwọn ìjọba ayé yìí àtàwọn ètò tó gbára lé wọn jìgìjìgì, á sì ṣí wọn nídìí. Ìpọ́njú ńlá máa dópin nígbà tí Jèhófà bá pa gbogbo ìjọba ayé yìí run pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn alátìlẹyìn rẹ̀, tí wọ́n lòdì sí Ìjọba Ọlọ́run. (Jer. 25:​31-33) Lẹ́yìn ìyẹn, a ò tún ní gbúròó èyíkéyìí lára ètò búburú ayé yìí mọ́ láé!

9. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé ayé tuntun máa wà létòlétò?

9 Kí ló máa rọ́pò àwọn ètò búburú ayé yìí? Ṣé ètò míì máa wà láyé yìí lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì? Bíbélì sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pét. 3:13) Ọ̀run àti ayé ògbólógbòó  yìí kò ní sí mọ́, ìyẹn àwọn ìjọba búburú àtàwọn èèyàn burúkú abẹ́ wọn. Kí ló máa wá rọ́pò wọn? Gbólóhùn náà, “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” túmọ̀ sí ìjọba tuntun tó máa ṣàkóso ayé àti àwọn èèyàn tuntun tó máa ṣàkóso lé lórí. Jésù Kristi tó jẹ́ ọba Ìjọba náà máa ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ètò. (1 Kọ́r. 14:33) Torí náà, àwọn nǹkan máa wà létòlétò nínú “ayé tuntun.” Àwọn ọkùnrin rere láá máa bójú tó àwọn nǹkan. (Sm. 45:16) Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n á jọ ṣàkóso láá máa darí àwọn ọkùnrin yẹn. Ẹ wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí ètò kan ṣoṣo, tó jẹ́ mímọ́, tó sì wà níṣọ̀kan bá rọ́pò àwọn ètò búburú ayé yìí!

ÌWÀKIWÀ

10. Ìwàkiwà wo ló wọ́pọ̀ lágbègbè tó ò ń gbé, báwo làwọn ìwà náà sì ṣe kan ìwọ àti ìdílé rẹ?

10 Báwo ni ìwàkiwà ayé yìí ṣe kàn wá? Inú ayé tí ìwàkiwà ti gbòde kan là ń gbé. Ìṣekúṣe, ìwà àìṣòótọ́ àti ìwà ìkà ló kúnnú ayé búburú yìí. Ọ̀pọ̀ òbí ló ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àwọn ìwàkiwà yìí má bàa ran àwọn ọmọ wọn. Bóyá ni ìwàkiwà kan wà tí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti eré orí ìtàgé kì í gbé jáde, bẹ́ẹ̀ náà ló kúnnú orin àtàwọn eré ìnàjú, ìyẹn sì ń mú káwọn èèyàn máa wo àwọn ìlànà Ọlọ́run bí èyí tí kò bóde mu. (Aísá. 5:20) Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í fàyè gba irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀. À ń sa gbogbo ipá wa káwọn oníwàkiwà àtàwọn èèyànkéèyàn tó kúnnú ayé yìí má bàa kó èèràn ràn wá.

11. Kí la rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe pa àwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà run?

11 Kí ni Jèhófà máa ṣe sí ìwàkiwà tó kúnnú ayé? Bíbélì sọ ohun tí Jèhófà ṣe sí àwọn tó ń hùwàkiwà ní Sódómù àti Gòmórà. (Ka 2 Pétérù 2:​6-8.) Inú ìlú yẹn ni Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ olódodo àti ìdílé rẹ̀ ń gbé, ìwàkiwà táwọn èèyàn ibẹ̀ ń hù sì ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Torí náà, Jèhófà pa àwọn èèyàn ìlú náà run, ó sì fòpin sí ìwàkiwà wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún tipa bẹ́ẹ̀ fi “àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.” Bí Jèhófà ṣe fòpin sí gbogbo ìwàkiwà táwọn èèyàn ìgbà yẹn hù jẹ́ kó dá wa lójú pé á fòpin sí ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù lóde òní nígbà tó bá pa ayé búburú yìí run.

12. Àwọn nǹkan wo ni wàá fẹ́ ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá pa ayé búburú yìí run?

12 Kí ló máa rọ́pò ìwàkiwà? Iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ làá máa ṣe nínú Párádísè. Ẹ wo bí inú wa ti máa dùn tó bá a ṣe ń sọ ayé di Párádísè, tá à ń kọ́lé fúnra wa àti fáwọn èèyàn wa. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wa nígbà tá a bá ń kí àwọn tó jíǹdè káàbọ̀, tá a sì ń kọ́ wọn nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ti ṣe fáráyé. (Aísá. 65:​21, 22; Ìṣe 24:15) Ojoojúmọ́ làá máa ṣe àwọn ohun táá máa múnú wa dùn, táá sì máa fògo fún Jèhófà!

