Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bá A Ṣe Ń Ran Ará Ìlú Lọ́wọ́

BÁ A ṢE Ń RAN ARÁ ÌLÚ LỌ́WỌ́

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀, Ìfẹ́ Máa Ń Mú Ká Ṣèrànwọ́

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà àjálù.

BÁ A ṢE Ń RAN ARÁ ÌLÚ LỌ́WỌ́

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀, Ìfẹ́ Máa Ń Mú Ká Ṣèrànwọ́

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà àjálù.

Wọ́n Mára Tu Àwọn Èèyàn Níbi Eré Ìdárayá Tour de France

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé àwọn àtẹ ìwé tó ṣeé tì kiri lọ sáwọn ìlú táwọn èèyàn ti ṣeré ìdárayá Tour de France, kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ ìtùnú táá jẹ́ kí wọ́n nírètí hàn wọ́n.

Wọ́n Ń Ran Àwọn tí Ogun Lé Wá sí Àárín Gbùngbùn Yúróòpù Lọ́wọ́

Kì í ṣe oúnjẹ, aṣọ àti ilé nìkan làwọn tí ogun lé kúrò nílùú nílò. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó yọ̀ǹda ara wọn ń sọ̀rọ̀ ìtùnú àti ọ̀rọ̀ táá jẹ́ kí wọ́n nírètí fún wọn látinú Bíbélì.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kọ́wọ́ Ti Àwọn Aráàlú Láti Tún Ìlú Rostov-on-Don Ṣe

Ìjọba ìlú Rostov-on-Don, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kọ lẹ́tà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe nígbà táwọn èèyàn ń tún ìlú náà ṣe nígbà ìrúwé.

Mo Rìnnà Kore Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Donald, tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nígbà kan sọ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe jẹ́ kó mọ Ọlọ́run, tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, tó sì wá di ọkọ rere.