Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 1 (January sí August 2015)

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 1 (January sí August 2015)

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kó kúrò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Mill Hill nílùú London lọ síbi tó jìn tó máìlì mẹ́tàlélógójì (43) sí ìlà oòrùn, ní tòsí ìlú Chelmsford, Essex. Láàárín oṣù January sí August 2015, àwọn òṣìṣẹ́ ṣètò àwọn ibi tí wọ́n á máa kó àwọn irinṣẹ́ sí kí iṣẹ́ lè bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

January 23, 2015—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ gbàṣẹ lọ́wọ́ ìjọba láti gé àwọn igi tó wà níbi tí wọ́n ti fẹ́ ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì palẹ̀ rẹ̀ mọ́ kí wọ́n lè ráyè ṣiṣẹ́. Wọ́n rí i dájú pé àwọn tètè parí iṣẹ́ yìí kó tó di àsìkò táwọn ẹyẹ máa ń kọ́lé sórí igi. Wọ́n fi àwọn èérún igi ṣe ọ̀nà táwọn èèyàn á máa gbà kọjá, wọ́n sì kó àwọn ẹ̀là gẹdú jọ fún iṣẹ́ tí wọn ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ yìí.

January 30, 2015—Iṣẹ́ ilé ìjẹun

Oníṣẹ́ iná kan ń ṣe ibi tí wọ́n á máa ki wáyà iná tẹlifíṣọ̀n bọ̀ ní ilé ìjẹun. Òtẹ́ẹ̀lì ni wọ́n ń fi ibí yìí ṣe tẹ́lẹ̀. Wọ́n ti wá sọ ọ́ di yàrá ìdáná àti ilé ìjẹun báyìí. Àwọn tẹlifíṣọ̀n yìí ni àwọn òṣìṣẹ́ á máa fi wo ìjọsìn òwúrọ̀ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì bá ń ṣe.

February 23, 2015—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń mọ fẹ́ǹsì tó máa yí èyí tó pọ̀ jù lára ibi ìkọ́lé náà ká. Torí pé ibẹ̀ ò tíì fi bẹ́ẹ̀ lajú, wọ́n gbìyànjú láti rí i pé wọn ò ṣèpalára fún àwọn ẹran igbó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n rọra fi àyè díẹ̀ sísàlẹ̀ fẹ́ǹsì tí wọ́n mọ kí àwọn ẹranko tó ń wá oúnjẹ lóru lè máa gba ibẹ̀ kọjá.

February 23, 2015—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Wọ́n ń ṣe ọ̀nà tí wọ́n á máa lò títí wọ́n á fi parí iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Ọ̀nà yìí ni wọ́n á máa gbà láti ilé gbígbé lọ sí ibi iṣẹ́ ìkọ́lé náà.

March 5, 2015—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Ọ̀nà tí wọ́n á máa lò títí wọ́n á fi parí iṣẹ́ ìkọ́lé náà là ń wò lápá ìlà oòrùn yìí. Lókè, lápá ọ̀tún, ọ̀nà yìí já sí ibi ìkọ́lé náà. Àwọn ilé tó wà nísàlẹ̀ lápá òsì ni wọ́n sọ di ilé táwọn òṣìṣẹ́ ń gbé. Wọ́n máa kọ́ ibùgbé kéékèèké sí ilẹ̀ gbalasa tó wà ní ẹ̀gbẹ́ yẹn.

April 20, 2015—Ibi táwọn òṣìṣẹ́ ń gbé

Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹlòmíì tó jẹ́ aṣojú oríléeṣẹ́ wa bẹ àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà wò. Ní ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, wọn ṣe àkànṣe ìpàdé kan tí wọ́n ta àtagbà rẹ̀ sí gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ireland. Wọ́n ṣèfilọ̀ pé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ni Ìgbìmọ̀ Ìlú Chelmsford fún wọn láṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

May 13, 2015—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣe irin tó máa dáàbò bo ìtàkùn igi, wọ́n gbé e sáàárín igi ńlá méjì. Ọ̀nà yìí ni wọ́n á máa gbà láti ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí lọ sí ibi tí wọ́n ti ń kọ́lé. Irin yìí á jẹ́ kí wọ́n lè máa gbé àwọn irinṣẹ́ tó wúwo kọjá láì jẹ́ pé wọ́n ṣèpalára fún ìtàkùn kankan.

