Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá ká lè mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan. A máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìdílé wa, a sì máa ń ran ìdílé àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́. A gbà pé Ọlọ́run ló ṣètò ìdílé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:21-24; Éfésù 3:14, 15) Nínú Bíbélì, ó kọ́ wa láwọn ìlànà tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé kí ìgbéyàwó wọn lè láyọ̀ kí àárín tọkọtaya sì gún régé.

Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Ìdílé Wọn Lè Dáa

À ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì, torí ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ ọkọ tó dáa, ká lè jẹ́ ìyàwó tó dáa, ká sì lè jẹ́ òbí rere. (Òwe 31:10-31; Éfésù 5:22–6:4; 1 Tímótì 5:8) Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa ń ran àwọn tó wà nínú ìdílé lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí, tí ẹ̀sìn wọn bá tiẹ̀ yàtọ̀ síra. (1 Pétérù 3:1, 2) Ẹ gbọ́ ohun táwọn kan tó ti ṣègbéyàwó sọ, àmọ́ tí wọn kì í se Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ẹnì kejì wọn sì wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

  • “Ṣe là ń jà ṣáá ní gbogbo ọdún mẹ́fà àkọ́kọ́ tá a ṣègbéyàwó, a sì máa ń múnú bí ara wa gan-an. Àmọ́ nígbà tí Ivete, ìyàwó mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o di eni tó ń ní sùúrù, ó sì wá nífẹ̀ẹ́ mi gan-an. Ìyípadà tó ṣe yìí ni ò jẹ́ kí ìgbéyàwó wa tú ká.”—Clauir, láti orílẹ̀-èdè Brazil.

  • “Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Chansa, ọkọ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò gbà fún wọn, torí mo rò pé ṣe ni wọ́n máa ń tú ìdílé ká. Àmọ́ látìgbà yẹn, mo ti wá rí i pé ṣe ni ẹ̀kọ́ Bíbélì mú kí ìgbéyàwó wa dáa sí i.”—Agness, láti orílẹ̀-èdè Zambia.

Tá a bá ń wàásù fáwọn aládùúgbò wa, a máa ń fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì hàn wọ́n, èyí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè

  • Fi ọgbọ́n yan ẹni tí wọ́n á fẹ́

  • Ṣàṣeyọrí láàárín ọdún àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó

  • Yanjú ìṣòro àárín àwọn àti àna wọn

  • Máa ṣọ́wó ná

  • Jáwọ́ nínú bíbá ara wọn jiyàn

  • Máa dárí ji ara wọn

  • Tọ́ àwọn ọmọ wọn dáadáa

Tẹ́nì kan bá yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà, ǹjẹ́ ìyẹn lè fa èdèkòyédè nínú ìdílé?

Lóòótọ́, ó máa ń rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1998, nígbà tí ilé iṣẹ́ Sofres ń ṣèwádìí nípa àwọn ìdílé tí ọkọ tàbí ìyàwó nìkan ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí, wọ́n rí i pé tí wọ́n bá kó ogún (20) ìdílé jọ, ìdílé kan máa níṣòro torí pé ọkọ tàbí ìyàwó ti yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà.

Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ òun ò ní bá ìdílé wọn rẹ́ nígbà míì. (Mátíù 10:32-36) Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Will Durant kíyè sí i pé lábẹ́ ìjọba Róòmù, “wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn Kristẹni pé wọ́n máa ń tú ìdílé ká,” * wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn yẹn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà lónìí. Ṣé ohun tó wá túmọ̀ sí ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fa èdèkòyédè yìí?

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù

Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ń dá ẹjọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n máa ń tú ìdílé ká, Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn mẹ́ńbà ìdílé tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dá ìjà sílẹ̀ torí pé wọn kì í “gbà pé ìbátan wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn rẹ̀ ní gbangba.” Ilé Ẹjọ́ náà fi kún un pé: “Ohun kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó wà nínú ìdílé míì tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra, kò sì yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀.” * Kódà, nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àtakò sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, a máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”Róòmù 12:17, 18.

Ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé ẹni tó ń ṣe ẹ̀sìn wọn nìkan ló yẹ kí wọ́n fẹ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni inú Bíbélì tó sọ pé kéèyàn gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa,” ìyẹn ni pé, kí wọ́n fẹ́ eni tí wọ́n jọ ní ìgbàgbọ́ kan náà. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Bíbélì ló pa àṣẹ yìí, ó sì bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan tó jáde lọ́dún 2010 nínú ìwé Journal of Marriage and Family sọ pé “àwọn tọkọtaya tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ kan náà” sábà máa ń ní àjọṣe tó dáa. *

Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sọ fún àwọn mẹ́ńbà wọn pé kí wọ́n fi ọkọ tàbí ìyàwó wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀; àti obìnrin tí ó ní ọkọ tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:12, 13) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àṣẹ yìí.

^ ìpínrọ̀ 17 Wo ìwé Caesar and Christ, ojú ìwé 647.

^ ìpínrọ̀ 18 Wo ẹjọ́ tí wọ́n dá tó wà nínú ìwé Jehovah’s Witnesses of Moscow and Others v. Russia, ojú ìwé 26-27, ìpínrọ̀ 111.

^ ìpínrọ̀ 20 Wo ìwé náà, Journal of Marriage and Family, Volume 72, Number 4, (August 2010), ojú ìwé 963.