Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Fọ́tò Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick, Apá 6 (March sí August 2016)

Fọ́tò Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick, Apá 6 (March sí August 2016)

Àwọn fọ́tò yìí máa jẹ́ kó o rí ibi táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báṣẹ́ dé ní oríléeṣẹ́ wa tuntun, wàá sì rí báwọn èèyàn ṣe kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́lé náà láàárín March sí August 2016.

Fọ́tò oríléeṣẹ́ wa tá a ti kọ́ tán ní Warwick. Wò ó láti apá òsì sí apá ọ̀tún:

  1. Ibi Tá Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

  2. Ibi Ìgbọ́kọ̀sí fún Àwọn Àlejò

  3. Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

  4. Ilé Gbígbé B

  5. Ilé Gbígbé D

  6. Ilé Gbígbé C

  7. Ilé Gbígbé A

  8. Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

March 16, 2016​—Ọgbà Warwick

Àwọn tó ń bójú tó àyíká ń já igi óákú àti igi maple nínú ọkọ̀ sí ibi tí wọ́n ń kó igi sí. Àwọn igi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìn sí ọgbà Warwick lé ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [1,400].

March 23, 2016​—Ibi Tá Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

Àwọn òṣìṣẹ́ ní Warwick wà níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, èyí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ń ṣe lọ́dọọdún. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [384] èèyàn ló wá síbi èyí tí wọ́n ṣe nínú ilé yìí.

April 15, 2016​—Ọgbà Warwick

Àwọn káfíńtà ń ṣe gíláàsì sí ojú wíńdò ilé kékeré tó máa wà lẹ́nu géètì ọgbà náà. Àwọn tó bá ń ṣiṣẹ́ lẹ́nu géètì yìí lá máa jẹ́ kí àwọn àlejò wọlé, àwọn lá máa ṣọ́ ọgbà, tí wọ́n á sì máa darí àwọn mọ́tò tó ń wọlé tó sì ń jáde nínú ọgbà.

April 19, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Bàbá àti ọmọ ló jọ ń ṣiṣẹ́ yìí. Wọ́n ń lẹ kápẹ́ẹ̀tì kéékèèké tó nípọn mọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tó gba àárín àwọn ọ́fíìsì ní àjà kejì ilé yìí. Irú àwọn kápẹ́ẹ̀tì kéékèèké tó nípọn yìí ni wọ́n lẹ̀ mọ́ ojú ọ̀nà táwọn èèyàn sábà máa ń gbà, torí pé á rọrùn láti ṣí èyí tó bá bà jẹ́, kí wọ́n sì lẹ òmíì síbẹ̀.

April 27, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Àwọn káfíńtà ń fi àwọn pákó tó ṣeé tú palẹ̀ pín àwọn ọ́fíìsì. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ̀ka tó bá máa lo àwọn ọ́fíìsì yìí láti tún àwọn ọ́fíìsì wọn tò bí wọ́n bá ṣe fẹ́.

May 10, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Òṣìṣẹ́ kan ń ṣiṣẹ́ níbi ilé ìtura tó wà fáwọn àlejò, tó wà nítòsí ibi àbáwọlé, kó tó di pé àwọn òṣìṣẹ́ míì máa wá pín in sí yàrá kéékèèké, kí wọ́n sì gbé àwo àti ẹ̀rọ omi sí i.

May 26, 2016​—Ọgbà Warwick

Àwọn Tó Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàjáwìrì ń fi bí wọ́n ṣe lè máa pa iná kọ́ra. Tí àwọn panápaná yìí bá ń ṣètò láti yára wá nǹkan ṣe tírú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀, wọ́n máa lè dáàbò bo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ náà àtàwọn ilé tó wà níbẹ̀. Èyí á tún jẹ́ kí ẹrù tó wà lọ́rùn àwọn panápaná ìjọba fúyẹ́.

May 30, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Olùtọ́jú èrò kan ń fọwọ́ sọ fáwọn òṣìṣẹ́ tó wà nínú yàrá ìjẹun pé Ìjọsìn Òwúrọ̀ máa tó bẹ̀rẹ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí wọ́n máa wo Ìjọsìn Òwúrọ̀ látorí tẹlifíṣọ̀n níbí.

May 31, 2016​—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Káfíńtà kan ń lẹ àmì mọ́ ara ògiri, ó wá ń fi ẹ̀rọ oníná kan wò ó bóyá ó dúró dáadáa àbí ó wọ́ ṣẹ́gbẹ̀ẹ́. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] àmì tí wọ́n ṣe kó lè máa tọ́ àwọn tó ń gbé ní oríléeṣẹ́ àtàwọn àlejò sọ́nà.

June 1, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Ajórinmọ́rin kan ń ṣe irin síbi àtẹ̀gùn téèyàn máa gbà láti ibi àbáwọlé débi gbọ̀ngàn ńlá tó wà ní oríléeṣẹ́. Aṣọ tó nípọn tó wà nísàlẹ̀ àwòrán yìí ló fi bo àwọn nǹkan tó wà nítòsí kí iná má bàa ràn wọ́n.

June 9, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Òṣìṣẹ́ kan ní Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Ògiri àti Òrùlé ń parí iṣẹ́ lára ògiri, níbi téèyàn máa gbà tó bá fẹ́ lọ wo àtẹ tá a pè ní “Faith in Action,” ìyẹn ọ̀kan lára àwọn àtẹ tí àwọn àlejò lè wò fúnra wọn. Èèyàn máa rí ohun tí àtẹ kọ̀ọ̀kan dá lé lára ohun táwọn ayàwòrán ilé ṣe síbi àwọn àtẹ náà.

June 16, 2016​—Ibi Tá Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

Àwọn òṣìṣẹ́ ń fọ ilẹ̀ kí wọ́n tó fi ẹ̀rọ kì í. Kíkì tí wọ́n bá ki ilẹ̀ náà kò ní jẹ́ kó tètè bà jẹ́, eruku ò ní máa lẹ̀ mọ́lẹ̀, táyà ọkọ̀ ò ní fàlà síbẹ̀, á sì rọrùn láti máa bójú tó o.

June 29, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Àwọn káfíńtà kan ń to gíláàsì tó nípọn sórí ohun tí wọ́n fi bo ibi àbáwọlé. Èyí á jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ lè máa wọ ibi àbáwọlé náà.

June 29, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Tọkọtaya kan jọ ń ṣiṣẹ́ lórí ẹnu ọ̀nà tí àwọn àlejò máa gbà wọlé tí wọ́n bá fẹ́ wá wo àtẹ tá a pè ní “The Bible and the Divine Name.”

July 6, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Káfíńtà kan ń de àga mọ́lẹ̀ nínú gbọ̀ngàn ńlá yìí. Ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìdínlógún [1,018] ni àga tó wà nínú gbọ̀ngàn yìí. Ibẹ̀ ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì á máa lò tí wọ́n bá fẹ́ ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ètò míì tó wà fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì.

July 9, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Níbi àbáwọlé, àwọn káfíńtà, àwọn oníṣẹ́ iná àtàwọn òṣìṣẹ́ míì ń ṣe àmì ńlá kan tí iná á máa tàn lára ẹ̀, òun làwọn àlejò máa kọ́kọ́ rí kí wọ́n tó wọlé.

July 13, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Àwọn méjì lára àwọn tó ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ń pọnmi fún àwọn òṣìṣẹ́ níbi àbáwọlé. Léraléra ni wọ́n máa ń rán àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé létí pé kí wọ́n máa mumi dáadáa, pàápàá lásìkò ooru.

July 19, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Káfíńtà kan ń ṣe ibi tí wọ́n máa kó àwọn Bíbélì tó ṣọ̀wọ́n sí níbi àtẹ tá a pè ní “The Bible and the Divine Name.” Àá máa pààrọ̀ ohun tó wà nínú àtẹ yìí látìgbàdégbà, àá máa kó àwọn Bíbélì míì síbẹ̀ àtàwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó jẹ mọ́ Bíbélì.

July 22, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Káfíńtà kan ń ṣiṣẹ́ lórí àwòrán ilẹ̀ tó wà lára ògiri níbi àbáwọlé. Ẹ̀rọ oníná kan ló jẹ́ kí àwọn àwòrán búlúù kan hàn lára ògiri yẹn, káfíńtà yìí wá ń lẹ nǹkan mọ́ ibi tí àwòrán ilẹ̀ Australia àti tàwọn erékùṣù tó wà ní Gúúsù ìlà oòrùn Éṣíà ti fara hàn. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje [700] èdè ni wọ́n fi kọ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sára ògiri náà.

July 23, 2016​—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Wọ́n ń dá ìdílé Bẹ́tẹ́lì lẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí oríléeṣẹ́ ní Warwick, kí wọ́n lè máa yẹra fáwọn ohun kan tó ṣì wà nínú ọgbà tó lè wu ẹ̀mí wọn léwu.

August 17, 2016​—Yàrá tí Wọ́n ti Ń Ṣe Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW

Àwọn òṣìṣẹ́ ń gbé irin ńlá kan kọ́ sókè yàrá yìí, irin yìí ló máa gbé iná dúró, tábìlì tí ẹni tó ń ṣe ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW máa jókòó sí á sì wà lábẹ́ iná yẹn. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ohun tí wọ́n ń tò sínú yàrá yìí ni wọ́n kó wá láti Brooklyn, níbi tí wọ́n ti ń ṣe ètò Tẹlifíṣọ̀n JW tẹ́lẹ̀.

August 24, 2016​—Ọgbà Warwick

Oníṣẹ́ iná kan ń ṣe iná sára àmì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sí ojú ọ̀nà téèyàn máa gbà dé inú ilé. Bẹ̀rẹ̀ láti September 1, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀ka tó wà ní oríléesẹ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Warwick.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÀWỌN WO LÓ Ń ṢE ÌFẸ́ JÈHÓFÀ LÓDE ÒNÍ?

Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?

Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi àrà ọ̀tọ̀ kan tó ní ìdí pàtàkì tí a fi kọ́ ọ. Mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.