Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú Bíbélì. (Ẹ́kísódù 6:3; Sáàmù 83:18) Ẹlẹ́rìí ni ẹni tó ń sọ ohun tó dá a lójú tàbí òtítọ́ tó mọ̀ dájú. Nítorí náà, orúkọ wa, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fi hàn pé a jẹ́ àwùjọ Kristẹni tó ń sọ òtítọ́ nípa Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. (Ìṣípayá 4:11) À ń jẹ́rìí fún àwọn èèyàn nípasẹ̀ ọ̀nà tí à ń gbà gbé ìgbésí ayé wa àti nípa sísọ ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì fún wọn.—Aísáyà 43:10-12; 1 Pétérù 2:12