May 21, 2015—Ibi táwọn òṣìṣẹ́ ń gbé

Àwọn tó ń fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀ ń gbẹ́ kòtò tí wọ́n máa gbé irinṣẹ́ gbà lọ sí ilé gbígbé tí wọ́n á lò fúngbà díẹ̀. Àwọn àádọ́ta (50) ilé tí wọ́n kọ́kọ́ kọ́ ló wà lẹ́yìn yẹn. Ibẹ̀ láwọn òṣìṣẹ́ tó ń kọ́lé á máa gbé.

June 16, 2015—Ibi táwọn òṣìṣẹ́ ń gbé

Oníṣẹ́ omi ẹ̀rọ kan ń ṣe páìpù omi sí ọ̀kan lára àwọn ilé tí wọ́n máa lò fúngbà díẹ̀.

June 16, 2015—Ibi táwọn òṣìṣẹ́ ń gbé

Téèyàn bá wò ó láti ìlà oòrùn, àwọn ibùgbé tí wọ́n máa lò fúngbà díẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ nìyẹn. Lápá iwájú, wọ́n ń fi ìpìlẹ̀ àwọn ilé gbígbé tí wọ́n fẹ́ kọ́ láfikún sí tilẹ̀ lélẹ̀. Àwọn ilé táwọn òṣìṣẹ́ tó ń gbé ibí á máa lò sí ló wà lápá òsì yẹn. Wọ́n ní ilé ìjẹun níbẹ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ tó ń kọ́lé. Ibi tí wọ́n máa kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí ló wà láàárín lọ́wọ́ ẹ̀yìn.

June 16, 2015—Ibi táwọn òṣìṣẹ́ ń gbé

Oníṣẹ́ ọwọ́ kan ń so wáyà méjì pọ̀ ní yàrà tí wọ́n ti ń ṣètò tẹlifóònù. Nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, wọ́n nílò kọ̀ǹpútà àti Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi ṣe gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìkọ́lé, láti kàn sí àwọn tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì míì, kí wọ́n sì tún lè máa gba ìtọ́ni láti oríléeṣẹ́.

July 6, 2015—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Agbaṣẹ́ṣe kan ń fi ẹ̀rọ GPS wo ibi tí wọ́n máa gbẹ́ kòtò sí. Àwọn kòtò yìí máa ran àwọn awalẹ̀pìtàn lọ́wọ́ láti ṣèwádìí nípa ilẹ̀ náà kó tó di pé iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ̀rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láyé àtijọ́, àwọn ará Róòmù ló ń gbé nílùú Chelmsford tó wà ní tòsí ibí yìí, a ò tíì rí nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé kankan nínú àwọn kòtò ọgọ́rùn-ún lé méje [107] tí wọ́n ti gbẹ́.

July 6, 2015—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Wọ́n ń gé férémù ìlẹ̀kùn sí ìwọ̀n tó máa gba ẹnu ọ̀nà. Wọ́n tún díẹ̀ lára àwọn ilé tó wà níbi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí ṣe kí wọ́n lè sọ ọ́ di ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Àwọn ọ́fíìsì tí wọ́n máa lò láàárín ìgbà ìkọ́lé yìí àtàwọn ibi tí wọ́n á ti máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì à tún wà níbí.

July 6, 2015—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Wọ́n ń fi ọkọ̀ kó yẹ̀pẹ̀ tí wọ́n á fi kún ilé.

July 7, 2015—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rèé téèyàn bá dúró sí apá gúúsù ibi tá a ti ń kọ́lé. Títì kan wà ní tòsí tá ò fi hàn nínú àwòrán yìí tó ṣe é gbà dé etíkun, pápákọ̀ òfuurufú àti ìlú London.

July 23, 2015—Ibi tá a fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí

Àwọn agbaṣẹ́ṣe ń wó àwọn ilé tó wà lórí ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, kí wọ́n lè ráyè kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun sí.

August 20, 2015—Ibi tí wọ́n ń kó irinṣẹ́ sí

Ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé nǹkan tó tóbi ń sọ apá kan lára àwọn ilé tó ṣeé tú palẹ̀ sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ lò ó.. Ní apá iwájú nínú àwòrán yìí la ti rí ìpìlẹ̀ tí wọ́n ṣe fún irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ṣì máa gbé síbẹ̀. Àwọn ilé yìí ni wọ́n á fi ṣe ọ́fíìsì àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé.