Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Wọ́n Ń Ran Àwọn tí Ogun Lé Wá sí Àárín Gbùngbùn Yúróòpù Lọ́wọ́

Wọ́n Ń Ran Àwọn tí Ogun Lé Wá sí Àárín Gbùngbùn Yúróòpù Lọ́wọ́

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ogun ti lé wá sí ilẹ̀ Yúróòpù láti ilẹ̀ Áfíríkà, Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn àti Gúúsù Éṣíà. Àwọn iléeṣẹ́ ìjọba àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn sì ti ń fún wọn lóúnjẹ, ibi tí wọ́n á máa gbé, wọ́n sì tún ṣètò bí àwọn dókítà á ṣe máa tọ́jú wọn.

Àmọ́ ká sòótọ́, ohun táwọn tí ogun lé kúrò nílùú máa ń nílò kọjá ìyẹn. Ràbọ̀ràbọ̀ ohun tí ogun fojú wọn rí kì í tètè tán lára ọ̀pọ̀ nínú wọn, torí náà, wọ́n tún nílò ohun tó máa tù wọ́n nínú, táá sì jẹ́ kí wọ́n nírètí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àárín gbùngbùn Yúróòpù ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tí ogun lé wá yìí, wọ́n máa ń tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn yìí bá ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tù wọ́n nínú.

Wọ́n Fi Bíbélì Tù Wọ́n Nínú

Láti August 2015, àwọn Ẹlẹ́rìí láti ìjọ tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] lórílẹ̀-èdè Austria àti Jámánì ti sapá gidigidi láti tu àwọn tí ogun lé wá sí ilẹ̀ Yúróòpù nínú. Wọ́n rí i pé ó máa ń wu àwọn èèyàn yìí gan-an láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí:

Láàárín August sí October 2015, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà béèrè láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Àárín Gbùngbùn Yúróòpù, wọn ò sì díye lé ìwé tí wọ́n ń fún àwọn èèyàn náà.

Wọn Ò Jẹ́ Kí Èdè Ṣèdíwọ́

Èdè ìbílẹ̀ wọn nìkan ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ogun lé wá yìí ń sọ. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo ìkànnì jw.org láti bá wọn sọ̀rọ̀ torí àwọn àpilẹ̀kọ àti fídíò wà níbẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Matthias àti Petra, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn nílùú Erfurt, lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé, “Nígbà míì tá a bá fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ṣe la máa ń fọwọ́ júwe, àá fi àwòrán hàn wọ́n tàbí ká fọwọ́ yàwòrán ohun tá à ń sọ.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa ń lo JW Language, ìyẹn ètò orí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù tí wọ́n fi ń kọ́ èdè. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n lè fi èdè ìbílẹ̀ àwọn èèyàn náà bá wọn sọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí míì máa ń ka Bíbélì fún wọn látorí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library tó ní oríṣiríṣi èdè, wọ́n sì máa ń fi àwọn fídíò tó wà níbẹ̀ hàn wọ́n.

Ohun Tó Tẹ̀yìn Rẹ̀ Yọ Yani Lẹ́nu Gan-an

Tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wá láti ìlú Schweinfurt, lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé, “Ṣe làwọn èrò ya bò wá. Láàárín wákàtí méjì ààbọ̀, àwọn tí ogun lé wá yìí gba ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta [360] ìwé. Nígbà tá a fún àwọn kan nínú wọn níwèé, wọ́n rọra tẹrí ba fún wa, wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa.” Wolfgang, tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ nílùú Diez, lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé, “Inú àwọn èèyàn yẹn máa ń dùn pé àwọn kan tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn. Nígbà míì, wọ́n á ní ká fún àwọn níwèé lóríṣiríṣi èdè, bíi márùn-ún sí mẹ́fà.”

Tí ọ̀pọ̀ nínú wọn bá ti gba ìwé, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n á ti máa kà á, àwọn míì á sì pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ilonca tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Berlin, lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé, “Ọ̀dọ́kùnrin méjì kan gbàwé lọ́wọ́ wa. Nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn náà ni wọ́n bá pa dà wá, wọ́n mú búrẹ́dì wá fún wa. Wọ́n ní ká máà bínú pé àwọn ò ní nǹkan míì táwọn lè fi dúpẹ́ lọ́wọ́ wa.”

“Ẹ Ṣé O! Ẹ Ṣé Gan-An!”

Àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn aládùúgbò mọrírì báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́. Òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan tó ń bójú tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] nínú àwọn tí ogun lé kúrò nílùú sọ pé, “Ẹ ṣé o! Ẹ ṣé gan-an fún bẹ́ ẹ ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn àjèjì yìí jẹ yín lọ́kàn!” Òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re míì tó ń ṣiṣẹ́ níbi táwọn èèyàn tí ogun lé wá yìí ń gbé sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé ó dáa gan-an bí wọ́n ṣe ń fún àwọn èèyàn yìí ní ìwé tó nítumọ̀ tí wọ́n lè kà ní èdè wọn, “torí pé lọ́wọ́lọ́wọ́, kò sóhun tí wọ́n ń ṣe ju kí wọ́n jẹun ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́.”

Marion àti Stefan ọkọ rẹ̀, tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè Austria, ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi yọ̀ǹda ara wọn fún ọlọ́pàá méjì tó wá wo ohun tó ń lọ. Àwọn ọlọ́pàá náà dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ní kí wọ́n fún àwọn ní ìwé méjì. Marion sọ pé: “Ṣe làwọn ọlọ́pàá náà ṣáà ń kí wa kú iṣẹ́.”

Obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Austria tó máa ń kó nǹkan wá lọ́fẹ̀ẹ́ síbi táwọn tí ogun lé wá ń gbé máa ń kíyè sí i pé láìka bí ojú ọjọ́ bá ṣe rí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn yìí. Lọ́jọ́ kan, obìnrin náà sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé: “Lóòótọ́, àwọn tí ogun lé wá síbí nílò oúnjẹ, aṣọ àti ibi tí wọ́n á máa gbé. Àmọ́ ohun tí wọ́n nílò jù ni ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n nírètí. Ohun tẹ́ ẹ sì ń fún wọn gẹ́lẹ́ nìyẹn.”