Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ṣé Ẹ̀ya Ìsìn Amẹ́ríkà ni Ẹ̀sìn Yín?

Ṣé Ẹ̀ya Ìsìn Amẹ́ríkà ni Ẹ̀sìn Yín?

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni orílé-iṣẹ́ wa àgbáyé wà. Àmọ́, ẹ̀sìn wa kì í ṣe ẹ̀ya ìsìn Amẹ́ríkà, àwọn ohun tó mú ka sọ bẹ́ẹ̀ rèé:

  • Àwọn kan ka ẹ̀ya ìsìn sí àwùjọ kan tó ya kúrò lára ẹ̀sìn tó ti wà tẹ́lẹ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ya kúrò lára àwọn ẹ̀sìn mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la pa dà sí bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.

  • Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù déédéé ní ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè tó ju ọgbọ̀n lé ní igba [230] lọ. Ibi yòówù tí a ń gbé, a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, kì í ṣe sí Ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tàbí ìjọba èèyàn èyíkéyìí.—Jòhánù 15:19; 17:15, 16.

  • Gbogbo ẹ̀kọ́ wa ló wá látinú Bíbélì, kì í ṣe látinú ìwé àwọn olórí ìsìn kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà.1 Tẹsalóníkà 2:13.

  • Jésù Kristi ni à ń tẹ̀ lé, kì í ṣe èèyàn èyíkéyìí tó jẹ́ olórí.—Mátíù 23:8-10.