Ó lé ní ọgọ́ta [60] èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Kánádà, ọ̀kan nínú àwọn èdè yìí sì ní èdè ìbílẹ̀ tí àwọn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mẹ́tàlá [213,000] tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Kánádà ń sọ.

Kí iṣẹ́ ìwàásù lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tó wà ní ìgbèríko yìí, ọ̀pọ̀ lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ ọ̀kan nínú àwọn èdè yìí. Nígbà tó fi máa di ìparí ọdún 2015, ó lé ní àádọ́ta-lérúgba [250] àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti yege nínú kíkọ́ àwọn èdè ìbílẹ̀ yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣètò kíláàsì yìí.

Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tú àwọn ìtẹ̀jáde tó ṣàlàyé Bíbélì, tó fi mọ́ àwọn fídíò kéékèèké, sí mẹ́jọ lára àwọn èdè ìbílẹ̀ Kánádà, àwọn èdè bíi: Algonquin, Blackfoot, Plains Cree, West Swampy Cree, Inuktitut, Mohawk, Odawa àti Northern Ojibwa. *

Àwọn tó kọ́ àwọn èdè ìbílẹ̀ yìí sọ pé ó lè má rọrùn. Carma sọ pé: “Ní ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí i ran àwọn atúmọ̀ èdè Blackfoot lọ́wọ́, ńṣe ló ń ṣe mí bí i pé wọ́n fi nǹkan bò mí lójú tí mo sì ń ṣiṣẹ́. Mi ò mọ èdè náà dáadáa. Mi ò lè kà á, mi ò sì mọ ìró ohùn rẹ̀.”

Terence tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn atúmọ̀ èdè West Swampy Cree sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ kan gùn, ó sì ṣòro láti pè.” Daniel, òjíṣẹ́ tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù ní ìlú Manitoulin Island, Ontario, sọ pé: “Kò sí ìwé tàbí ìwé atúmọ̀ èdè téèyàn lè fi kọ́ èdè náà. Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà kọ́ èdè Odawa ní pé kó o wá ọ̀kan lára àwọn àgbàlagbà tó wà ládùúgbò náà, tó mọ èdè náà dáadáa pé kó kọ́ ọ.”

Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ kára báyìí? Obìnrin kan tó ń sọ èdè Ojibwa gbóríyìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé iṣẹ́ àṣekára wa ló jẹ́ ká dá yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn míì. Ó sọ pé bí a ṣe ń lọ sí ilé àwọn èèyàn tá a sì ń ka Ìwé Mímọ́ fún wọn lédè Ojibwa, kó máa wu wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bert, atúmọ̀ èdè kan tó dàgbà sí àgbègbè Tribe reserve ní Alberta, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn Blackfoot tí mo máa ń rí á dì mọ́ ìtẹ̀jáde wa, wọ́n á wá sọ pé ‘Èdè mi rèé. Tèmi ni!’ Mo máa ń rí i tí omijé máa ń lé ròrò sójú wọn tí wọ́n bá ń wo fídíò tá a ṣe lédè wọn.”

Inú obìnrin kan tó sọ èdè Cree dùn gan-an sí fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? tó wà lédè ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé ṣe ló dà bí pé ìyá òun ló ń bá òun sọ̀rọ̀.

Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Ribiribi

Ọ̀pọ̀ nínú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń sa gbogbo ipá wa láti rí i pé ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì dé ọ̀dọ̀ àwọn tó wà ní ìgbèríko. Terence àti ìyàwó rẹ̀, Orlean, rántí ìgbà kan tí wọ́n rin irú ìrìn àjò yìí. Wọ́n sọ pé: “A wà lára àwọn tó rin ìrìn àjò fún wákàtí méjìlá lórí yìnyín, ká lè lọ wàásù fún àwọn tó wà ní àgbègbè Little Grand Rapids. Inú wa dùn gan-an sí bí àwọn èèyàn ibẹ̀ ṣe dáhùn pa dà!”

Àwọn kan ti sí kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì kó lọ sí tòsí àwọn ìlú yìí. Daniel àti ìyàwó rẹ̀ LeeAnn gbádùn ìṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ṣe fún oṣù mẹ́ta ní Manitoulin Island, bí wọ́n ṣe pinnu pé àwọn á sí lọ síbẹ̀ nìyẹn. Daniel sọ pé: “A wá ní ọ̀pọ̀ àkókò láti wàásù ká sì tún máa ṣe ìpadàbẹ̀wò.”

“Nítorí Mo Kanlẹ̀ Nífẹ̀ẹ́ Wọn”

Kí nìdí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń sa gbogbo ipá wọn láti wàásù fún àwọn tó wà ní ìgbèríko? Rose ìyàwó Bert, sọ pé: “Torí mo jẹ́ ọmọ ìlú náà, mo sì tún mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa pa àwọn ìlànà Bíbélì mọ́, ìdí nìyí tí mo fi fẹ́ ràn àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ káwọn náà lè mọ̀ ọ́.”

Orlean sọ pé “Mo fẹ́ kí Ẹlẹ́dàá wa máa darí àwọn ará Cree. Àǹfààní ńlá ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì borí àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní.”

Marc ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń túmọ̀ èdè Blackfoot. Kí ló dé tó fi fẹ́ ran àwọn tó wà ní ìgbèríko tó wà làgbègbè rẹ̀ lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Ìdí ni pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn.”

^ ìpínrọ̀ 4 Àwọn tó wà ní ìgbèríko orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà máa ń sọ ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí.