Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Èèyàn Lè Kúrò Nínú Ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ṣé Èèyàn Lè Kúrò Nínú Ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun méjì ni ẹnì kan lè ṣe tó bá fẹ́ kúrò nínú ẹ̀sìn wa:

  • Ó lè sọ fún wa. Tẹ́nì kan bá pinnu pé òun ò fẹ́ ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ó lè bá wa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ tàbí kó kọ̀wé sí wa.

  • Ó lè gbé ìgbésẹ̀. Ẹnì kan lè ṣe ohun kan tó máa fi hàn pé òun ò sí lára ẹgbẹ́ ará wa tó wà kárí ayé mọ́. (1 Pétérù 5:9) Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe ẹ̀sìn míì, kó sì jẹ́ kó hàn pé ẹ̀sìn yẹn lòun fẹ́ máa ṣe báyìí.1 Jòhánù 2:19.

Tẹ́nì kan ò bá wàásù mọ́ tàbí tí kò wá sí ìpàdé yín mọ́ ńkọ́? Ṣé ẹ máa ka ẹni náà mọ́ ara àwọn tó ti kúrò nínú ẹ̀sìn yín ni?

Rárá, a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tó kúrò nínú ẹ̀sìn wa tàbí tó pinnu pé òun ò dara pọ̀ mọ́ wa mọ́ yàtọ̀ sí ẹni tó nígbàgbọ́, àmọ́ tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò lágbára mọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, tẹ́nì kan ò bá jọ́sìn déédéé tàbí ti ò jọ́sìn mọ́, kì í ṣe pé ó ti kúrò nínú ẹ̀sìn yẹn, ó lè jẹ́ pé onítọ̀hún ti ń rẹ̀wẹ̀sì ni. Dípò tá a fi máa wá pa ẹni náà tì, ṣe la máa ń gbìyànjú láti tù ú nínú, ká sì ràn án lọ́wọ́. (1 Tẹsalóníkà 5:14; Júúdà 22) Tẹ́ni náà bá fẹ́ ká ran òun lọ́wọ́, àwọn alàgbà nínú ìjọ ló máa kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà sún mọ́ Ọlọ́run.Gálátíà 6:1; 1 Pétérù 5:1-3.

Àmọ́, àwọn alàgbà ò láṣẹ láti fipá mú ẹnì kan pé kò gbọ́dọ̀ kúrò nínú ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kálukú ló máa pinnu ẹ̀sìn tó máa ṣe. (Jóṣúà 24:15) A gbà pé téèyàn bá fẹ́ sin Ọlọ́run, ó yẹ kó ṣe é látọkàn wá, kò yẹ kí wọ́n fipá mú un.Sáàmù 110:3; Mátíù 22:37.