Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Fọ́tò Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick, Apá 4 (May sí August 2015)

Fọ́tò Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick, Apá 4 (May sí August 2015)

Wo ọ̀wọ́ àwọn fọ́tò yìí kó o lè rí ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tuntun tẹ̀ síwájú dé láti May sí August 2015. Wàá tún rí bí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà lásìkò yẹn.

Bí orílé-iṣẹ́ wa ní Warwick ṣe máa rí tá a bá kọ́ ọ tán rèé. Wò ó láti apá òsì sí apá ọ̀tún:

  1. Ibi Tá Ó Ti Máa Tún Ọkọ̀ Ṣe

  2. Ibi Ìgbọ́kọ̀sí fún Àwọn Àlejò

  3. Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

  4. Ilé Gbígbé B

  5. Ilé Gbígbé D

  6. Ilé Gbígbé C

  7. Ilé Gbígbé A

  8. Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

May 6, 2015—Ọgbà Warwick

Ọ̀kan lára àwọn tó máa ń ri nǹkan mọ́lẹ̀ ń gbé ẹ̀rọ kan sínú adágún Sterling Forest Lake. Ẹ̀rọ yìí ní kò ní jẹ́ kí àwọn ìdọ̀tí ńlá dí ojú ibi tí omi náà ń gbà ṣàn jáde.

May 6, 2015—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Àwọn tó ń kọ́lé ń fi ẹ̀rọ fọ́n kọnkéré sára ìgbátí òrùlé ilé tó jẹ́ Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé. Bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀rọ fọ́n kọnkéré yìí máa ń yá jú kí wọ́n máa rọ kọnkéré sínú ẹ̀ lọ.

May 15, 2015—Ọgbà Warwick

Ayàwòrán kan tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Ṣàkọsílẹ̀ ń yàwòrán bí wọ́n ṣe ń kọ́lé. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ní Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wo àwọn fọ́tò iṣẹ́ ìkọ́lé náà kí wọ́n lè mọ bí iṣẹ́ ṣe ń lọ sí.

May 30, 2015—Ilé tó wà ní ìlú Tuxedo

Àwọn tọkọtaya yìí yọ̀ǹda ara wọn láti gúúsù Californa kí wọ́n lè bá Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Ẹ̀rọ Omi ṣiṣẹ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ló dé sí Tuxedo lọ́jọ́ yìí. Ìlú Tuxedo ni wọ́n ti máa ń to àwọn ohun ìkọ́lé tí wọ́n á lò ni Warwick jọ. Àwọn ẹni tuntun tó tó ọgọ́rùn-ún méje ó lé méje (707) ló dé síbẹ̀ ní August 1.

June 9, 2015—Ilé Gbígbé B

Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń fi ẹ̀rọ tó máa ń gbé ẹrù tó wúwo gbé ògiri tá a ti mọ kalẹ̀ lọ síbi tó yẹ kó wà. Gbogbo ilé gbígbé tó kù ni wọ́n ti gbé ògiri sí. Ilé gbígbé B yìí ni wọ́n ṣe gbẹ̀yìn.

June 16, 2015—Ilé Gbígbé C àti D

Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń gbé afárá tó so Ilé Gbígbé C àti D mọ́ra sí àyè rẹ̀.

June 25, 2015—Ilé Gbígbé C

Àwọn tó ń mú kí ilẹ̀ rẹwà ń gbin koríko sí apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ náà.

July 2, 2015—Ọgbà Warwick

Àwọn tó ń kọ́lé ń tún ibi tí omi á máa dúró sí ṣe. Ibí yìí àti inú adágún ni omi á máa dúró sí.Àárín ọdún 1950 sí 1959 ni wọ́n kọ́kọ́ kọ́ ibí yìí. Wọ́n ń tún un gbẹ́ tórí òjò àti ìjì tó ń jà ládùúgbò yìí ti wá pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kí omíyalé má bàa yọ wá lẹ́nu ní Warwick.

