Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Kọ́ Orílé-Iṣẹ́ Tuntun

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Kọ́ Orílé-Iṣẹ́ Tuntun

Ní July ọdún 2009, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ra ilẹ̀ kan sí àríwá ìlú New York kí wọ́n lè gbé orílé-iṣẹ́ wọn lọ síbẹ̀. Ilẹ̀ hẹ́kítà méjìlélọ́gọ́rùn-ún [102] náà wà ní nǹkan bí ọgọ́rin [80] kìlómítà sí ibi tí orílé-iṣẹ́ wọn wà nísìnyí ní Brooklyn, New York, tí wọ́n ti wà láti ọdún 1909.

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lá a máa gbé níbi tuntun náà tí wọ́n á sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ó máa ní ọ́fíìsì, ilé ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn àti ilé gbígbé mẹ́rin. Wọ́n tún fẹ́ kọ́ ilé ìgbàlódé kan tí wọ́n máa kó àwọn ohun àtijọ́ sí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tòde òní.

Hẹ́kítà méjìdínlógún ni wọ́n máa kọ́lé sí lára ilẹ̀ tí wọ́n rà náà, wọ́n á sì fi igbó àti omi tó yí i ká sílẹ̀ bó ṣe wà láìkọ́ nǹkan kan síbẹ̀. Wọn ò ní gbin koríko tó pọ̀ láti tún ojú ilẹ̀ ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn igi àti koríko tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti dára tó, wọ́n á sì fi wọ́n sílẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Àwọn ayàwòrán ilé ti ya ilé náà lọ́nà tí kò fi ní máa fi iná mànàmáná àtàwọn nǹkan míì ṣòfò, kò ní fi bẹ́ẹ̀ pa àyíká lára, owó tí wọ́n á sì máa ná sí i lórí á mọ níwọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, ewéko tó le, tí kò fi bẹ́ẹ̀ nílò àtúnṣe ni wọ́n máa fi bo òrùlé ilé náà, èyí kò ní jẹ́ kí omi òjò tá a máa dà sílẹ̀ pọ̀ jù, kò sì ní jẹ́ kí ooru tàbí òtútù pọ̀ jù. Wọ́n máa kọ́ ọ́fíìsì náà lọ́nà tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn á fi lè wọlé, tí wọ́n á fi máa ríran kedere. Wọn tún máa rí sí i pé wọn kò fomi ṣòfò.

Kí nìdí tí wọ́n fi fẹ́ kó lọ sí ibòmíì? Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn orílẹ̀-èdè kan ti bẹ̀rẹ̀ sí i tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ pé Brooklyn nìkan ni wọ́n ti ń tẹ̀ ẹ́ tẹ́lẹ̀. Ní ọdún 2004, wọ́n gbé iṣẹ́ títẹ ìwé àti kíkó ìwé ránṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sí Wallkill, nílùú New York, tó wà ní nǹkan bí kìlómítà márùnlélógóje [145] ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Brooklyn.

Owó tí wọ́n ń ná níbi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ tún wà lára ìdí tí wọ́n fi fẹ́ kúrò níbẹ̀. Iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní Brooklyn àti títún àwọn nǹkan ṣe máa ń ná wọn lówó gan-an. Bí wọ́n ṣe fẹ́ kó lọ sí ilé tó wà lójú kan yìí, á mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí túbọ̀ lè lo owó táwọn èèyàn fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó dára sí i.

Wọ́n ṣì máa ṣàyẹ̀wò ipa tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà máa ní lórí àyíká ibẹ̀ kí ìjọba tó fọwọ́ sí i pé kí iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀. Bí gbogbo nǹkan bá lọ bá a ṣe rò, ó yẹ kí iṣẹ́ ìkọ́lé náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2013 kó sì parí lẹ́yìn ọdún mẹ́rin.

Yàtọ̀ sí ibi tí wọ́n ti ń tẹ̀wé ní Wallkill, ní New York, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ní ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan sí Patterson, New York. Wọ́n tún ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lé ní mílíọ̀nù méje àtàbọ̀.