Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ka Sáyẹ́ǹsì Sí?

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ka Sáyẹ́ǹsì Sí?

A kì í fọwọ́ rọ́ ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe sẹ́yìn, a sì máa ń fara mọ́ àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe tí wọ́n bá fi ẹ̀rí tì í.

Ìwé atúmọ̀ èdè tó ń jẹ́ Collins Cobuild Advanced Learner’s English Dictionary sọ pé: “Sáyẹ́ǹsì dá lórí ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tó wà láyìíká, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn nǹkan yìí.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì, Bíbélì sọ ohun tó lè mú káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun ẹlẹ́mìí tó wà láyé, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwádìí táwọn míì ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ sáyẹ́ǹsì. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí:

  • Àgbáálá ayé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn.”​—Aísáyà 40:26.

  • Àwọn ohun ẹlẹ́mìí: Sólómọ́nì máa ń “sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi, láti orí kédárì tí ó wà ní Lẹ́bánónì dórí hísópù tí ń jáde wá lára ògiri; òun a sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko àti nípa àwọn ẹ̀dá tí ń fò àti nípa àwọn ohun tí ń rìn ká àti nípa àwọn ẹja.”​—1 Àwọn Ọba 4:​33.

  • Ìmọ̀ ìṣègùn: “Àwọn tí ó lera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.”​—Lúùkù 5:​31.

  • Ojú ọjọ́: “Ìwọ ha ti wọ àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti ìrì dídì, tàbí ìwọ ha rí àní àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti yìnyín . . . ? Ibo wá ni . . . ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn sì gbà ń tú káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?”​—Jóòbù 38:22-​24.

A kì í fojú kéré ọ̀rọ̀ sáyẹ́ǹsì, kódà àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí sáyẹ́ǹsì àtàwọn ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe máa ń jáde nínú àwọn ìwé wa. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rán ọmọ wọn níléèwé kí wọ́n lè lọ kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè túbọ̀ mọ ohun tó ń lọ láyìíká wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kan, bí àwọn tó ń ṣèwádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ohun alààyè, àwọn tó ń fi ìṣirò ṣèwádìí àtàwọn onímọ̀ ẹ̀rọ.

Àwọn ohun tí sáyẹ́ǹsì ò lè ṣàlàyé

A ò gbà pé sáyẹ́ǹsì lè dáhùn gbogbo ìbéèrè tí aráyé ń wá ìdáhùn sí. * Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ṣèwádìí nípa ohun tó wà nínú ilẹ̀ ṣàlàyé ohun tó para pọ̀ di ayé, àwọn tó sì ń ṣèwádìí nípa àwa èèyàn máa ń sọ ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́. Àmọ́ kí nìdí tó fi jẹ́ pé ayé yìí náà ló dùn ún gbé, nìdí tí àwọn ẹ̀yà ara wa fi máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀?

Ibi tá a parí èrò sí ni pé Bíbélì nìkan ló lè jẹ́ ká rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè yìí. (Sáàmù 139:13-​16; Aísáyà 45:18) Torí náà, a gbà pé kò burú kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa sáyẹ́ǹsì, àmọ́ ó dáa kó tún kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì.

Nígbà míì, ó máa ń dà bíi pé sáyẹ́ǹsì àti Bíbélì ta kora. Àmọ́ torí pé àwọn kan ṣi ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lóye ló jẹ́ kó dà bíi pé àwọn ohun kan ta kora. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ò fi kọ́ wa pé ọjọ́ mẹ́fà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ní wákátì mẹ́rìnlélógún [24] ni Ọlọ́run fi dá ayé.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:1; 2:4.

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé òótọ́ làwọn ohun kan táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ, àmọ́ kò sí ẹ̀rí gidi tó tì í lẹ́yìn, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì míì táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún láwùjọ náà ò sì fara mọ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn míì ló ti wá gbà pé àwọn ohun ẹlẹ́mìí ò ṣàdédé wà torí pé àwọn ohun tá à ń rí láyìíká wa fi hàn pé ẹnì kan tó gbọ́n ló dá wọn lọ́nà àrà. Àwa náà sì gbà pẹ̀lú wọn.

^ ìpínrọ̀ 10 Erwin Schrödinger, ọmọ ilẹ̀ Austria tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ, tó sì tún gba àmì ẹ̀yẹ Nobel sọ pé sáyẹ́ǹsì “ò sọ nǹkan kan rárá nípa gbogbo ohun . . . tó ń jẹ wá lọ́kàn, tó sì ṣe pàtàkì sí wa gan-an.” Albert Einstein náà sọ pé: “Ojú wa ti rí màbo láyé yìí, ìyẹn sì ti jẹ́ ká mọ̀ pé èrò orí nìkan ò tó láti bá wa yanjú ìṣòro tá à ń ní nígbèésí ayé.”