Àwọn ìwé ìròyìn wa tá a gbé ka Bíbélì wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè wà wọ́n jáde ní èdè tó lé ní àádọ́jọ [150]. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ń jẹ́ ká rí bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ti ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe fi hàn. Ó ń fi ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tu àwọn èèyàn nínú, ó sì ń gbani níyànjú láti nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Ìwé ìròyìn Jí! ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè kápá àwọn ìṣòro òde òní ó sì ń mú kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí tí Ẹlẹ́dàá ṣe pé ayé tuntun alálàáfíà tí kò léwu máa wà.