Yorùbá
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Láti Ṣe Ìmọ́tótó Igbó Tó Wà Nítòsí Ìlú Lviv
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/502018507/univ/art/502018507_univ_sqr_xl.jpg

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Láti Ṣe Ìmọ́tótó Igbó Tó Wà Nítòsí Ìlú Lviv

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Láti Ṣe Ìmọ́tótó Igbó Tó Wà Nítòsí Ìlú Lviv

Ní May 6, 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tó àádóje [130] ló lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìmọ́tótó igbó Bryukhovychi Forest tó wà nítòsí ìlú Lviv, ní orílẹ̀-èdè Ukraine. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wà láàárín ẹni ọdún méjìdínlógún [22] sí ọgọ́rin [80] gbogbo wọn ló ǹ ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń gbé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti Ukraine tó wà nítòsí igbó yẹn. Ibi tí wọn ti siṣẹ́ fẹ̀ tó àádọ́ta [50] éékà, iye ìdọ̀tí tí wọ́n sì kó láàárín wákàtí mẹ́ta tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà kílógírámù [600kg].

Mykhailo Splavinskyi tó ń múpò iwájú nínú àwọn tó ń bójú tó Lviv Forest Breeding and Drilling Center sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe ìmọ́tótó tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, láti ọdún 2014 sì ni wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ìdí Tí Wọn Fi Ń Ṣe Ìmọ́tótó Igbó Yẹn

Ọ̀gbẹ́ni Splavinskyi sọ pé: “Ọ̀nà méjì ni ìdọ̀tí fi máa ń dé inú igbó yìí, àkọ́kọ́, àwọn kan máa ń ju ìdọ̀tí síbẹ̀. Ìkejì, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé máa ń wá fi mọ́tò ńlá da ìdọ̀tí síbẹ̀.”

Kò dáa kí ìdọ̀tí máa wà nínú igbó yìí rárá. Ọ̀gbẹ́ni Splavinskyi sọ pé: “Ó máa ń pẹ́ káwọn ìdọ̀tí yẹn tó jẹrà, lẹ́yìn náà ó máa ba omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀ jẹ́, ìyẹn sì lè ba àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti dá sílẹ̀ jẹ́.” Yàtọ̀ síyẹn, gíláàsì lè darí oòrùn sára ewé ní tààràtà, ìyẹn sì lè mú kí iná sọ sínú igbó. Gíláàsì tó ti fọ́ àti abẹ́rẹ́ náà lè ṣe èèyàn léṣe, pàápàá jù lọ àwọn ọmọdé. “Tá a bá kó àwọn ìdọ̀tí yẹn kúrò, kò ní ṣe èèyàn ní jàǹbá.

Kò rọrùn rárá láti ṣe ìmọ́tótó igbó tó fẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn mẹ́ta [3,300] éékà, iṣẹ́ ńlá gidi gan-an ni. “Àwọn márùn-ún péré ló ń bá wa sọ́ ọgbà yìí, torí náà a ò lè dá tún ibi yìí ṣe. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń pe gbogbo èèyàn láti wá bá wa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìmọ́tótó náà.”

Bá A Ṣe Ń Kó Ìdọ̀tí Jọ, Là Ń Yà á sọ́tọ̀, tá a sì ń Dàá Nù

Àwọn Ẹlẹ́rìí náà máa ń wọ gílọ̀ọ̀fù, wọ́n á tún lo náílọ́ọ̀nù, àti réèkì láti kó àwọn ìgò, táyà mọ́tò, gíláàsì, irin, bébà, ike, àti abẹ́rẹ́. Ihor Fedak tó máa ń tọ́jú àwọn igi tó wà nínú igbó yẹn sọ pé: “Ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣiṣẹ́ mọ́ gan-an.”

Ṣe ni wọ́n tún ṣa àwọn ìdọ̀tí yẹn sọ́tọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí òfin kankan tó sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n fi gíláàsì, bébà àti ike sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn sì mú kó rọrùn láti tún àwọn nǹkan yẹn lò fún nǹkan míì. Ilé iṣẹ́ kan tó máa ń bójú tó ìdọ̀tí ló máa wá kó wọn lọ. Láti ọdún 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń sanwó fún ilé iṣẹ́ tó máa ń kó ìdọ̀tí yẹn lọ. Ọ̀gbẹ́ni Fedak sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran wá lọ́wọ́ gan-an ni, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.”

“Mi Ò Kọjá Ẹni Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìmọ́tótó”

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń dùn láti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìmọ́tótó igbó yìí lọ́dọọdún. Wọ́n fẹ́ ṣe nǹkan tó máa ṣe àwọn ará àdúgbò láǹfààní tó sì máa mú kí igbó yẹn wà ní mímọ́. Volker sọ pé àwọn sábà máa ń sọ pé: “Mi ò kọjá ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó. Iyì ló jẹ́ láti máa ṣe ohun tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní, ohun tó sì máa ń fún mi láyọ̀ nìyẹn.”

Anzhelika náà sọ pé: “Fún èmi, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ń kó àwọn ìdọ̀tí yẹn kúrò, kì í ṣe pé kí ń máa béèrè ẹni tó ju ìdọ̀tí síbẹ̀.” Lois tó jẹ́ ẹni ọdún [78] náà lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìmọ́tótó yẹn. Ó ní: “Dípò ká máa wo àwọn ìdọ̀tí yẹn bí ohun ìríra tá a bá ń rìn kọjá níbẹ̀, ohun tó dáa jù ni pé ká wá bá a ṣe máa kó wọn dànù.”

Wieslaw sọ pé: “Tá a bá wá wàásù fún àwọn èèyàn, wọ́n sábà máa ń rí i pé a múra dáadáa, a tún de táì. Àmọ́, a tún ṣe tán láti ká apá aṣọ wa sókè láti ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó àti àwọn nǹkan míì tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní.”