Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ parí àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ kún ilé Watchtower Farms tó wà ní Wallkill, nílùú New York. Ọdún mẹ́fà sẹ́yìn ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí, àmọ́ iṣẹ́ náà gbomi nígbà tó ku ọdún méjì kó parí, èyí sì mú kí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀ pọ̀ sí i. Torí pé wọ́n á nílò ilé tí wọ́n á dé sí, wọ́n yá ilé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ládùúgbò yẹn.

Àwọn Ayálégbé

Báwo ló ṣe rí lára àwọn onílé pé wọ́n yá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilé wọn?

  • Onílé kan kọ̀wé pé, “Inú wa dùn sí àwọn tó gbélé wa yẹn gan-an. Iwájú [ilé tá a fi rẹ́ǹtì] lèmi àti ọkọ mi ń gbé, [a] sì rí i pé àwọn tá a gbà sílé yẹn máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa, ara wọn sì yá mọ́ọ̀yàn.”

  • Onílé míì, tóun náà ń gbé ní tòsí ilé tó fi rẹ́ǹtì kọ̀wé nípa àwọn tó gbà sílé, ó ní: “A ò níṣòro pẹ̀lú wọn rí. [A] ní odò kékeré kan téèyàn ti lè lúwẹ̀ẹ́ lẹ́yìnkùlé wa, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tá a yá nílé sì sábà máa ń wá síbẹ̀ tá a bá pè wọ́n. Nígbàkigbà tí wọ́n bá wá síbẹ̀, wọ́n máa ń gba tiwa rò, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wa. A máa ń gbádùn wọn tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ wa, ní báyìí tí wọ́n sì ti ń lọ, a ò ní rí wọn kí wọ́n máa sáré kiri lórí pápá mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Àárò wọn á sọ wá o.” Obìnrin onílé náà fi kún un pé: “Àwọn ayálégbé tó dáa jù rèé.”

  • Onílé kan sọ pé, “Inú wa dùn gan-an, torí pé kì í kàn ṣe ayálégbé làwọn èèyàn yìí jẹ́ sí wa, aládùúgbò wa ni wọ́n.”

Àwọn Ilé tí Wọ́n Yá

Kí làwọn onílé sọ nípa bí wọ́n ṣe bá ilé wọn lẹ́yìn tí àwọn tó yá a kúrò níbẹ̀?

  • “Wọn kì í jẹ owó ilé rárá, wọ́n [sì] lo ilé náà dáadáa, bá a ṣe bá ilé náà múnú wa dùn gan-an.”

  • Onílé kan tá a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ sọ pé, “A dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀yin àti gbogbo iléeṣẹ́ Watchtower fún bẹ́ ẹ ṣe tọ́jú ilé wa.” Ó sọ pé òun ò retí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa tún ilé náà ṣe “tó báyìí.”

  • Obìnrin kan sọ pé, “Torí pé a mọ̀ pé ẹ̀yin ajẹ́rìí máa ń ṣòótọ́, a ò [béèrè] àsansílẹ̀ owó lọ́wọ́ wọn. Rèǹtè-rente la bá àwọn ilé ta a yá wọn.”

  • Lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá onílé kan ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lára ilé rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Báwo ni mo ṣe lè máa rí àwọn èèyàn yín gbéṣẹ́ fún?” Ó ní, “Tẹ́ ẹ bá sọ pé ọjọ́ báyìí lẹ máa wá ṣiṣẹ́ kan, ẹ máa wá, ẹ ò sì ní pẹ́ dé rárá. Àwọn tí mo máa ń gbéṣẹ́ fún ò ṣeé bá ṣàdéhùn ní tiwọn.”

Bó Ṣe Rí Lára Wọn

  • Kí owó ilé kan tí wọ́n yá tó tán, onílé náà kọ̀wé pé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá máa sanwó ọdún míì, òun máa dín owó wọn, kóun lè “fà wọ́n lójú mọ́ra.”

  • Onílé míì sọ pé: “Tí àyè ẹ̀ bá tún yọ, ó máa wù wá ká yá iléeṣẹ́ Watchtower ní ilé wa.”