Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Wọ́n Pàtẹ Ìṣúra Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ ní Botswana

Wọ́n Pàtẹ Ìṣúra Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ ní Botswana

Orílẹ̀-èdè Botswana làwọn awakùsà ti máa ń wa dáyámọ́ńdì jù. Àmọ́ ní August 22 to 28, 2016, ìṣúra tó ṣàrà ọ̀tọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà pàtẹ síbi ìpàtẹ ọjà Botswana Consumer Fair. Ara ohun tí wọ́n pàtẹ ni àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, ìkànnì jw.org, àtàwọn fídíò tó ń ran ìdílé lọ́wọ́ kí àjọṣe àárín wọn lè lágbára.

Fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà gbàfiyèsí àwọn òbí àtàwọn ọmọ tó lọ síbi táwọn Ẹlẹ́rìí pàtẹ sí. Ọ̀wọ́ àwọn fídíò yìí máa ń jẹ́ kéèyàn rí béèyàn ṣe lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Torí pé fídíò bèbí ò pọ̀ lédè Setswana, ìyẹn èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Botswana, ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbi ìpàtẹ náà ló béèrè bí wọ́n ṣe lè rí àwọn fídíò yẹn gbà.

Ìwé tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] làwọn tó wá síbi ìpàtẹ náà látibi gbogbo lórílẹ̀-èdè náà gbà, ọgọ́fà [120] èèyàn ló sì ní kí wọ́n wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Ó wú ọ̀pọ̀ èèyàn lórí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Setswana jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ níbi ìpàtẹ náà.

Nígbà tí àwọn alábòójútó ìpàtẹ ọjà náà wo gbogbo ohun táwọn èèyàn wá pàtẹ síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n fún lẹ́bùn pé wọ́n gba ipò kìíní.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÀWỌN WO LÓ Ń ṢE ÌFẸ́ JÈHÓFÀ LÓDE ÒNÍ?

What Can Be Found on Our Web Site?

O lè mọ púpọ̀ sí i nípa wa àtohun tá a gbà gbọ́, wàá sì tún rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ̀ nípa Bíbélì.

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀?

Jèhófà, Ọlọ́run aláyọ̀ fẹ́ kí ìdílé láyọ̀. Ká nípa àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó lè mú kí ọkọ, aya, òbí àtàwọn ọmọ ṣe ojúṣe wọn.