Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Wọ́n Rìn Gba Àárín Òkun Kọjá Láti Lọ Wàásù

Wọ́n Rìn Gba Àárín Òkun Kọjá Láti Lọ Wàásù

Àwọn èèyàn tí iye wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ló ń gbé ní erékùṣù Halligen tó wà níbi òkun àríwá tó wà nítòsí etíkun ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Schleswig-Holstein lórílẹ̀-èdè Jámánì. Kí ló máa ń ná àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti lè lọ wàásù fún àwọn tó ń gbé ní erékùṣù yìí?Mátíù 24:14.

Àwa ẹlẹ́rìí máa ń wọ ọkọ̀ ojú omi kékeré tá a bá fẹ́ lọ wàásù láwọn erékùṣù kan níbẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀ tá a bá ń lọ sáwọn erékùṣù míì, ó máa ń gbà pé káwọn àwùjọ kékeré kan fẹsẹ̀ rin ìrìn kìlómítà márùn-ún gba àárín òkun kọjá. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é?

Wọ́n Ń Lo Àǹfààní Ìgbì Òkun

Ìgbì òkun ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní abúlé yìí, láàárín wákàtí mẹ́fà òkun yìí fi nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà kún sí i tàbí fà sí i! Nígbà tí ìgbì òkun yẹn bá lọ sílẹ̀, a máa ń fẹsẹ̀ lọ wàásù láwọn erékùṣù mẹ́ta torí èyí tó pọ̀ jù lára ibi tí omi òkun yẹn kún dé ló ti máa gbẹ.

Báwo ni ìrìn àjò yìí ṣé máa ń rí? Ulrich tó nírìírí nípa ìrìn àjò tó sì tún ṣáájú àwọn tó lọ síbẹ̀ sọ pé: “A máa ń rin ìrìn wákàtí méjì ká tó dé erékùṣù kan. Lọ́pọ̀ ìgbà ẹsẹ̀ lásán la máa fi ń rìn. Ọ̀nà tó rọrùn jù lọ tá a fi lè gba àárín òkun náà kọjá nìyẹn. Láwọn àsìkò òtútù ṣe la máa ń wọ àwọn bàtà tó gùn dé orúnkún.”

Ulrich tún sọ pé: Ọ̀rọ̀ náà máa ń dà bí nǹkan nígbà míì torí ṣe ló máa ń dà bí pé inú ayé míì la ti ń rìn. Ẹrẹ̀ máa pọ̀ láwọn ibì kan, àwọn ibòmíì sì rèé àpáta ni, nígbà tó sì tún jẹ́ pé àwọn ewéko òkun ló máa bo àwọn ibòmíì mọ́lẹ̀. Ẹ máa rí àwọn ẹyẹ etíkun tó pọ̀, alákàn, àtàwọn ẹranko míì.” Àwùjọ yìí tún máa gba ibi omi kan tí wọ́n ń pè ní Priele lédè Jámánì kọjá.

Kì í rọrùn fáwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn. Ulrich kìlọ̀ pé: “Ó rọrùn láti sọnù, pàápàá tí kùrukùru bá bo ojú ọjọ́. Torí náà, a máa ń lo kọ́ńpáàsì àti ẹ̀rọ GPS tó máa ń júwe ọ̀nà láti fi rìnrìn àjò, a sì tún máa ń fọwọ́ pàtàkì mú ètò tá a ṣe ká má bá à kó sí páńpẹ́ ìgbì òkun tó ń ru bọ̀.”

Wọ́n wàásù ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Halligen

Ṣé ó yẹ kí wàhálà yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ulrich sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó sábà máa ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó sì tún ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, ó sọ pé torí pé ọjọ́ ti ń lọ, àwọn ò ráyè dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin yìí, ni ọkùnrin náà bá gbé kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì lé àwọn bá, ó wá sọ pé: ‘Ṣé ẹ ò ní fún mi ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ mi ni?’ Inú wa dùn láti fún-un.”