July 15, 2015—Ilé Gbígbé A

Kó má bàa sí ìkọlùkọgbà níbi tá a ti ń ṣiṣẹ́, títí dòru làwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ inú ilé máa ń ṣiṣẹ́, irú bí àwọn tó ń kun ilé àtàwọn tó ń wé páìpù kí omi inú wọn má bàa máa dì. Láwọn àsìkò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ dòru yìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló máa ń ṣiṣẹ́ láàárín aago mẹ́ta ọ̀sán sí aago méjì òru.

July 20, 2015—Ilé Gbígbé D

Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣètò bí ilé á ṣe máa gbóná tàbí tutù ń kọ́ òṣìṣẹ́ míì bó ṣe máa wé àwọn páìpù kí omi inú wọn má bàá máa dì.

July 21, 2015—Ilé Gbígbé B

Wọ́n ń kun afárá tí wọ́n á máa gbà láti Ilé Gbígbé B lọ sí Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé.

July 27, 2015—Ilé tó wà ní ìlú Tuxedo

Ní ibi ìgbọ́kọ̀sí tó wà lẹ́yìn, ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ń dúró de ọkọ̀ tó máa gbé wọn lọ sí Warwick. Ṣe ni àwọn ọkọ̀ tó máa ń gbé àwọn òṣìṣẹ́ lọ síbi iṣẹ́ ìkọ́lé náà tí wọ́n á tún gbé wọn bọ̀ máa ń tò tẹ̀ léra.

July 27, 2015—Ilé tó wà ní ìlú Tuxedo

Wọ́n ń gẹrun fún mẹ́ta lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Warwick. Irun èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ni wọ́n máa ń gẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nílùú Tuxedo, nílùú Warwick àti níbi tí wọ́n ń kẹ́rù sí nílùú Montgomery.

August 3, 2015—Ọgbà Warwick

Ibí yìí ni ooru àti òtútù á ti máa tú jáde. Wọ́n ń ṣe ìpìlẹ̀ tí wọ́n máa da kọnkéré sí níbẹ̀. Wọ́n ti gbẹ́ kànga ọgọ́fà (120) tó jìn gan-an tí ẹ̀rọ tí wọ́n bá gbé síbẹ̀ á máa lò láti máa jẹ́ kí ilé tutù nígbà ooru tàbí kó gbóná nígbà òtútù. Irú ètò yìí ò fi bẹ́ẹ̀ náni lówó, kì í sì í ba àyíká jẹ́.

August 7, 2015—Montgomery nílùú New York

Ibí làwọn tá à ń rajà lọ́wọ́ wọn máa ń já àwọn ohun èlò ìkọ́lé sí. Wọ́n á wá tò wọ́n pọ̀ sí bí wọ́n á ṣe lò wọ́n níbi ìkọ́lé ní Warwick.

August 14, 2015—Tuxedo Park nílùú New York

Méjì lára àwọn òṣìṣẹ́ ní Warwick (ẹni kejì àti ẹni kẹta láti apá ọ̀tún) ń bá ìdílé kan tó ń gbé ní Warwick jẹun. Ọ̀pọ̀ ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe bí ìdílé yìí, tí wọ́n gba àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ní Warwick sílé wọn.

August 17, 2015—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí

Òṣìṣẹ́ kan ń fi awò wo bí ojú ilẹ̀ ṣe rí.

August 20, 2015—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́

Wọ́n ti parí gbogbo fèrèsé tó wà ní ibi àbáwọlé táwọn àlejò tó bá wá ṣèbẹ̀wò máa dé sí.

August 26, 2015—Ọgbà Warwick

Láàárín oṣù May sí August, wọ́n parí gbígbé ògiri àti òrùlé sí Ilé Gbígbé B. Wọ́n ti parí gbogbo àwọn ilé gbígbé tó kù, Ilé Gbígbé B ni wọ́n ṣe kẹ́yìn. Wọ́n tún gbé gbogbo afárá tí wọ́n fi so àwọn ilé pọ̀ síbi tó yẹ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tún ojú ilẹ̀ ṣe.