ÀWỌN IPÒ TÍ KÒ BÁRA DÉ

13. Kí ni ọ̀tẹ̀ Sátánì, Ádámù àti Éfà ti fà fún aráyé lónìí?

13 Báwo làwọn ipò tí kò bára dé ṣe kàn wá? Àwọn èèyàn burúkú, ètò búburú inú ayé yìí àti ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù ti mú kí nǹkan dojú rú láyé yìí. Ta ló lè sọ pé ogun, ipò òṣì àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kò kan òun? Yàtọ̀ síyẹn, àìsàn àti ikú ńkọ́? Kò sẹ́ni tí kì í mọ àwọn nǹkan yìí lára. Ohun tó sì fa gbogbo nǹkan yìí ni bí Sátánì, Ádámù àti Éfà ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Ní báyìí, kò sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ wàhálà tí ọ̀tẹ̀ wọn ti fà.

14. Kí ni Jèhófà máa ṣe sí ipò tí kò bára dé? Sọ àpẹẹrẹ kan.

 14 Kí ni Jèhófà máa ṣe sí ipò tí kò bára dé? Ní ti ogun, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fòpin sí i títí láé. (Ka Sáàmù 46:​8, 9.) Àìsàn ńkọ́? Á mú àìsàn kúrò pátápátá. (Aísá. 33:24) Kí ni Jèhófà máa ṣe sí ikú? Á gbé ikú mì títí láé! (Aísá. 25:8) Yàtọ̀ síyẹn, kò ní sí ẹni tó máa tòṣì mọ́. (Sm. 72:​12-16) Bákan náà, á mú àwọn ipò tí kò bára dé kúrò, ojú ò sì ní pọ́n àwọn èèyàn mọ́. Kódà, ìwà abèṣe tó kúnnú ayé yìí kò ní sí mọ́, torí pé Ọlọ́run á ti palẹ̀ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ mọ́ títí láé.​—Éfé. 2:2.

Wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí kò bá sí ogun,

àìsàn àti ikú mọ́! (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Àwọn nǹkan wo ni kò ní sí mọ́ títí láé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì?

15 Wo bó ṣe máa rí lára rẹ tí ogun, àìsàn àti ikú kò bá sí mọ́! Rò ó wò ná, kò ní sí àwọn ọmọ ogun èyíkéyìí mọ́! Kò ní sí àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń jagun mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sáwọn ère tí wọ́n fi ń rántí àwọn tó kú sógun. Kò ní sílé ìwòsàn, dókítà tàbí nọ́ọ̀sì, kò ní sí itẹ́ òkú, ilé ìgbókùúsí, kò sì ní sí àwọn gbókùú-gbókùú àtàwọn abánigbófò mọ́! Torí pé kò ní sí ìwà ọ̀daràn mọ́, kò ní sáwọn òṣìṣẹ́ aláàbò, kò ní sí ọlọ́pàá, kò ní sí àgádágodo àti kọ́kọ́rọ́ mọ́. Ẹ wo bí ọkàn wa ti máa balẹ̀ tó nígbà táwọn nǹkan yìí kò bá sí mọ́!

16, 17. (a) Ìtura wo làwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já máa ní? Ṣàpèjúwe. (b) Kí ló yẹ ká ṣe ká lè wà títí láé nígbà tí ayé búburú yìí kò bá sí mọ́?

16 Báwo ni nǹkan ṣe máa rí tí ipò tí kò bára dé kò bá sí mọ́? Kò dájú pé a lè mọ bó ṣe máa rí lára wa. Ìdí sì ni pé ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń gbé inú ayé yìí débi pé a lè má tiẹ̀ fi taratara kíyè sí báwọn nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń gbé nítòsí títì tàbí ojú irin kì í mọ ariwo ọkọ̀ lára mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó ń gbé nítòsí ààtàn kì í gbóòórùn ìdọ̀tí mọ́. Àmọ́ tí gbogbo nǹkan yẹn kò bá sí mọ́, pẹ̀sẹ̀ lara máa tù wá!

17 Kí ló máa rọ́pò gbogbo nǹkan tó ń kó wa lọ́kàn sókè? Sáàmù 37:11 sọ pé: ‘Wọn yóò rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.’ Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí kò múnú rẹ dùn? Ohun tí Jèhófà fẹ́ fún ẹ náà nìyẹn. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe, kó o túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run àti ètò rẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí! Máa ṣìkẹ́ ìrètí tó o ní, jẹ́ kó máa wà lọ́kàn rẹ nígbà gbogbo, kó o sì máa sọ ọ́ fáwọn míì! (1 Tím. 4:​15, 16; 1 Pét. 3:15) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á dá ẹ lójú pé o ò ní bá ayé búburú yìí lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wàá wà láyé, wàá wà láàyè, wàá sì máa láyọ̀ títí láé fáàbàdà!

^ ìpínrọ̀ 1 Ohun tí wọ́n máa ń ṣe sáwọn ẹlẹ́wọ̀n láwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ìpínrọ̀ yìí ń sọ.