Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Fọ́tò Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick, Apá 5 (September 2015 sí February 2016)

Fọ́tò Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick, Apá 5 (September 2015 sí February 2016)

Wo ọ̀wọ́ àwọn fọ́tò yìí kó o lè rí ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tuntun tẹ̀ síwájú dé láti September 2015 sí February 2016. Wàá tún rí bí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà lásìkò yẹn.

Bí orílé-iṣẹ́ wa ní Warwick ṣe máa rí tá a bá kọ́ ọ tán rèé. Wò ó láti apá òsì sí apá ọ̀tún:

  1. Ibi Tá Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

  2. Ibi Ìgbọ́kọ̀sí fún Àwọn Àlejò

  3. Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

  4. Ilé Gbígbé B

  5. Ilé Gbígbé D

  6. Ilé Gbígbé C

  7. Ilé Gbígbé A

  8. Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

October 7, 2015—Ọgbà Warwick

Wọ́n ń gbé irin kọdọrọ tí wọ́n á fi ṣe afárá sórí ilẹ̀ olómi lọ sí ibi tí afárá náà á wà. Nígbà tí wọ́n fẹ́ já afárá náà kúrò nínú ọkọ̀ akẹ́rù, wọ́n to táyà sílẹ̀. Afárá yìí ò ní jẹ́ ká pa àwọn ohun ẹlẹ́mìí tó wá lábẹ́ omi náà lára.

October 13, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Koríko tútù tó ń jẹ́ sedum ni wọ́n gbìn sí orí òrùlé yìí. Koríko yìí máa ń pàwọ̀dà lásìkò òtútù. Oríṣiríṣi koríko sedum tó tó mẹ́rìndínlógún (16) ni wọ́n gbìn sórí àwọn òrùlé. Tí wọ́n bá gbin koríko sórí òrùlé, ó máa ń dín ìṣòro omíyalé kù, ó máa ń dín ìnáwó kù, bẹ́ẹ̀ gbogbo ohun tá a máa ṣe ò ju ká kàn máa ro koríko náà lọ.

October 13, 2015— Ilé Gbígbé D

Káfíńtà kan ń parí iṣẹ́ lórí àwọn kọ́bọ́ọ̀dù inú ilé ìdáná tó wà fún yàrá kan lára àwọn ilé gbígbé. Nígbà tó fi máa di ìparí February 2016, Ẹ̀ka Tó ń Bójú To Iṣẹ́ Káfíńtà ti parí èyí tó ju ìdajì lára gbogbo kọ́bọ́ọ̀dù tó wà láwọn ilé ìdáná.

October 16, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Àwọn oníṣẹ́ iná ń fi iná táá máa tàn sábẹ́ àmì Ilé Ìṣọ́ tó wà lára ilé gogoro tí wọ́n kọ́ mọ́ ilé yìí.

October 21, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Wọ́n tan iná sí Ilé yìí, ilé gogoro tí wọ́n kọ́ mọ́ ọn àti ibi àbáwọlé rẹ̀ lálẹ́. Táwọn èèyàn bá wá ṣèbẹ̀wò sí Warwick, wọ́n máa lè rí oríléeṣẹ́ wa yìí àti àgbègbè ẹ̀ dáadáa látinú ilé gogoro náà.

October 22, 2015—Ọgbà Warwick

Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣe ọ̀nà kan táwọn ọkọ̀ á máa gbà tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Wọ́n ń da yẹ̀pẹ̀ dúdú sílẹ̀ kí wọ́n tó da ọ̀dà lé e, wọ́n sì ń po kọnkéré. Ohun tó dà bí àpò ṣaka tí wọ́n fi bo ibi tí wọ́n gbẹ́ lọ́ọ̀ọ́kán yẹn kì í jẹ́ kí omi òjò ṣan yẹ̀pẹ̀ síbi tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́.

November 9, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Àwọn òṣìṣẹ́ ń de òrùlé tó máa ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọlé tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ mọ́ òkè ẹnu ọ̀nà ibi tí ẹ̀rọ agbéniròkè máa wà. Irú òrùlé yìí mọ́kànlá ni wọ́n ṣe sí Ilé yìí, ó sì máa ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọlé láti ìta.

November 16, 2015—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Ajórinmọ́rin kan ń lo ẹ̀rọ tó ń fi atẹ́gùn gé irin láti gé páìpù táá máa gbé omi tútù.

November 30, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Káfíńtà kan ń kan àyè tó ṣeé gbé nǹkan sí tó máa ń wà níbí wíńdò. Tí wọ́n bá ti kàn án tán, tí wọ́n sì ti parí ògiri ibẹ̀, wọ́n máa gbé òmíì lé e.

December 17, 2015—Ọgbà Warwick

Àwọn òṣìṣẹ́ ń to òkúta pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ tí wọ́n ti ṣe sórí ilẹ̀ lọ́jọ́ tí òjò rọ̀. Láàárín, nínú fọ́tò yìí, wàá rí ẹ̀rọ gbọọrọ funfun kan tí wọ́n ń wọ́ lórí ilẹ̀ tí wọ́n ti da òkúta wẹẹrẹ sí, kí ibẹ̀ lè tẹ́jú. Lápá ìsàlẹ̀ níbí, wọ́n ń fi ẹ̀rọ kan to àwọn òkúta pẹlẹbẹ náà sórí ilẹ̀. Lápá òsì, wọ́n da àpò ńlá kan bo ilẹ̀ ibẹ̀ kí omi òjò má bàa wọ́ yẹ̀pẹ̀ ibẹ̀ lọ.

December 24, 2015—Ọgbà Warwick

Àwọn òṣìṣẹ́ ń tú wáyà iná, wọ́n sì ń wọ́ ọ lọ síbi ilé tí ẹ̀rọ tó ń gbé iná mọ̀nàmọ́ná jáde wà. Ẹ̀rọ yìí ló ń pín iná fún gbogbo ilé tó wà ní oríléeṣẹ́ wa yìí.

January 5, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Òṣìṣẹ́ kan ń parí iṣẹ́ lórí ìbòrí tí wọ́n ṣe sí ojú ọ̀nà táwọn èèyàn á máa fẹsẹ̀ rìn gbà láti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí fún Àwọn Àlejò sí Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́. Ìbòrí yìí ò ní jẹ́ kí òjò pa àwọn àlejò, á sì bò wọ́n lórí tí yìnyín bá ń rọ̀.

January 5, 2016—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Akọ́ṣẹ́mọsẹ́ kan ń tẹ kọ̀ǹpútà tó wà lára ẹ̀rọ ńlá tó ń mú kí omi gbóná kó lè ṣàtúnṣe sí bó ṣe ń ṣiṣẹ́. Irú ẹ̀rọ ńlá yìí mẹ́rin ló wà ní oríléeṣẹ́ wa, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

February 8, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Aṣọ Fífọ̀ rèé. Àwọn òṣìṣẹ́ tó mọ̀ nípa ẹ̀rọ ń ṣètò àwọn ẹ̀rọ táá máa fún aṣọ gbẹ síbẹ̀. Àwọn ẹ̀rọ yìí tóbi, wọ́n lè gba aṣọ tó pọ̀ gan-an lẹ́ẹ̀kan náà. Apá òsì yìí ni wọ́n á gbé àwọn ẹ̀rọ ìfọṣọ sí.

February 8, 2016—Ọgbà Tuxedo

Gerrit Lösch, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n tàtagbà ètò náà sáwọn ibòmíì tí wọ́n fi àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Warwick sí.

February 19, 2016—Ilé Gbígbé A

Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Inú Ilé Lọ́ṣọ̀ọ́ ń gbé kápẹ́ẹ̀tì wọ ọ̀kan lára àwọn ilé gbígbé. Kápẹ́ẹ̀tì tá a rà pé a máa lò ní oríléeṣẹ́ wa yìí pọ̀ gan-an.

February 22, 2016—Ọgbà Warwick

Láàárín September 2015 sí February 2016, a rí ìwé ilé tó fọwọ́ sí i pé káwọn èèyàn máa gbé Ilé Gbígbé C àti D gbà, àwọn òṣìṣẹ́ sì ti ń gbé ibẹ̀ báyìí. Wọ́n ti gbé gbogbo ẹ̀rọ agbéniròkè tó yẹ kó wà níbẹ̀ sí i. Wọ́n ti ṣe ojú ọ̀nà tó wọ àwọn Ilé Gbígbé náà tán, wọ́n sì ti to àwọn òkúta pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ sí i. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àyíká rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí torí pé òtútù ò dí wọn lọ́wọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ mú tó bí wọ́n ṣe rò.

February 24, 2016—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣe òrùlé ń parí iṣẹ́ lórí irin inú àjà ilé yìí. Ó ń fi irinṣẹ́ kan tó dà bí ẹsẹ̀ àgéré rìn torí kí ọwọ́ ẹ̀ lè tó òkè dáadáa. Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Ògiri àti Òrùlé Ilé ló máa ń ṣe àwọn ògiri ilé sílẹ̀, wọ́n á fi nǹkan wé e kó lè máa móoru, wọ́n á ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n á wá tò ó sínú ilé, wọ́n á sì parí iṣẹ́ lórí ẹ̀. Ẹ̀ka yìí ló tún máa ń fi ọ̀dà kan tí kì í jẹ́ kí iná ràn rẹ́ ibi tí wọ́n bá gbé wáyà tàbí òpó gbà lára ògiri.