Èyí tó pọ̀ jù nínú owó tí a fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ nípasẹ̀ ọrẹ àtinúwá tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń mú wá. A kì í gba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láwọn ìpàdé wa, a kì í sì í gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ará ìjọ. (Mátíù 10:7, 8) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ń gbé àwọn àpótí tí àwọn èèyàn lè fi ọrẹ sínú rẹ̀ sáwọn ibi tá a ti ń ṣe ìpàdé kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fi owó ṣètìlẹ́yìn lè fi síbẹ̀. A kì í dárúkọ ẹni tó fi owó síbẹ̀.

Ọ̀kan lára ìdí tí a fi ń rówó ṣe àwọn nǹkan tí à ń ṣe ni pé kò sí àwọn àlùfáà tí à ń sanwó fún. Láfikún sí i, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba owó fún iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tí à ń ṣe, àwọn ilé ìjọsìn wa kì í sì í tóbi gìrìwò.

Owó tá a bá fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la fi máa ń bójú tó àwọn tí àjálù dé bá, a fi ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, a sì tún máa ń lò ó láti kọ́ àwọn ilé tá a ti ń ṣe ìpàdé láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Bákan náà, à ń fi owó yìí tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé míì tó ń ṣàlàyé Bíbélì, ká sì tún kó wọ́n ránṣẹ́.

Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa ń pinnu bóyá òun fẹ́ fi owó ṣètìlẹ́yìn fún ìnáwó ìjọ, iṣẹ́ ìwàásù wa kárí ayé tàbí méjèèjì. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì máa ń jẹ́ kí àwọn ará ìjọ mọ bí wọ́n ṣe ń náwó.