“Kì í súni, ó ń jẹ́ kéèyàn ronú jinlẹ̀, ó gbádùn mọ́ni.”

“Ó máa ń jẹ́ kí Bíbélì wu èèyàn láti kà.”

“Ó ń wọni lọ́kàn! Ó ń jẹ́ kí àwọn ìtàn inú Bíbélì ní ìtumọ̀ sí mi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

Èyí kàn jẹ́ díẹ̀ lára ohun tí àwọn tó gbọ́ àtẹ́tísí ìwé Mátíù sọ. Ìwé Mátíù tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ yìí wà lórí ìkànnì jw.org lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Ọdún 1978 ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀, èyí tá a ṣe lọ́dún yẹn ni àkọ́kọ́ irú ẹ̀. Nígbà tó yá, a gbé àtẹ́tísí ẹ̀dà Bíbélì yìí jáde ní apá kan tàbí lódindi ní ogún [20] èdè.

Nígbà tá a mú ẹ̀dà Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde ní ọdún 2013, a rí i pé ó yẹ ká gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́, bí a ṣe máa gba ohùn Bíbélì tá a tún ṣe yìí sílẹ̀ máa yàtọ̀ sí bí a ṣe ṣe ti tẹ́lẹ̀. Ẹni mẹ́ta péré ló ka Bíbélì tá a kọ́kọ́ gbohùn rẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ ó ju ẹgbẹ̀rún kan [1,000] èèyàn tí ohùn wọn yàtọ̀ síra tó máa ka ẹ̀dà Bíbélì tuntun yìí.

Bí a ṣe lo onírúurú ohùn nínú àtẹ́tísí ẹ̀dà Bíbélì tuntun yìí á jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ ọ lè máa fi ojú inú wo bí àwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe ṣẹlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ṣe àtẹ́tísí Bíbélì yìí bí ẹni ṣe eré ìtàn, èyí tó máa ń ní ohùn orin àti àwọn ìró kan tó ń dún lábẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ó máa jẹ́ kó dà bíi pé ohun tí ò ń gbọ́ ń ṣẹlẹ̀ níṣojú rẹ.

Iṣẹ́ tó bá ti ní ọ̀pọ̀ èèyàn nínú bí èyí gba ètò tó mọ́yán lórí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a máa fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ibi tá a fẹ́ kà dáadáa láti mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀, ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a máa pinnu ohùn ẹni tá a máa lò tó bá jẹ́ pé àpọ́sítélì kan tí wọn ò dárúkọ rẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ la fẹ́ gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Tí ẹni tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ bá sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó ń ṣiyèméjì, a lè yàn án fún Tọ́másì. Tí ọ̀rọ̀ ẹni náà bá sì fi hàn pé ó bẹ gan-an, a lè yàn án fún Pétérù.

A tún máa ń wo ọjọ́ orí ẹni tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ láti pinnu irú ohùn tí a máa lò fún un. Ohùn ọ̀dọ́kùnrin la máa lò fún àpọ́sítélì Jòhánù nígbà tó wà ní ọ̀dọ́, a sì máa lo ohùn àgbàlagbà fún àpọ́sítélì Jòhánù nígbà tó dàgbà.

Ní àfikún sí i, a máa wá àwọn tó mọ ìwé kà dáadáa. Àwọn tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló pọ̀ jù lára àwọn tó wá bá wa kàwé. A ṣe ìdánrawò fún àwọn tá a fẹ́ lò, ńṣe la yan àyọkà látinú ìwé ìròyìn Jí! fún wọn ṣáájú láti fi gbára dì. Wọ́n tún ka àwọn apá kan nínú Bíbélì níbi tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ti wáyé, tó sì fi bí nǹkan ṣe rí lára wọn hàn irú bí ìbínú, ìbànújẹ́, ìdùnnú tàbí ìjákulẹ̀. Ìdánrawò yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ bí àwọn òǹkàwé yìí ṣe mọ ìwé kà tó, ká sì lè pinnu apá ibí tí wọ́n ti lè ṣe dáadáa.

Tí wọ́n bá ti yan ibi tí àwọn òǹkàwé máa kà fún wọn, wọ́n á lọ sí ọkàn lára àwọn ilé ìgbohùnsílẹ̀ wa tó wà ní Brooklyn tàbí Patterson, ibẹ̀ ni wọ́n á ti ka apá tí wọ́n yàn fún wọn tí wọ́n á sì gba ohùn wọn sílẹ̀. Akọ́nimọ̀ọ́kà kan wà nílé ìgbohùnsílẹ̀ tó máa ríi dájú pé òǹkàwé náà lo ohùn tó yẹ. Akọ́nimọ̀ọ́kà àti òǹkàwé máa lo ìwé kan tá a dìídì ìtọ́ni sí nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n bójú iṣẹ́ yìí tó fi mọ́ ìtọ́ni nípa ibi tí òǹkàwé á ti dánu dúró àti bó ṣe máa tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tó bá ń kàwé. Akọ́nimọ̀ọ́kà tún máa lo àtẹ́tísí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a kọ́kọ́ ṣe kó lè mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe.

Tí wọ́n bá ti gba ohùn sílẹ̀ tán, wọ́n á wá fi ẹ̀rọ ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ sí i. Kí ohùn tí wọ́n gbà sílẹ̀ lè rí bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí, àwọn amojú ẹ̀rọ á fi ẹ̀rọ so àwọn ohùn tí wọ́n tí gbà sílẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ pọ̀ kó lè di odindi àtẹ́tísí.

A ò mọ bó ṣe máa pẹ́ tó láti parí ṣíṣe àtẹ́tísí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe lọ́dún 2013 lédè Gẹ̀ẹ́sì tá a dáwọ́ lé yìí. Àmọ́, bí a bá ṣe ń parí ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan ni a ó máa gbé e sórí ìkànnì jw.org. Wàá rí àmì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ orúkọ ìwé Bíbélì tá a bá ti parí tó máa fi hàn pé àtẹ́tísí ni, ibi tá a pè ní “Books of the Bible,” ìyẹn àwọn ìwé Bíbélì ló wà.