Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Bá Ń Kọ́ Mi Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ṣé Dandan Ni Kí N Di Ara Wọn?

Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Bá Ń Kọ́ Mi Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ṣé Dandan Ni Kí N Di Ara Wọn?

Rárá o, kì í ṣe dandan. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbádùn bá a ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọn ò sì di ará ìjọ wa. * Ìdí tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kí wọ́n lè mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Tó o bá ti mọ̀ ọ́n, ọwọ́ ẹ ló kù sí láti pinnu ohun tó o máa ṣe. A gbà pé kálukú ló máa yan ẹni tó máa sìn.​—Jóṣúà 24:15.

Ṣé mo lè lo Bíbélì tèmi tí wọ́n bá ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a fi èdè tá à ń sọ lóde òní kọ ló máa ń wù wá ká lò, a sì lè fún ẹ ní ọ̀kan lọ́fẹ̀ẹ́ tó o bá fẹ́, síbẹ̀, inú wa máa dùn tó o bá lo Bíbélì tìẹ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìtúmọ̀ Bíbélì tó ò ti lè rí ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àti bá a ṣe lè rí ìgbàlà.

Kí ló dé tí ẹ̀ ń kọ́ àwọn tí kò di ara yín lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

  • Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run gan-an la ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ káwọn Kristẹni máa kọ́ àwọn míì ní ohun tí wọ́n ti kọ́. (Mátíù 22:37, 38; 28:19, 20) Àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ la kà á sí pé a jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” ká máa kọ́ wọn lóhun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.​—1 Kọ́ríńtì 3:​6-9.

  • Torí pé a nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa la tún ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 22:39) Ó máa ń múnú wa dùn ká máa sọ àwọn ohun àgbàyanu tá a ti kọ́ fáwọn míì.​—Ìṣe 20:35.

^ ìpínrọ̀ 2 Lọ́dún ???, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ??? là ń darí lóṣooṣù, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé àwọn tó jọ máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ kan máa ń ju ẹyọ kan lọ. Síbẹ̀, àwọn ??? péré ló ṣèrìbọmi tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún yẹn.