Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Jí!  |  November 2015

 ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bó O Ṣe Lè Tọrọ Àforíjì

Bó O Ṣe Lè Tọrọ Àforíjì

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bá ara yín fa ọ̀rọ̀ kan tán. Lo bá ń sọ lọ́kàn rẹ pé: ‘Mi ò lè bẹ̀ ẹ́, torí èmi kọ́ ni mo dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀!’

Ẹ̀yìn méjèèjì jánu lórí ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kò tán nínú yín. Nígbà tó yá, o rò ó lọ́kàn pé kó o tọrọ àforíjì, ṣùgbọ́n ó ṣòro fún ẹ láti sọ pé, “má bínú.”

OHUN TÓ FÀ Á

Ìgbéraga. Baálé ilé kan tó ń jẹ́ Charles * sọ pé: “Ńṣe ló máa ń dà bíi pé mò ń rẹ ara mi nípò wálẹ̀ tí mo bá bẹ ìyàwó mi.” Ìgbéraga lè mú kó ṣòro fún ẹ láti gbà pé ìwọ náà lẹ́bi nínú ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń bá ara yín fà.

Èrò rẹ. O lè máa ronú pé wàá tọrọ àforíjì tó bá jẹ́ pé ìwọ ló jẹ̀bí. Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Jill sọ pé: “Ó máa ń rọrùn fún mi láti bẹ ọkọ mi tó bá jẹ́ pé èmi ni mo jẹ̀bi. Àmọ́ ó máa ń ṣòro tó bá jẹ́ pé àwa méjèèjì la lẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà. Kí nìdí tí màá fi bẹ̀bẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé a jọ jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ni?”

Ó lè túbọ̀ ṣòro tó bá jẹ́ pé ẹnì kejì rẹ ló dá gbogbo ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Baálé ilé kan tó ń jẹ́ Joseph sọ pé: “Ọ̀nà táwọn kan ń gbà fi hàn pé àwọn kò jẹ̀bi nínú ọ̀rọ̀ kan ni pé wọn kì í tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹnì kejì wọn.”

Bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìdílé tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ka títọrọ àforíjì sí ni wọ́n ti tọ́ ẹ dàgbà. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè má rọrùn fún ẹ láti gba àwọn àṣìṣe rẹ. Torí pé kò mọ́ ẹ lára láti máa tọrọ àforíjì ní kékeré, ó lè ṣòro fún ẹ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí tó o ti dàgbà.

 OHUN TÓ O LÈ ṢE

Títọrọ àforíjì lè paná wàhálà

Ro ti ẹnì kejì rẹ. Ronú nípa bí inú rẹ ṣe dùn nígbà tẹ́nì kan tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ. Tí ìwọ náà bá tọrọ àforíjì, bó ṣe máa rí lára ẹnì kejì rẹ náà nìyẹn. Kódà, tó o bá rò pé o kò jẹ̀bi, ó ṣì yẹ kó o bẹ ẹnì kejì rẹ torí pé bí ìwọ náà ṣe fèsì ká a lára. Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kí ara tu ẹnì kejì rẹ.—Ìlànà Bíbélì: Lúùkù 6:31.

Ro ti ìgbéyàwó rẹ. Títọrọ àforíjì kò túmọ̀ sí pé o ya ọ̀dẹ̀, àmọ́ ńṣe ló máa mú kí àjọgbé yín tura. Ó ṣe tán, Òwe 18:19 sọ pé ẹni “tí a ṣẹ̀ sí ṣòro ju ìlú olódi lọ.” (Bíbélì Mímọ́) Ìyẹn ni pé ó máa ṣòro kí àlàáfíà tó lè jọba tí ẹnì kan bá rin kinkin pé òun kò jẹ̀bi. Ní ìdàkejì, tó o bá tọrọ àforíjì, ọ̀rọ̀ náà kò ní di ńlá. Èyí sì máa fi hàn pé o ka ìgbéyàwó rẹ sí pàtàkì ju ojú tó o fi ń wo ara rẹ.—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 2:3.

Tètè máa tọrọ àforíjì. Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti tọrọ àforíjì tí o kò bá fi bẹ́ẹ̀ jẹ̀bi. Síbẹ̀, torí pé ìwọ kọ́ lo dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ìwọ náà kò jẹ̀bi rárá. Torí náà, má ṣe lọ́ra láti tọrọ àforíjì tàbí kó o máa rò pé tó bá yá ọ̀rọ̀ náà á tán nílẹ̀. Tó o bá tọrọ àforíjì, èyí lè mú kí ẹnì kejì rẹ náà tọrọ àforíjì. Bó o bá ń sapá láti máa tọrọ àforíjì, tó bá yá, á mọ́ ẹ lára.—Ìlànà Bíbélì: Mátíù 5:25.

Jẹ́ kó wá látọkàn rẹ. Títọrọ àforíjì yàtọ̀ pátápátá sí ṣíṣe àwáwí. Tó o bá sì ń bẹ̀bẹ̀, jẹ́ kó wá látọkàn rẹ torí pẹ̀lẹ́ lákọ, ó lábo. Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “Ṣáà má bínú, mi ò mọ̀ pé o máa gbé e sórí tó yẹn.” Gbà pé ìwọ náà ṣàṣìṣe, kó o sì fi sọ́kàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ dun ẹnì kejì rẹ, kódà tó o bá ronú pé kò yẹ kó dùn ún tó bẹ́ẹ̀.

Gbà pé ìwọ náà máa ń ṣe àṣìṣe. Ìwọ kọ́ lo jẹ̀bi lónìí, kò túmọ̀ sí pé o kò lè jẹ̀bi lọ́la. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tí kì í ṣe àṣìṣe! Bákan náà, tó o bá rò pé o kò lẹ́bi kankan nínú ohun tó ṣẹlẹ̀, rántí pé apá tó kọjú sí ẹ nìkan lo mọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kìíní nínú ẹjọ́ rẹ̀ jẹ́ olódodo; ọmọnìkejì rẹ̀ wọlé wá, dájúdájú, ó sì yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀.” (Òwe 18:17) Torí náà, tó o bá fi sọ́kàn pé ìwọ náà máa ń ṣe àṣìṣe, èyí á mú kó túbọ̀ yá ẹ lára láti máa tọrọ àforíjì.

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌDÍLÉ RẸ LÈ JẸ́ ALÁYỌ̀

Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ràn Yín Lọ́wọ́ Kí Ẹ Lè Jẹ́ Tọkọtaya Aláyọ̀

Ìbéèrè méjì wà tó rọrùn tó o lè bi ara ẹ tó máa jẹ́ kó o rí ohun tó o lè ṣe kí ìgbéyàwó ẹ lè túbọ̀ láyọ̀.

JÍ!

Nje Bibeli Wulo fun Wa Lonii?—Ife

Ife ti Bibeli saba maa n menu kan ki i se ife aarin lokotaya.

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Bawo La Ṣe Ń Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìlànà Bíbélì?

Jésù ṣàlàyé ìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìlànà Bíbélì méjì tó ṣe pàtàkì jù.