Onírúurú àjọ àti àwọn èèyàn ń sapá láti mú kí ayé dẹrùn fún àwọn olùgbé ilẹ̀ Áfíríkà. Síbẹ̀, àgbègbè yìí ṣì ní àwọn ìṣòrò tó le gan-an.

Wọ́n Ń Pa Ẹranko Ráínò (RHINO) Láìgbàṣẹ

Lọ́dún 2013, wọ́n pa ẹranko kan tí wọ́n ń pè ní ráínò tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́rin [1,004] ní orílẹ̀-èdè South Africa láìgbàṣẹ. Bẹ́ẹ̀, mẹ́tàlá péré ni wọ́n pa lára àwọn ẹranko yìí lọdún 2007. Pẹ̀lú bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń ta ìwo ẹranko yìí tó, àwọn èèyàn ò yéé béèrè fún un, ó le débi pé iye tí wọ́n ń ta kìlógíráàmù kan lára ìwo rẹ̀ ju iye tí wọ́n ń ta kìlógíráàmù góòlù kan lọ. Wọ́n lè rí ìdajì mílíọ̀nù dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, (ìyẹn nǹkan bíi 83,750,000 náírà) látara ẹyọ ìwo kan péré.

RONÚ LÓRÍ ÈYÍ: Ǹjẹ́ ìjọba lè fòpin sí ìwà ìrúfin?—Jeremáyà 10:23.

Àwọn Èèyàn Kì í Fẹjọ́ Sùn Tí Wọ́n Bá Gba Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Lọ́wọ́ Wọn

Àjọ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ kíkó owó jẹ lágbàáyé, ìyẹn àjọ Transparency International, sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà ni wọ́n ti ń gbà àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jù lọ láyé. Síbẹ̀, nǹkan bí ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn tí wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ wọn ni kì í fẹjọ́ sùn. Agbẹnusọ fún àjọ yìí lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà sọ pé: “Ó jọ pé àwọn aráàlú kò fọkàn tán ìjọba pé wọ́n máa ṣe nǹkan kan sí i tí àwọn bá fẹjọ́ sùn pé àwọn kan ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ojú àwọn tí ó ríran kedere.”—Ẹ́kísódù 23:8.

Àwọn Tó Ń Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì Nílẹ̀ Áfíríkà

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìkàn-síra-ẹni lágbàáyé, ìyẹn àjọ International Telecommunication Union, fojú bù ú pé tó bá fi máa di ìparí ọdún 2014, nǹkan bí ìdá ogún lára àwọn èèyàn tó ń gbé nílẹ̀ Áfíríkà á ti máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Iye àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lórí ẹ̀rọ alágbèéká nílẹ̀ Áfíríkà ń yára pọ̀ sí í ní ìlọ́po méjì ju iye àwọn tó ń lò ó kárí ayé.