Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Jí!  |  March 2015

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ BÍBÉLÌ WÚLÒ FÚN WA LÓNÌÍ

Ikora-Eni-Nijaanu

Ikora-Eni-Nijaanu

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.”Òwe 29:11.

“Ńṣe ló dà bíi pé mo ti kú tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá jí mi dìde!”

ÈRÈ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Tá a bá ní ká máa kọ àwọn èrè tó wà nínú kéèyàn máa kó ara rẹ̀ níjàánu, ilẹ̀ á kún! Ó kéré tán, ẹni bá lẹ́mìí ìkóra-ẹni-níjàánu máa ní ìlera tó dáa. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè.” Ó tún sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.” (Òwe 14:30; 17:22) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí torí ìwádìí fi hàn pé àìsàn kì í jìnnà sáwọn tó máa ń bínú, pàápàá àìsàn ọkàn. Àmọ́ ṣá, èrè tó wà nínú kéèyàn máa kó ara rẹ̀ níjàánu ju kéèyàn ní ìlera tó dáa.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Cassius tó ti lé ní ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún sọ pé: “Onígbòónára àti oníbìínú èèyàn ni mí tẹ́lẹ̀, mo sì máa ń wájà àwọn èèyàn. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ ka ara mi sí, àmọ́ mo yíwà mi pa dà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Mo kọ́ béèyàn ṣe ń kó ara rẹ̀ níjàánu àti béèyàn ṣe ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀ kó sì máa dárí jini. Ká ní kì í ṣe àwọn ìlànà Bíbélì tí mo fi sílò ni, ẹ̀wọ̀n ni mi ò bá wà. Ńṣe ló dà bíi pé mo ti kú tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá jí mi dìde!”

Cassius kọ́ béèyàn ṣe ń kó ara rẹ̀ níjàánu àti béèyàn ṣe ń dárí jini

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Bawo La Ṣe Ń Jàǹfààní Látinú Àwọn Ìlànà Bíbélì?

Jésù ṣàlàyé ìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìlànà Bíbélì méjì tó ṣe pàtàkì jù.