Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ojú Ìwé Rẹ̀ Ò Pọ̀, Ó sì Wà ní Ọ̀pọ̀ Èdè

Ojú Ìwé Rẹ̀ Ò Pọ̀, Ó sì Wà ní Ọ̀pọ̀ Èdè

Bẹ̀rẹ̀ láti January 2013, a máa dín ojú ìwé àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń fi sóde àti Jí! kù láti ojú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n [32] tó wà tẹ́lẹ̀ sí ojú ìwé mẹ́rìndínlógún [16].

Torí pé àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà kò ní pọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, èyí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè láti máa túmọ̀ wọn sáwọn èdè púpọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, èdè mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] la tú ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! ti December 2012 sí, a sì tú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ December 2012 sí igba ó dín márùn-ún [195] èdè. Àmọ́, nígbà tó fi máa di January 2013, èdè méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] la tú ìwé ìròyìn Jí! sí tá a sì tú Ilé Ìṣọ́ sí igba ó lé mẹ́rin [204] èdè.

Ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò ṣì máa wà ní ojú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n [32].

Ojú Ìwé ti Orí Bébà Máa Kéré, ti Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì sì Máa Pọ̀ Sí I

Ọ̀nà méjì ni àyípadà tó bá àwọn ìwé ìròyìn tí a ó máa tẹ̀ sórí bébà á gbà ní ipa lórí ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.jw.org/yo.

  1. Ní báyìí, orí Íńtánẹ́ẹ̀tì nìkan la ó ti máa rí àwọn àpilẹ̀kọ kan tí a máa ń tẹ̀ sórí bébà tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àpilẹ̀kọ bí “Abala Àwọn Ọ̀dọ́,” “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” àti ìròyìn nípa ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó máa ń wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá máa ń fi sóde, títí kan “Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé” àti “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” tó máa ń wà nínú Jí! la ó máa gbé jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nìkan báyìí.

  2. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! á tún máa wà ní ẹ̀dà tó máa ń ṣí lórí ẹ̀rọ. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá la ti máa ń gbé Ilé Ìṣọ́ àti jáde sórí ìkànnì www.jw.org/yo ní ẹ̀dà PDF. Ní báyìí, ẹ ó máa rí àwọn ìwé ìròyìn yìí kà ní ẹ̀dà HTML, èyí á jẹ́ kó rọrùn fún wa láti ṣí i ká sì kà á lórí kọ̀ǹpútà tàbí ẹ̀rọ alágbèéká. Ẹ ó sì tún lè rí àwọn ìtẹ̀jáde wa míì kà pẹ̀lú ìrọ̀rùn lórí ìkànnì ní nǹkan bí irínwó [400] èdè.