Àwọn tí wọ́n bá fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn ní láti gbà pé Ọlọ́run àti Jésù fara mọ́ ẹ̀sìn wọn. Ká ní wọn kò gbà bẹ́ẹ̀ ni, ṣé wọ́n á máa ṣe é?

Jésù Kristi kò fara mọ́ èrò àwọn kan pé ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn tàbí ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà, pé gbogbo wọn ló máa ṣamọ̀nà sí ìgbàlà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:14) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé wọ́n ti rí ọ̀nà yẹn. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, wọn ì bá ti wá ẹ̀sìn míì.