Rárá o. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn ka Ìwé Mímọ́. Àwọn ẹlẹ́sìn kan ń kọ́ni pé kíkó àwọn Júù jọ ní Palestine jẹ mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní irú èrò yìí. Wọn kò gbà pé Ìwé Mímọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìkórajọ tó jẹ mọ́ òṣèlú yìí. Ká sòótọ́, Ìwé Mímọ́ kò ṣètìlẹ́yìn fún ìjọba èèyàn èyíkéyìí, kò sì gbé ìran èèyàn kan ga ju òmíràn lọ. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, tó jẹ́ ìwé ìròyìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti sọ kedere pé: “Ìwé Mímọ́ kò ti ẹgbẹ́ òṣèlú Zionism lẹ́yìn.”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé ẹgbẹ́ Zionism jẹ́ “ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn Júù tí wọ́n fẹ́ dá orílẹ̀-èdè Júù sílẹ̀ ní Palestine, kí wọ́n sì tì í lẹ́yìn. Wọ́n gbé e karí ẹ̀sìn àti òṣèlú. ” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ṣètìlẹ́yìn fún ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ti ẹgbẹ́ Zionism, wọn kò sì lọ́wọ́ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Zionism.

Ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ti ẹ̀sìn kì í sì í ṣètìlẹ́yìn fún ètò ìṣèlú kankan, títí kan ti ẹgbẹ́ Zionism. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ sí òṣèlú, àwọn èèyàn sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí ó wà ní àkọ́sílẹ̀ nínú ìtàn. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fara da inúnibíni tó le kú nítorí wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe òṣèlú. Ó dá wa lójú pé ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa mú àlàáfíà tó máa wà títí lọ́ wá sí ayé, kò sí ìjọba èèyàn tàbí ẹgbẹ́ kankan tó lè ṣe é.

Ìlànà ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ibikíbi tí wọ́n bá ń gbé ni pé kí wọ́n máa ṣègbọràn sí òfin àwọn aláṣẹ ìjọba. Wọn kì í ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn aláṣẹ ìjọba, wọn kì í sì í jagun.