Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ò Pa Àwọn Ẹran Igbó àti Àyíká Lára Nílùú Warwick

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ò Pa Àwọn Ẹran Igbó àti Àyíká Lára Nílùú Warwick

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ oríléeṣẹ́ wọn tuntun sí tòsí adágún odò Sterling Forest Lake (ìyẹn Blue Lake) ní ìgbèríko ìpínlẹ̀ New York. Kí ni wọ́n ń ṣe kí wọn má bàa pa àwọn ẹran igbó tó wà níbẹ̀ àti ibi tí wọ́n ń gbé lára?

Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ọgbà yí ká ibi tí wọ́n ti ń kọ́ ilé náà kí àwọn ejò àtàwọn ìjàpá lóríṣiríṣi má bàa wọ ibẹ̀, kí wọ́n má bàa pa wọ́n, àmọ́ wọ́n ní in lọ́kàn láti yọ ọgbà náà tí wọ́n bá ti kọ́lé tán. Wọ́n máa ń yẹ ọgbà náà wò déédéé kí wọ́n lè dí ọ̀nà èyíkéyìí táwọn ẹranko yẹn lè gbà wọlé síbi tí wọ́n ti ń kọ́lé, kó má bàa di pé wọ́n á há sínú ibẹ̀. Tí wọ́n bá ti kọ́ ilé náà tán, tí wọ́n sì yọ ọgbà náà, tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n rí ejò kankan ní tòsí ibẹ̀, ẹnì kan tó mọ̀ ọ́n mú máa mú un kúrò níbẹ̀ lọ sínú igbó láìní pa ejò náà lára.

Ẹyẹ eastern bluebird

Ìgbà òtútù ni wọ́n gé àwọn igi tó wà níbi ilé tí wọ́n ń kọ́ náà kí wọ́n má bàa ṣèdíwọ́ fáwọn ẹyẹ eastern bluebird nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ ìtẹ́ wọn. Táwọn Ẹlẹ́rìí bá ti kọ́lé tán, wọ́n máa gbé àwọn ìtẹ́ ẹyẹ tí wọ́n fi pákó ṣe kọ́ káàkiri káwọn ẹyẹ náà lè pa dà wálé.

Bákan náà, láàárín oṣù October sí March, wọ́n máa ń ro ilẹ̀ láwọn ibì kan, wọ́n sì ń gé igbó kí irúgbìn hyssop skullcap lè fọ́n káàkiri, kó sì lè hù dáadáa torí ewéko yẹn ò wọ́pọ̀ mọ́. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ látìgbàdégbà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì rí ewéko náà ládùúgbò ilé tí wọ́n ń kọ́ sí ìlú Warwick látọdún 2007.

Oríṣiríṣi pẹ́pẹ́yẹ tó ń jẹ́ waterfowl àti oríṣiríṣi ẹja ló wà níbi odò Sterling Forest Lake tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé táwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ yìí. Kí wọ́n má bàa pa àwọn ohun tó wà nínú adágún odò náà lára, wọ́n ṣe oríṣiríṣi nǹkan tí kò ní ba àyíká jẹ́. Lára ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n gbin koríko sórí àwọn òrùlé, ìyẹn máa sẹ́ àwọn ìdọ̀tí tó ń ba àyíká jẹ́ kúrò nínú omi òjò tó bá rọ̀, á sì dín omi táá máa ṣàn kiri kù. Ohun míì tí wọ́n tún ṣe ni pé wọn ò fọwọ́ kan àwọn ewéko tó wà létí odò náà, wọ́n sì ń bójú tó o.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí iṣẹ́ rẹ̀ ní Warwick jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ yìí sọ pé, “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tá à ń ṣe yìí máa gba àkókò àti ètò, a ti pinnu pé a ò ní pa àwọn ẹran igbó àti àyíká lára níbi tá à ń kọ́lé sí nílùú Warwick.”