Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Sinti àti Roma ló ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì. * Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe àwọn ìwé lóríṣiríṣi tó dá lórí Bíbélì, bí ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn fídíò jáde lédè Romany, ìyẹn èdè ìbílẹ̀ táwọn èèyàn yìí ń sọ. *

Lóṣù September àti October ọdún 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àkànṣe ìwàásù, wọ́n sì sapá láti fi àwọn ìtẹ̀jáde àti fídíò tó wà lédè Romany yìí han àwọn Sinti àtàwọn Roma tó ń gbé lóríṣiríṣi ìlú lórílẹ̀-èdè Jámánì, àwọn ìlú bíi Berlin, Bremerhaven, Freiburg, Hamburg àti Heidelberg. Wọ́n tún ṣètò láti ṣèpàdé lédè Romany láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn.

Àbájáde Rẹ̀ Wúni Lórí Gan-an

Ẹnu ya ọ̀pọ̀ àwọn Sinti àtàwọn Roma nígbà tí wọ́n rí ètò táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe láti wàásù fún wọn, inú wọn sì dùn kọjá sísọ. Andre àti Esther, tọkọtaya kan tó lọ́wọ́ sí àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù náà, sọ pé: “Inú àwọn èèyàn dùn gan-an torí pé a ṣètò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ká lè kàn sí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì lédè àbínibí wọn, tí wọ́n sì kà á fúnra wọn, ó wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lédè Romany. Ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tó ń wò ó. Léraléra ló ń sọ pé, “Èdè mi ni wọ́n ń sọ yìí!”

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Matthias, tó kọ́wọ́ ti àkànṣe ìwàásù náà nílùú Hamburg sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́jọ tó lọ wàásù níbì kan táwọn Sinti àti Roma tó tó irínwó [400] ń gbé. Gbogbo àwọn tá a bá sọ̀rọ̀ ló ní ká fún àwọn ní ìwé.” Bettina, tóun náà yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti wàásù ní Hamburg, fi kún un pé: “Ṣe ni omijé ń bọ́ lójú àwọn kan nígbà tí wọ́n rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ìwé jáde lédè Romany.” Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé náà sókè lójú ẹsẹ̀, kódà àwọn míì gba ìwé sí i kí wọ́n lè fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn.

Àwọn Sinti àti Roma mélòó kan gbà láti wá sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Nílùú Hamburg, àwọn mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [94] ló wá sípàdé. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni ò wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba rí. Nílùú Reilingen, nítòsí ìlú Heidelberg, àwọn ọgọ́fà ó lé mẹ́ta [123] ló wá sípàdé. Lẹ́yìn ìpàdé náà, àwọn márùn-ún tó ń sọ èdè Romany ló ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Nígbà àkànṣe ìwàásù yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pín ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé pẹlẹbẹ tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000]. Àwọn Sinti àti Roma tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta [360] làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sọ̀rọ̀, àwọn mọ́kàndínlógún [19] ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ nínú wọn sọ pé, “Inú wa dùn gan-an pé Ọlọ́run ò gbàgbé wa.”

^ ìpínrọ̀ 2 Àwùjọ èèyàn kékeré kan làwọn Sinti, Ìwọ̀ Oòrùn àti Àárín Gbùngbùn ilẹ̀ Yúróòpù ni wọ́n ń gbé. Àwùjọ èèyàn kékeré kan làwọn Roma náà, Ìlà Oòrùn àti Gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù ni wọ́n ti wá.

^ ìpínrọ̀ 2 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica lórí ìkànnì sọ pé “ọgọ́ta [60] èdè ìbílẹ̀ lóríṣiríṣi tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ” ló wà nínú àwọn èdè Romany. Àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, “Romany” la máa pè èdè táwọn Sinti àtàwọn Roma tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì ń sọ.