Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 2 (September 2015 sí August 2016)

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 2 (September 2015 sí August 2016)

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kó kúrò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Mill Hill nílùú London lọ síbi tó jìn tó máìlì mẹ́tàlélógójì (43) sí ìlà oòrùn, nítòsí ìlú Chelmsford, ní Essex. Àwọn fọ́tò yìí máa jẹ́ kó o rí bí iṣẹ́ ṣe lọ sí ní September 2015 sí August 2016 lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tuntun tá à ń kọ́.

October 29, 2015​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń da kọnkéré síwájú ibi tí wọ́n á ti máa tún àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìkọ́lé ṣe.

December 9, 2015​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń de òrùlé ilé tí wọ́n fẹ́ máa lò fún ọ́fíìsì àti yàrá ìjẹun nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lọ́wọ́.

January 18, 2016​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Níbi àbáwọlé, òṣìṣẹ́ kan ń fi katakata gé àwọn igi kan kúrò. Katakata yẹn ní ẹ̀rọ kan tó máa ń di igi mú, á gé e, katakata náà á wá gbé igi yẹn kúrò. Kí iṣẹ́ ìkọ́lé náà tó parí, àwọn tó ń bójú tó àyíká máa gbin ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi míì láti fi rọ́pò àwọn èyí tí wọ́n gé.

March 31, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń kó ìdọ̀tí kúrò lórí ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ni ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ ló fi àwọn nǹkan yẹn sílẹ̀ níbẹ̀. Tí wọ́n bá ti kó ìdọ̀tí náà kúrò tán, yẹ̀pẹ̀ yẹn á ṣeé lò.

April 14, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ fẹ́ fi ẹ̀rọ ńlá kan gbé àwọn ilé onípákó tí wọ́n fẹ́ máa lò fúngbà díẹ̀ yìí síbi tó máa wà. Ibẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé àtàwọn agbaṣẹ́ṣe tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ á máa fi ṣe ọ́fíìsì tí wọ́n á ti máa ṣiṣẹ́.

May 5, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣa àwọn ohun tó ṣì wúlò, wọ́n máa wá kó o lọ síbi tí wọ́n á ti tún un lò. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé sọ pé káwọn òṣìṣẹ́ ṣa èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ohun tó bá ṣì wúlò kúrò níbi ilẹ̀ tí wọ́n ń da ìdọ̀tí sí, àwọn òṣìṣẹ́ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀, kódà wọ́n ń ṣe é ju bí wọ́n ṣe rò. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n wólé, bíi bíríkì, kọnkéré àti gẹdú, ni wọ́n ti kó lọ síbòmíì tí wọ́n á ti lò ó lórí ilẹ̀ náà.

May 23, 2016​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Òṣìṣẹ́ kan ń kó yẹ̀pẹ̀ dí kòtò kan tí wọ́n gbé irinṣẹ́ gbà. Àwọn ohun èlò tó jẹ́ ti ilé táwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé á máa gbé fúngbà díẹ̀ ni wọ́n gbé gba nínú kòtò yìí.

May 26, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Agbaṣẹ́ṣe kan ń yẹ yẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ wò kó lè mọ̀ bóyá yẹ̀pẹ̀ yẹn máa ṣeé lò tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn ọ̀nà tó máa gba orí ilẹ̀ náà.

May 31, 2016​—Bí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ṣe máa rí

Ní May 31, 2016, Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọwọ́ sí i pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa rí bó ṣe wà nínú àwòrán yìí. Bí wọ́n ṣe fọwọ́ sí i yìí, tó sì jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ìlú náà ti fọwọ́ sí ètò tá a ṣe, á jẹ́ pé kíṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ló kù.

June 16, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń yọ ohun tí kò dáa kúrò lára yẹ̀pẹ̀ tí wọ́n kó lórí ilẹ̀ náà. Tí wọ́n bá ti yọ ọ́ tán, wọ́n lè lo yẹ̀pẹ̀ náà níbikíbi. Èyí á jẹ́ kí wọ́n ṣọ́wó ná, torí ó máa ná wọn lówó tí wọ́n bá fẹ́ kó yẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ náà kúrò, ó sì máa ná wọn lówó láti ra òmíì rọ́pò.

June 20, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣe ibi tí ọ̀nà àbáwọlé gangan máa wà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé odindi oṣù kan ni òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá fi rọ̀, tó sì sọ gbogbo ilẹ̀ di ẹrọ̀fọ̀, iṣẹ́ náà ò dáwọ́ dúró.

July 18, 2016​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Wọ́n ń fi ẹ̀rọ wọ́n omi sílẹ̀ kí eruku lè dín kù. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àjọ Considerate Constructors Scheme, kí wọ́n lè tẹ̀ lé ìlànà tí ìlú ń tẹ̀ lé lórí iṣẹ́ ìkọ́lé. Ara òfin tí àjọ náà sì ṣe ni pé kí ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé ti ń lọ máa mọ́ tónítóní. Òfin tí wọ́n ṣe yìí bá ìlànà Bíbélì mu, torí tá a bá tẹ̀ lé e, ó máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fáwọn aráàlú, a sì gba tàwọn aládùúgbò rò.

July 18, 2016​—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Oníṣẹ́ irin kan ń gé irin tí wọ́n máa fi gbé àwọn ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀rọ amúlétutù dúró.

July 22, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń jọ yẹ̀pẹ̀ kúrò lára òkúta. Katakata tó wà lápá òsì yìí ń da yẹ̀pẹ̀ olókùúta sínú ẹ̀rọ kan tó wà láàárín nínú àwòrán yìí. Oríṣiríṣi asẹ́ ló wà nínú ẹ̀rọ yìí, ó lè yọ àwọn òkúta ńlá, ó sì lè yọ àwọn òkúta tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi. Tó bá ti sẹ́ ẹ tán, yẹ̀pẹ̀ tó dáa máa lọ sísàlẹ̀ ẹ̀rọ náà. Ẹ̀rọ náà ní ọwọ́ mẹ́ta tó máa wá kó yẹ̀pẹ̀ náà lọ sínú àwọn katakata kéékèèké.

July 22, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ yẹ̀pẹ̀ kúrò kí ilẹ̀ náà lè tẹ́jú, kí ilé náà bàa lè rí bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí tí wọ́n bá kọ́ ọ tán.

August 18, 2016​—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

INí àárín fọ́tò yìí lọ́wọ́ òsì, àwọn agbaṣẹ́ṣe ti ṣe ilẹ̀ yẹn kó tẹ́jú, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ilé gbígbé. Ilé kan wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn, lápá òsì pátápátá. Ibẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé á máa gbé. Ilé náà lè gba òṣìṣẹ́ méjìdínlọ́gọ́fà [118].