Rárá. Kristẹni ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ a kì í ṣe ara àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Kí nìdí?

Àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ni “àjọ àwọn ẹlẹ́sìn kan tí wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Kátólíìkì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fara mọ́ ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì fi ń kọ́ni, síbẹ̀ a kì í ṣe ara àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì torí àwọn ìdí yìí:

  1. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ló ta ko ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kọ́ wa pé “Ọlọ́run kan ni ó wà” kì í ṣe Mẹ́talọ́kan. (1 Tímótì 2:5; Jòhánù 14:28) Bákan náà, Bíbélì fi hàn kedere pé ìparun títí láé ló wà fún àwọn aṣebi kì í ṣe inú iná ọ̀run àpáàdì ni wọ́n ń lọ.Sáàmù 37:9; 2 Tẹsalóníkà 1:9.

  2. A kì í ṣe ìwọ́de lòdì sí ẹ̀sìn Kátólíìkì tàbí àwọn ẹlẹ́sìn míì, a kì í sì fẹ́ ṣàtúnṣe sí wọn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ńṣe la máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere náà. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ohun tí a fẹ́ ni pé kí a kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí í ṣe Bíbélì, kì í ṣe láti ṣàtúnṣe sí ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn míì fi ń kọ́ni.Kólósè 1:9, 10; 2 Tímótì 2:24, 25.