Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Jí!  |  September 2015

 TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Párì Ọ̀nì

Párì Ọ̀nì

KÒ SÍ ẹranko míì láyé yìí tó lè fagbára deyín mọ́ nǹkan tó ọ̀nì. Bí àpẹẹrẹ, agbára tí àwọn ọ̀nì tó wà lágbègbè Ọsirélíà fi ń deyín mọ́ nǹkan fi ìlọ́po mẹ́ta ju agbára tí kìnnìún àti ẹkùn fi ń deyín mọ́ nǹkan lọ. Síbẹ̀, ọ̀nì máa ń tètè nímọ̀lára tí nǹkan bá kan párì rẹ̀, kódà, ó máa ń yára mọ nǹkan lára ju àwa èèyàn lọ. Báwo ni ọ̀nì tí awọ ara rẹ̀ yi bí irin ṣe lè tètè máa mọ nǹkan lára?

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn sẹ́ẹ̀lì tíntìntín tó ń gbé ìsọfúnni lọ sínú ọpọlọ ló wà ní párì ọ̀nì. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Duncan Leitch sọ pé: “Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fọ́nrán iṣan tó so kọ́ àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ló gba inú àwọn ihò tíntìntín tó wà nínú agbárí ọ̀nì.” Ihò agbárí yìí máa ń dáàbò bo àwọn fọ́nrán iṣan yẹn, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó máa ń jẹ́ kó yára gba ìsọfúnni, èyí ló fà á tí ọ̀nì fi máa ń tètè mọ nǹkan lára. Fún ìdí yìí, ọ̀nì tètè máa ń mọ̀ ìyàtọ̀ láàárín oúnjẹ àti ohun tí kì í ṣe oúnjẹ tó bá wà ní ẹnu rẹ̀. Bákan náà, ọ̀nì tún lè kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí ẹnu láìjẹ́ pé ó máa ṣèèṣì deyín mọ́ wọn. Ká sòótọ́, ohun àrà gbáà ni páárì ọ̀nì jẹ́ torí pé, bó ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe tètè máa ń mọ̀ nǹkan lára.

Kí lèrò rẹ? Ṣé párì ọ̀nì kàn ṣàdédé wà bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?