Ìwádìí kan fi hàn pé mílíọ̀nù kan ààbọ̀ ni àwọn tó ń rìnrìn àjò lórí òkun káàkiri ayé. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bá sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé léraléra ni àwọn awakọ̀ òkun máa ń rìnrìn àjò láti ibùdókọ̀ òkun kan lọ síbòmíì? Tí ọkọ̀ òkun kan bá ti gúnlẹ̀ sí ibùdókọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ máa ń wọlé síbẹ̀, wọ́n á kọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òkun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè tí wọ́n bá fẹ́, wọ́n á sì fún wọn láwọn ìtẹ̀jáde wa.

Kí ló ti tẹ̀yìn ohun tí wọ́n ń ṣe yìí yọ? Stefano, Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti wàásù ní ibùdókọ̀ òkun tó wà nílùú Vancouver lórílẹ̀-èdè Kánádà, ṣàlàyé pé: “Àwọn kan máa ń rò pé ọ̀dájú ni gbogbo awakọ̀ òkun, tí wọn kì í sì í ka èèyàn sí. Àwọn kan lè rí bẹ́ẹ̀ nínú wọn lóòótọ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń rìnrìn àjò lórí òkun tá a máa ń rí ló lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó sì máa ń yá wọn lára láti kẹ́kọ̀ọ́.” Stefano fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló gba Ọlọ́run gbọ́, tí wọ́n sì fẹ́ kó bù kún àwọn, torí náà, wọ́n máa ń gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” Láàárín September 2015 sí August 2016, nílùú Vancouver nìkan, ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] ìgbà tí wọ́n gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá wàásù nínú ọkọ̀ òkun! Àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀jáde lóríṣiríṣi èdè, ó sì lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún kan [1,100] lára wọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Báwo ni àwọn tó ń rìnrìn àjò lórí òkun ṣe máa ń bá ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì lọ tí wọ́n bá gbéra lọ síbòmíì?

Torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wà láwọn ibùdókọ̀ òkun káàkiri ayé, awakọ̀ òkun tó bá ṣì fẹ́ kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí pàdé òun ní ibùdókọ̀ míì tí òun ti máa dúró. Bí àpẹẹrẹ, ní May 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Vancouver pàdé ẹnì kan tó ń jẹ́ Warlito, ọ̀gá alásè ni nínú ọkọ̀ òkun kan tí wọ́n fi ń kẹ́rù. Wọ́n fi fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? hàn án, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí wọ́n kọ́ Warlito dùn mọ́ ọn, kò sì fẹ́ dá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dúró, àmọ́ ó di ìlú Paranaguá lórílẹ̀-èdè Brazil kí ọkọ̀ òkun tó ti ń ṣiṣẹ́ tó tún dúró, ibẹ̀ sì jìnnà gan-an.

Lẹ́yìn oṣù kan ó lé, nígbà tí ọkọ̀ òkun náà gúnlẹ̀ sí Paranaguá, ó ya Warlito lẹ́nu gan-an nígbà tó rí i tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil wá a wá síbi ẹnu ọ̀nà ọkọ̀ òkun náà, tí wọ́n láwọn ń béèrè ẹ̀, wọ́n tiẹ̀ tún dárúkọ ẹ̀! Wọ́n ní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Vancouver ti fi tó àwọn létí pé ó máa fẹ́ káwọn wá kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú Warlito dùn gan-an láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil yìí, ó sì sọ pé òun mọyì ètò tí wọ́n ṣe gan-an kí wọ́n lè kàn sí òun. Tayọ̀tayọ̀ ló gbà pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi tí ọkọ̀ òkun àwọn bá tún gúnlẹ̀ sí.