Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn ilé tuntun sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú Quezon ní Philippines, a sì ń tún àwọn tó ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe. Nígbà tó ti jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Japan ló ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn tá a ń lò ní Philippines báyìí, a ti ṣàtúnṣe sí ilé ìtẹ̀wé tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Philippines, a sì ti sọ ọ́ di tuntun. Àwọn ẹ̀ka tó ń lò ó báyìí ni ẹ̀ka tó ń bójú tó kọ̀ǹpútà, ẹ̀ka tó ń yàwòrán ilé tí wọ́n sì ń kọ́ ọ, ẹ̀ka tó ń ṣàtúnṣe ilé, ẹ̀ka tó ń kó ìtẹ̀jáde ránṣẹ́ àti ẹ̀ka àwọn atúmọ̀ èdè. Ara àwọn àtúnṣe tá a ṣe sí ilé tá à ń lò fún ìtẹ̀wé tẹ́lẹ̀ àtàwọn ilé míì láti February 2014 sí May 2015 ló wà nínú àwọn fọ́tò tó wà nísàlẹ̀ yìí. A ṣètò pé a máa parí ìṣẹ́ yìí ní October 2016.

Bí ẹ̀ka ọ́fíìsì Philippines ṣe máa rí tá a bá kọ́ ọ tán rèé. Àwọn ilé tá à ń kọ́ àtàwọn èyí tá à ń ṣàtúnṣe sí ni:

  • Ilé 4 (Ilé Gbígbé)

  • Ilé 5 (Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Fídíò Tó sì Ń Gbohun Sílẹ̀ àti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn)

  • Ilé 6 (Àwọn Tó Ń Sọ Ojú Ilẹ̀ Di Ẹlẹ́wà, Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Tún Ọkọ̀ Ṣe, Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Jó Irin Pọ̀)

  • Ilé 7 (Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Bójú Tó Kọ̀ǹpútà, Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ, Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣàtúnṣe Ilé, Ilé Ìkówèéránṣẹ́, Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè)