Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Fọ́tò Orílé-Iṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick—Apá 3 (January sí April 2015)

Fọ́tò Orílé-Iṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick—Apá 3 (January sí April 2015)

Wo ọ̀wọ́ àwọn fọ́tò yìí kó o lè rí ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tuntun tẹ̀ síwájú dé láti January sí April 2015.

Bí orílé-iṣẹ́ wa ní Warwick ṣe máa rí tá a bá kọ́ ọ tán rèé. Wò ó láti apá ọ̀tún pa dà sí apá òsì:

  1. Ibi Tí A Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

  2. Ibi Ìgbọ́kọ̀sí fún Àwọn Àlejò

  3. Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

  4. Ilé Gbígbé B

  5. Ilé Gbígbé E

  6. Ilé Gbígbé D

  7. Ilé Gbígbé A

  8. Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

January 2, 2015—Ibi Tí A Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

Harold Corkern, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé Bíbélì kan tó ní àkòrí náà, “Máa Tẹ̀ Síwájú Láti Lo Ẹ̀bùn Rẹ.” Àwọn tó ń sọ àsọyé máa ń wá sí Warwick lóòrèkóòrè láti fún àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ níṣìírí.

January 14, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Wọ́n fi tapólì funfun bo ara ilé náà kó lè dáàbò bo àwọn òṣìṣẹ́, á sì jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ wọn lọ lásìkò òtútù. Ilé yìí ní yàrá ìjẹun, ibi ìtọ́jú aláìsàn, yàrá ìdáná àti yàrá ìfọṣọ.

January 16, 2015—Ilé Gbígbé E

Àwọn oníṣẹ́ iná ń múra láti fa wáyà iná wọlé. Wáyà tó gùn ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ẹsẹ bàtà (40,000 ft) ni wọ́n ti fà káàkiri àwọn ilé gbígbé náà. Gbàrà tá a ti ra ilẹ̀ tó wà ní Warwick ni iṣẹ́ iná ti bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀, yóò sì máa bá a lọ títí a ó fi parí gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé yìí.

January 16, 2015—Ilé Gbígbé A

Òṣìṣẹ́ kan ń fi téèpù wé etí ọ̀dẹ̀dẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kó lè máa ta omi dànù. Wọ́n fi èròjà olómi kan tí wọ́n ń pè ní polymethyl methacrylate (PMMA) kun ọ̀dẹ̀dẹ̀ àwọn ilé yìí lókè pátápátá kó lè máa ta omi dànù.

January 23, 2015—Ilé Gbígbé A

Bàbà kan àti ọmọ rẹ̀ obìnrin ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti fa wáyà iná wọnú àwọn yàrá kí iná lè tàn nínú àwọn ilé gbígbé náà.

February 6, 2015—Ibi Tí A Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

Àwọn òṣìṣẹ́ ń jẹun ọ̀sán nínú ibi tí wọ́n ṣì ń lò bíi yàrá ìjẹun. Àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ló ń jẹun lójúmọ́.

February 12, 2015—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Àwọn òṣìṣẹ́ kan ń de irin tẹ́ẹ́rẹ́ pọ̀ kí wọ́n lè kún kọnkéré àwọn ọ́fíìsì kéékèèké tí wọ́n á ti máa ṣe àtúnṣe ilé.

February 12, 2015—Ilé Gbígbé D

Lẹ́tà tí àwọn ọmọ kan kọ láti fi hàn pé wọ́n mọrírì iṣẹ́ takuntakun táwọn òṣìṣẹ́ náà ń ṣe. Ọ̀pọ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́ náà yọ̀ǹda láti ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀. Tá a bá fojú bù ú, àwọn òṣìṣẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn ún [500] ló wá ń ṣiṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní February, àwọn ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] òṣìṣẹ́ ló wá ń ṣiṣẹ́ ní Warwick lójoojúmọ́.

February 24, 2015—Ọgbà Warwick

Gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé náà ti parí kọjá ìdajì. Ní January sí April 2015 ni wọ́n ti parí àwọn ìpìlẹ̀ ilé gbígbé àti ìpìlẹ̀ onírin Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́. Bí ìyẹn ṣe ń lọ lọ́wọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ń gbé àwọn ògiri kọnkéré tí wọ́n ti kún sílẹ̀ sára Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́, wọ́n ń ṣe àwọn ojú ọ̀nà téèyàn lè gbà dé àwọn ilé gbígbé, wọ́n sì ń tún adágún Odò Sterling Forest Lake (Blue Lake) ṣe.

