Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì
A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.
Britain
Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a sì fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn.
Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mú rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.
Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán, wákàtí kan kó tó di pé wọ́n máa mú yín rìn yíká.
Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tí iye àwọn tó ń bọ̀ kò bá tó ogún (20), tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò—A Ò Tó Ogún.” Àmọ́ tẹ́ ẹ bá tó ogún (20) tàbí tẹ́ ẹ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ jọ̀wọ́, ẹ pè wá ká lè ṣètò sílẹ̀ fún yín.
Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.
Ìbẹ̀wò
Àwọn Iṣẹ́ Tí À Ń Ṣe Níbẹ̀
À ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní ilẹ̀ Britain, Ireland, àti Malta. À tún ń túmọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí oríṣiríṣi èdè, irú bí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti British, Irish, Scottish Gaelic àti Welsh. A tún ń ṣe àwọn fídíò àti àwọn ohun tá a lè tẹ́tí sí.
Ẹ Tún Lè Múra Yín Rìn Yíká
“Ìtàn Wa”: Láì jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tẹ̀lé yín, ẹ máa fúnra yín rí ìtàn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe bẹ̀rẹ̀ àti ibi tó dé báyìí ní Britain àti Ireland.
“Bíbélì ní Britain”: Apá yìí lẹ ti máa rí àwọn Bíbélì tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí lóde mọ́, ẹ tún máa rí bí ìtẹ̀síwájú ṣe ti dé bá iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì láti àwọn ọdún yìí wá.
Àwọn Ẹ̀ka Tá A Ní: Ibí lẹ ti máa rí oríṣiríṣi nǹkan títí kan fídíò tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ àwọn iṣẹ́ tá à ń ṣe ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Britain.

