“Nígbà tí Bàbá mi fẹ́ kúrò nílé ìwòsàn, a bẹ dókítà pé kó ṣàlàyé ohun tí àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ṣe fi hàn. Dókítà náà sọ pé èsì àyẹ̀wò náà dáa, ṣùgbọ́n ó fara balẹ̀ tún un wò. Sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, ó rí i pé méjì nínú èsì àyẹ̀wò náà kò dáa rárá! Ó tọrọ àforíjì, ó sì ké sí dókítà tó mọ̀ nípa ìṣòro náà. Ara dádì mi ti yá báyìí. Ọpẹ́lọpẹ́ pé a béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ dókítà náà.”—Maribel.

Kí ẹ tó lọ rí dókítà, ṣàkọsílẹ̀ bó ṣe ń ṣe ẹni náà àti àwọn oògùn tó ti lò

Tí èèyàn ẹni bá lọ rí dókítà tàbí tí wọ́n dá a dúró sí ilé ìwòsàn, ó máa ń kó ìdààmú báni. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Maribel fi hàn pé, ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an tí ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí kan bá wà pẹ̀lú aláìsàn náà, ó lè gba ẹ̀mí ẹni náà là pàápàá. Báwo lo ṣe lè ran èèyàn rẹ tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́?

Ṣáájú kó o tó lọ sí ilé ìwòsàn. Bá aláìsàn náà kọ ohun tó ń ṣe é sílẹ̀ àti àwọn oògùn tó ti lò sí i. Kẹ́ ẹ sì kọ àwọn ìbéèrè tí ẹ máa bi dókítà. Ẹ jọ ronú nípa gbogbo bí àìsàn náà ṣe ń ṣe é àti bóyá irú àìsàn yìí ti ṣe ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ̀ rí. Má ṣe ronú pé ó yẹ kí dókítà ti mọ gbogbo rẹ̀ tàbí pé ó máa mú ọ̀rọ̀ lọ síbẹ̀.

Fetí sílẹ̀ dáadáa, béèrè àwọn ìbéèrè tó yẹ, kó o sì ṣàkọsílẹ̀

Nígbà tó o bá wà nílé ìwòsàn. Ẹ rí i dájú pé ẹ lóye gbogbo ohun tí dókítà sọ. Béèrè ìbéèrè, àmọ́ má ṣe rin kinkin mọ́ èrò rẹ nípa àìsàn náà. Jẹ́ kí aláìsàn náà fẹnu ara rẹ̀ sọ̀rọ̀, kó sì béèrè ìbéèrè. Fetí sílẹ̀ dáadáa, kó o sì kọ ohun tí dókítà sọ sílẹ̀. Béèrè nípa onírúurú ìtọ́jú tó wà. Láwọn ìgbà míì, o lè dábàá pé kí aláìsàn náà lọ rí dókítà míì kó tó pinnu ohun tó máa ṣe.

Ẹ gbé ohun tí dókítà sọ yẹ̀ wò, kí ẹ sì wá àwọn oògùn tó kọ fún yín

Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá kúrò nílé ìwòsàn. Ẹ jọ yẹ ohun tí dókítà sọ wò. Rí i dájú pé oògùn tí wọ́n kọ fún un gẹ́lẹ́ ló rà. Rọ̀ ọ́ pé kó lo oògùn náà bí wọ́n ṣe ní kó lò ó. Tí oògùn náà bá sì gbòdì lára rẹ̀, kó tètè lọ rí dókítà. Sọ fún un pé kó má ṣe gbé ọ̀rọ̀ àìsàn náà sọ́kàn jù, kó sì tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tí dókítà fún un àti pé kó má ṣe yẹ ọjọ́ tí dókítà dá fún un. Bá a ṣe ìwádìí sí i nípa àìsàn náà.

 Ní Ilé Ìwòsàn

Rí i dájú pé ẹ kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú káàdì ilé ìwòsàn

Fara balẹ̀, kó o sì lákìíyèsí. Ẹni tó ń ṣàìsàn lè máa kárísọ tàbí kó máa kọ́kàn sókè tó bá dé ilé ìwòsàn. Àmọ́ tó o bá fara balẹ̀, tó o sì fọkàn sí bí nǹkan ṣe ń lọ, wàá mára tu gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀, o ò sì ní ṣe àṣìṣe. Rí i dájú pé ẹ kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú káàdì ilé ìwòsàn. Fi sọ́kàn pé aláìsàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìpinnu tó bá kan ọ̀rọ̀ ìlera rẹ̀. Tí àìsàn náà bá ti wọ̀ ọ́ lára débi tí kò fi lè ṣe ìpinnu, tẹ̀ lé ohun tó ti kọ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ nípa irú ìtọ́jú tó fẹ́. Bákan náà, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹni tí aláìsàn náà yàn láti jẹ́ aṣojú rẹ̀. *

Sọ ohun tó o kíyè sí fún dókítà náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀

Lo ìdánúṣe. Sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ láìbẹ̀rù. Múra dáadáa, kó o sì hùwà ọmọlúàbí, èyí lè mú káwọn dókítà fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ aláìsàn náà, kí wọ́n sì fún un ní ìtọ́jú tó pójú owó. Ní ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn, ó ju dókítà kan lọ tó máa ń rí aláìsàn. O lè ran àwọn dókítà yìí lọ́wọ́ nípa ṣíṣàlàyé ohun táwọn dókítà ẹlẹgbẹ́ wọn ti sọ ṣáájú. Torí pé ìwọ lo mọ aláìsàn náà dáadáa, á dáa kó o sọ àwọn ìyípadà tó o ṣàkíyèsí lára aláìsàn náà látìgbà tí àìsàn náà ti bẹ̀rẹ̀.

Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, àmọ́ má ṣàṣejù

Fi ọ̀wọ̀ hàn, kó o sì lẹ́mìí ìmoore. Iṣẹ́ ńlá ni àwọn dókítà máa ń ṣe, ó sì máa ń rẹ̀ wọ́n. Torí náà, bó o ṣe fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ẹ ni kó o ṣe sí wọn. (Mátíù 7:12) Fi hàn pé o mọyì iṣẹ́ takuntakun tí wọn ń ṣe. Fọkàn tán wọn pé akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni wọ́n, kó o sì fi ìmoore hàn fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe. Irú ẹ̀mí ìmoore bẹ́ẹ̀ lè sún wọn láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún aláìsàn náà.

Òótọ́ kan ni pé kò sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ àìsàn. Àmọ́, tó o bá múra sílẹ̀, tó o sì ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ ká, wàá lè ṣèrànwọ́ fún èèyàn rẹ tó ń ṣàìsàn lásìkò tẹ́ni náà nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì.—Òwe 17:17.

^ ìpínrọ̀ 8 Òfin tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ṣe lórí ẹ̀tọ́ àwọn aláìsàn yàtọ̀ síra. Rí i dájú pé gbogbo fọ́ọ̀mù tí aláìsàn náà kọ irú ìtọ́jú tó fẹ́ sí ló pé pérépéré.