February 25, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Bí ilé gogoro náà ṣe rí rèé téèyàn bá wò ó láti ìsàlẹ̀. Àwọn kọ́lékọ́lé tá a háyà ló ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà àti bó ṣe máa rí, àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú ló sì da kọnkéré rẹ̀.

February 26, 2015—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Òtútù mú lọ́jọ́ tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé de irin àjà àkọ́kọ́ ilé yìí. Yìnyín já bọ́ gan-an ní Warwick nígbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé ń lọ lọ́wọ́ láàárín oṣù January sí March. Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń fá yìnyín ló bá wa palẹ̀ gbogbo rẹ̀ mọ́, àwọn òṣìṣẹ́ wá lọ ń yáná níbi kan tí wọ́n ṣètò fún àwọn tó bá fẹ́ kí ara wọn móoru.

March 12, 2015—Ibi Ìgbọ́kọ̀sí fún Àwọn Àlejò

Wọ́n kan àwọn páànù onírin mọ́ àwọn irin ìrólé. Wọn á ti parí kíkan òrùlé onírin àwọn ilé gbígbé náà nígbà tó bá fi máa di April. Tó bá fi máa di àárín oṣù June wọ́n á ti kan òrùlé Ilé Gbígbé B parí.

March 18, 2015—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Òun nìyẹn lọ́ọ̀ọ́kán téèyàn bá wo apá ibi tí Ilé Gbígbé B wà.

March 18, 2015—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Àwọn oníṣẹ́ omi dúró sí Ibi Ìgbọ́kọ̀sí, wọ́n ń wo àwòrán tí wọ́n máa fi ṣiṣẹ́. Àwòrán tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [3,400] tí ìjọba fọwọ́ sí ni wọ́n máa lò fún iṣẹ́ ìkọ́lé yìí.

March 23, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Àwọn òṣìṣẹ́ kan fi ẹ̀rọ gun òkè láti ta tapólì funfun sára ilé kó lè bò ó. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ lóríṣiríṣi ni wọ́n ṣe fún àwọn òṣìṣẹ́ lórí bí wọ́n ṣe lè lo ẹ̀rọ tó ń gbé nǹkan sókè àtàwọn irinṣẹ́ míì lọ́nà tí kò fi ní fa ìpalára. Lára ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa ààbò tí wọ́n ṣe fáwọn òṣìṣẹ́ ni bí wọ́n ṣe ń lo oríṣiríṣi ẹ̀rọ tó ń gbé nǹkan sókè, bí wọn ò ṣe ní jábọ́ tí wọ́n bá wà níbi tó ga, ohun tó yẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé náà, bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń mí àtàwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ míì.

March 30, 2015—Ọgbà Warwick

Àwọn ilé gbígbé rèé lápá òsì. Tó bá fi máa di April, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀rọ àti àwọn oníṣẹ́ iná á ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn ní pẹrẹu lórí Ilé Gbígbé A, B àti E gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán yìí. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí i rẹ́ Ilé Gbígbé D (kò sí nínú àwòrán yìí), wọ́n ti ń lẹ àwo, ìyẹn tiles mọ́ ara ilé náà, wọ́n sì ti ń kun ilé náà.

April 15, 2015—Ilé Gbígbé B

Àwọn òṣìṣẹ́ méjì wà lórí ẹ̀rọ tó ń gbé èèyàn sókè, wọ́n ń fi kẹ́míkà kan kun ìta ilé náà. Ó gbà wọ́n tó oṣù méjì láti kun gbogbo àwọn ilé gbígbé náà pátá lọ́kọ̀ọ̀kan.

April 27, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Àwọn bíríkìlà ń fi òkúta granite mọ ògiri. Ibi tí wọ́n ń kọ́ yìí ni wọ́n á ti máa já ẹrù, wọ́n á sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ míì níbẹ̀.

April 30, 2015—Ọgbà Warwick

Òmùwẹ̀ kan tá a háyà ń bá wa pààrọ̀ nǹkan nínú odò adágún Blue Lake. Tí ìjì líle bá jà tàbí tí omíyalé bá ṣẹlẹ̀, ńṣe la ó kàn tẹ bọ́tìnnì kan tí omi náà á sí fà.