Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Jí!  |  May 2015

 ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bo O Se Le Ni Ajose To Daa Pelu Awon Ana Re

Bo O Se Le Ni Ajose To Daa Pelu Awon Ana Re

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

“Nígbà tá a ní ìṣòro nínú ìdílé wa, ìyàwó mi sọ fún àwọn òbí rẹ̀. Bàbá ìyàwó mi wá pè mí kó lè fún mi ní ìmọ̀ràn nípa ìṣòro náà. Inú mi ò dùn sí ohun tí ìyàwó mi ṣe yìí rárá!”—James. *

“Ìyá ọkọ mi sábà máa ń sọ pé, ‘Àárò ọmọ mi ń sọ mí gan-an!’ Ó máa ń sọ bí wọ́n ṣe mọwọ́ ara wọn tó, èyí sì máa ń jẹ́ kí n dá ara mi lẹ́bi pé mo fẹ́ ọmọ rẹ̀, tí mo sì wá mú kí ìyà ọkọ mi máa ronú!”—Natasha.

Ǹjẹ́ ohun kan wà tá a lè ṣe tí ìṣòro àwọn àna kò fi ní dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé wa?

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Téèyàn bá ṣègbéyàwó, ó ti dá ìdílé tiẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn. Bíbélì sọ pé bí ọkùnrin bá fẹ́yàwó “yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.” Bí ọ̀rọ̀ ìyàwó náà ṣe rí sí àwọn òbí rẹ̀ nìyẹn. Tó bá ti lọ́kọ, Bíbélì sọ pé àwọn méjèèjì “yóò sì di ara kan.” Wọ́n ti di ìdílé tuntun nìyẹn.—Mátíù 19:5.

Ìdílé tìẹ ni àkọ́kọ́. Agbaninímọ̀ràn kan tó ń jẹ́ John M. Gottman, kọ̀wé pé: “Ohun pàtàkì kan nínú ọ̀rọ̀ lọ́kọláya ni pé kí wọ́n máa fi ọ̀rọ̀ ẹnì kejì wọn ṣáájú nínú ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe. Tó o bá fẹ́ kí àjọṣe ìwọ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ gún régé, ó máa gba pé kó o dín àjọṣe ìwọ àtàwọn òbí rẹ kù.” *

Ó lè ṣòro fún àwọn òbí kan láti gbà pé ọmọ wọn ti ní ìdílé tiẹ̀. Ọkọ kan tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Ká tó ṣègbéyàwó, ohun tí àwọn òbí ìyàwó mi fẹ́ ni ìyàwó mi máa ń ṣe. Àmọ́ lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, ìyá ìyàwó mi rí i pé ẹlòmíì ti gba ipò òun. Èyí kò sì rọrùn fún un láti gbà.”

Ọ̀rọ̀ àna kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó. James tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ níní àna yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ yíyan ọ̀rẹ́. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹnì kan sọ fún ẹ pé, ‘bóofẹ́ bóokọ̀, o ti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun méjì.’ Bí ìwà wọn ò bá tiẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn pàápàá, wọ́n ti di mọ̀lẹ́bí rẹ!”

 OHUN TÓ O LÈ ṢE

Tí ọ̀rọ̀ ìwọ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ kò bá tíì wọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn àna, ńṣe ni kẹ́ ẹ fọwọ́sowọ́pọ̀ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà nítùbí-ìnùbí. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “máa wá ọ̀nà láti rí àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.”—Sáàmù 34:14.

Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí kókó yìí. A sọ ọ́ lọ́nà tó fi jẹ́ pé àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ àti ìkẹta jẹ́ ọkọ, ìkejì sì jẹ́ ìyàwó. Àmọ́, èyíkéyìí nínú ọ̀rọ̀ náà lè ṣẹlẹ̀ sí ọkọ, ó sì lè ṣẹlẹ̀ sí ìyàwó. Àwọ̀n ìlànà tá a jíròrò lè ràn ẹ lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòrò tí ọ̀rọ̀ àwọn àna máa ń fẹ́ dá sílẹ̀.

Ìyàwó rẹ sọ pé ó wu òun kí àárín ìwọ àti màmá òun túbọ̀ gún. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ìwọ àti ìyá ìyàwó rẹ kò wọ̀ rárá.

Gbìyànjú èyí wò: Jíròrò ìṣòrò náà pẹ̀lú ìyàwó rẹ, kó o sì múra tán láti ṣàtúnṣe. Kókó ibẹ̀ ni pé, àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹni tó o jẹ́jẹ̀ẹ́ fún pé wàá nífẹ̀ẹ́ ni kó o rò, kì í ṣe bí àárín ìwọ àti ìyá ìyàwó rẹ ṣe rí. Nígbà ìjíròrò náà, pinnu ohun kan tàbí méjì tó o máa ṣiṣẹ́ lé lórí tó máa mú kí àárín ìwọ àti ìyá ìyàwó rẹ gún régé, kó o sì ṣiṣẹ́ lé e lórí. Bí ìyàwó rẹ ṣe ń kíyè sí ìsapá rẹ, á túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.—Ìlànà Bíbélì: 1 Kọ́ríńtì 10:24.

Ọkọ rẹ sọ pé o máa ń fẹ́ ṣe ohun tí àwọn òbí rẹ fẹ́ dípò kó o ṣe ohun tí òun fẹ́.

Gbìyànjú èyí wò: Jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ọkọ rẹ, kó o sì fi ọ̀rọ̀ náà ṣírò ara rẹ wò. Lóòótọ́ kò yẹ kí ọkọ rẹ fi ọ̀rọ̀ náà ṣèbínú tó bá jẹ́ pé ńṣe lo kàn ń ṣe ojúṣe rẹ sí àwọn òbí rẹ. (Òwe 23:22) Síbẹ̀, nípasẹ̀ ìwà rẹ àti ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, o lè mú kó dá ọkọ rẹ lójú pé o fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú ti àwọn òbí rẹ. Bí o bá fi ọkàn ọkọ rẹ balẹ̀ lọ́nà yìí, kò ní máa ronú pé o ka àwọn òbí rẹ sí ju òun lọ.—Ìlànà Bíbélì: Éfésù 5:33.

Ìyàwó rẹ kì í fọ̀rọ̀ lọ̀ ẹ́ àwọn òbí rẹ̀ ló máa ń fọ̀rọ̀ lọ̀.

Gbìyànjú èyí wò: Bá ìyàwó rẹ sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ sì jọ ṣàdéhùn irú ọ̀rọ̀ táá máa fi lọ àwọn òbí rẹ̀. Àmọ́ má ṣe àṣejù. Ṣé gbogbo ìgbà ló burú láti sọ ohun tó ń jẹni lọ́kàn fún òbí ẹni? Ìgbà wo gan-an ló yẹ kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀? Tẹ́ ẹ bá jọ fohùn ṣọ̀kan nípa irú ọ̀rọ̀ táá máa fi lọ àwọn òbí rẹ̀, ìṣòrò tí ẹ ní lórí irú nǹkan báyìí máa dínkù.—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 4:5.

^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

^ ìpínrọ̀ 9 Látinú ìwé náà The Seven Principles for Making Marriage Work.