Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Wọ́n Kéde Ohun tí Bíbélì Sọ Nílùú Paris

Wọ́n Kéde Ohun tí Bíbélì Sọ Nílùú Paris

Ní November 30 sí December 12, 2015, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe ìpàdé àpérò kan nílùú Paris, nílẹ̀ Faransé lórí ọ̀rọ̀ ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà. Àwọn aṣojú láti orílẹ̀-èdè tó tó igba ó dín márùn-ún [195] ló wá síbi ìpàdé náà, wọ́n sì sọ̀rọ̀ lórí bí ohun táwọn èèyàn ń ṣe ò ṣe ní máa ba ojú ọjọ́ jẹ́. Àwọn èèyàn lóríṣiríṣi, títí kan àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, àwọn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká àtàwọn ọ̀gá oníṣòwò ló wá síbi ìpàdé náà, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì [38,000]. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn míì lọ síbì kan ní tòsí ibẹ̀ tí wọ́n ti lè rí ìsọfúnni púpọ̀ nípa ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lọ síbi ìpàdé yẹn, ọ̀rọ̀ àyíká jẹ àwọn náà lógún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló ṣe ìwàásù àkànṣe kan tí wọ́n ṣe nílùú Paris, wọ́n kéde ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pé Bíbélì sọ nípa ìgbà tí àwọn èèyàn ò ní ṣe ohun tó ń ba àyíká jẹ́ mọ́.

Nígbà tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà nínú ọkọ̀ èrò, ó bá ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Peru sọ̀rọ̀, aṣọ ìbílẹ̀ ilẹ̀ Peru ni ọkùnrin náà wọ̀. Ọkùnrin náà sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun nílera tó dáa, òun sì ń gbádùn orí òkè tó rẹwà tóun ń gbé, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ayé wa yìí lọ́jọ́ iwájú ṣì ń kọ òun lóminú. Ọ̀rọ̀ tí Ẹlẹ́rìí yẹn bá a sọ nípa ọjọ́ iwájú wọ̀ ọ́ lọ́kàn, tẹ̀rín-tẹ̀rín ló sì gba káàdì pélébé tí Ẹlẹ́rìí náà fún un tó fi darí rẹ̀ sí ìkànnì wa, www.jw.org.

Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì míì bá ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká sọ̀rọ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin. Ó yà á lẹ́nu nígbà tó gbọ́ pé ẹ̀ẹ̀mejì ni iléeṣẹ́ Green Building Initiative ti fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin, torí bá a ṣe kọ́ ilé wa tuntun méjì láìba àyíká jẹ́ tàbí ká máa ṣe ohun tó ń ba àyíká jẹ́ níbẹ̀. Wallkill nílùú New York làwọn ilé yìí wà, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sì ń lò ó. Tayọ̀tayọ̀ ni ọkùnrin yìí náà gba káàdì tó darí rẹ̀ sí ìkànnì wa.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé àwọn máa lọ wo ìkànnì wa torí pé ó wú wọn lórí báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àyíká jẹ wá lógún gan-an. Nígbà tí obìnrin kan tó jẹ́ aṣojú láti orílẹ̀-èdè Kánádà gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò débi tí ẹyẹ eastern bluebird máa ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí nígbà tí wọ́n ń kọ́ oríléeṣẹ́ wọn tuntun tó wà ní Warwick, nílùú New York, obìnrin náà sọ pé: “Onímọ̀ nípa àwọn ẹyẹ ni mí kó tó di pé mo di òṣìṣẹ́ tó ń rí sí àyíká. Mi ò mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka àwọn ẹranko sí pàtàkì tó báyìí o. Màá ka àwọn ìwé yín, màá sì lọ sórí ìkànnì yín kí n lè mọ̀ sí i nípa yín!”