Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé àwọn ìlànà àti àṣẹ tó wà nínú Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó múnú Ọlọ́run dùn, tó sì máa ṣe wá láǹfààní. (Aísáyà 48:17, 18) Àwa kọ́ la ṣe àwọn ìlànà yìí, àwa sì kọ́ la gbé àwọn àṣẹ yìí kalẹ̀, àmọ́ a máa ń tẹ̀ lé wọn. Wo bí díẹ̀ nínú àwọn ìlànà yìí ṣe kan ọ̀rọ̀ fífẹ́ra sọ́nà. *

  • Títí láé làwọn tó bá ṣègbéyàwó máa wà pa pọ̀. (Mátíù 19:6) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ fífẹ́ra sọ́nà, torí a gbà pé àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà ní in lọ́kàn pé àwọn máa ṣègbéyàwó.

  • Àwọn tó ti dàgbà tó láti ṣègbéyàwó nìkan ló lè fẹ́ra sọ́nà, torí wọ́n ti “ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” tàbí ká sọ pé wọ́n ti kọjá ìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ á máa pani bí ọtí.1 Kọ́ríńtì 7:36.

  • Àwọn tó bá lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣègbéyàwó ló lè fẹ́ra wọn sọ́nà. Lójú Ọlọ́run, àwọn kan tó kọra wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fẹ́ ẹlòmíì, torí pé ìlànà Ọlọ́run ni pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí ẹnì kan kọ ẹni tó bá ṣègbéyàwó sílẹ̀ ni tí ẹni náà bá lọ ṣe ìṣekúṣe.Mátíù 19:9.

  • Àṣẹ Ọlọ́run ni pé tẹ́nì kan bá fẹ́ ṣègbéyàwó, onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ nìkan ni kó fẹ́. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Ojú táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo àṣẹ yìí ni pé kí wọ́n fẹ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ bá tiwọn mu, tó sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi, kì í ṣe ẹni tó kàn fara mọ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (2 Kọ́ríńtì 6:14) Ọjọ́ pẹ́ tí Ọlọ́run ti ń pa á láṣẹ pé ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ bá tiwọn mu nìkan ni kí àwọn tó ń jọ́sìn òun fẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 24:3; Málákì 2:11) Àṣẹ yìí sì bọ́gbọ́n mu, torí ìwádìí táwọn èèyàn ṣe lóde òní fi hàn pé ohun tó bọ́gbọ́n mu nìyẹn. *

  • Ó yẹ káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu. (Òwe 1:8; Kólósè 3:20) Àṣẹ yìí kan àwọn ọmọ tó ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé ohun táwọn òbí wọn bá sọ tó bá dọ̀rọ̀ níní àfẹ́sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè sọ pé ó dáa kí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin pé ọmọ ọdún kan pàtó kó tó ní àfẹ́sọ́nà, ó sì lè lójú ohun táwọn òbí gbà wọ́n láyè láti ṣe tí wọ́n bá ń fẹ́ra sọ́nà.

  • Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan máa ń fi ìlànà Ìwé Mímọ́ pinnu bóyá òun máa ní àfẹ́sọ́nà àti ẹni tó máa jẹ́ àfẹ́sọ́nà òun. Èyí bá ìlànà Bíbélì mu, ó sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ní àfẹ́sọ́nà máa ń lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó dàgbà dénú, tó sì fẹ́ ire fún wọn kí wọ́n lè gbà wọ́n nímọ̀ràn.Òwe 1:5.

  • Ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn máa ń ṣe tí wọ́n bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà ló jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lójú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ká yẹra fún ìṣekúṣe. Kì í ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ni ìṣekúṣe, ó tún kan àwọn ohun àìmọ́ míì táwọn tí ò tíì ṣègbéyàwó ń bára wọn ṣe, bíi kẹ́nì kan máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, kó máa fẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ tàbí kó máa ti ihò ìdí bá a lò pọ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Táwọn tí ò tíì bára wọn ṣègbéyàwó bá ń ṣe ohun tó ń mú kó máa wù wọ́n láti bára wọn lò pọ̀, “ìwà àìmọ́” ni wọ́n ń hù yẹn bí wọn ò tiẹ̀ bára wọn lò pọ̀, Ọlọ́run sì kórìíra rẹ̀. (Gálátíà 5:19-21) Bíbélì tún dẹ́bi fún ìsọkúsọ, bí àpẹẹrẹ, “ọ̀rọ̀ rírùn.”Kólósè 3:8.

  • Ọkàn ẹni máa ń tanni jẹ. (Jeremáyà 17:9) Ó lè mú kéèyàn lọ ṣe ohun téèyàn mọ̀ pé kò dáa. Kí àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà má bàa jẹ́ kí ọkàn wọn tàn wọ́n jẹ láti ṣe ohun tí kò tọ́, á dáa kí wọ́n má jọ dá wà níbì kan náà. Wọ́n lè wà láàárín àwọn tó níwà ọmọlúàbí tàbí kí wọ́n rí i pé ẹnì kan tó dàgbà dénú wà pẹ̀lú àwọn. (Òwe 28:26) Bákan náà, àwọn Kristẹni mọ̀ pé ó léwu láti máa wá ẹni tí wọ́n á fẹ́ lórí ìkànnì, pàápàá ẹni tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀.Sáàmù 26:4.

^ ìpínrọ̀ 2 Ibi gbogbo kọ́ làwọn èèyàn ti máa ń fẹ́ra sọ́nà kí wọ́n tó ṣègbéyàwó, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn ilẹ̀ kan, àmọ́ kì í ṣe àṣà àwọn míì. Bíbélì ò sọ pé dandan ni ká ní àfẹ́sọ́nà, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé àfi káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó kọ́kọ́ fẹ́ra wọn sọ́nà.

^ ìpínrọ̀ 6 Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé Marriage & Family Review sọ pé “ìwádìí mẹ́ta tí wọ́n fara balẹ̀ ṣe láàárín àwọn tó ti ṣègbéyàwó tipẹ́, fún nǹkan bíi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sí àádọ́ta (50) ọdún ó lé, fi hàn pé ìgbéyàwó àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn kan náà, tí ìgbàgbọ́ wọn sì jọra máa ń tọ́jọ́.”—Ìdìpọ̀ 38, àpilẹ̀kọ 1, ojú ìwé 88 (2005).